1 Mo lérò pé ẹ legba ìwà òmùgò mi. Sùgbón ẹ ńfi ìwà mi jìnmí nítòótọ́. 2 Mò ń jowú yin fún èyí. Èyí tíí ṣe ìjowú ti Ọlọ́run, níwò̩n ìgbàtí mo ti s̩e ìlérí ìgbeyàwó fún yín nínú ọkọ kan. Mo ṣe ìlérí fún yín láti fi yín hàn gẹ́gẹ́ bíi wúndíá aláìlábàwọ́n fún Krístì. 3 S̩ùgbó̩n, ẹ̀rù ńbà mí nítorí gẹ́gẹ́ bí ejò s̩e tan Éfà jẹ nípa ìwà àrékérekè rẹ̀, èrò yín ń ṣì yín lọ́nà kúrò nínú ìwà títọ́ àti ẹ̀mí ìsìn tí ó pé fún Krístì. 4 Nígbàtí ẹlòmíràn bá wá láti kéde Jésù míràn fún yín yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù fún yín. Tàbí nígbàtí ẹ bá gba ẹ̀mí míràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà. Tàbí nígbàtí ẹ bá gba ìhìnrere míràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tẹ́lẹ̀. Ẹ fi ara dàá! 5 Èmi ròpé èmi kọ́ ni ẹnití ó kéré jù nínú àwọn àpọ́stélì tí ó gajùlọ. 6 Ṣùgbọ́n, kí á tilẹ̀ sọpé aláìlẹ́kọ̀ọ́ ni mojẹ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ̀, èmi kò jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀. Ní ọ̀nà gbogbo àti nínú ohun gbogbo, a ti sọ èyí di mímọ̀ fún yín. 7 Ǹjẹ́ mo dẹ́ṣẹ̀ nípa rírẹ ara mi sílẹ̀ kí ẹ̀yin le baà di gbígbéga bí ? nítorí èmi ńkéde ìhìnrere ti Ọlọ́run fún yín láìfi ipá múni. 8 Mò ńgba ìrànlọ́wọ́ nínú àwọn ìjọ míràn láti sìn yín. 9 Nígbàtí mo wà pẹ̀lú yín, tí mo sì jé̩ aláìní, èmi kò jẹ́ àjàgà fún ẹnikẹ́ni. Nítorí àwo̩n ara Masidóníà bá àìní mi pàdé. Nínú ohun gbogbo, mo ti ya ara mi kúrò nínú jíjẹ́ àjàgà fún yín, mo sì ńtẹ̀síwájú láti ma ṣe gẹ́gẹ́bí èyí. 10 Gẹ́gẹ́bí òtítọ́ Krístì ti wà nínú mi, ìṣògo èyí kì yóò di dídákẹ́jẹ́ ní apá Achaya. 11 Kínni ìdí èyí? Ǹjẹ́ nítorí èmi kò ní ìfẹ́ yín ni bí ? Ọlọ́run mọ̀. 12 Àti ohun tí mò ńṣe, n ó tè̩síwájú láti máa s̩e é, kí èmi kí ó le baà mú ẹ̀tọ́ ìgbéraga sími àti ẹ̀tọ́ ìfọ́nnu wípé àwọn ńṣe iṣẹ́ kannáà tí àwa ńṣe. 13 Nítorí àwọn ènìyàn yí jẹ́ apọsteli èké àti òṣìṣẹ́ tí ńtan ni jẹ. Wọn ndíbọ́n gẹ́gẹ́bíi apọsteli Krístì. 14 Èyí kò jẹ́ ìyàlẹ́nu, nítorí Sàtánì fúnrara rẹ̀ díbọ́n gẹ́gẹ́bíi ańgẹ́lì fún ìmọ́lẹ̀. 15 Kìí ṣe ìyàlẹ́nu tí ó tóbi jù, nígbàtí àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ náà bá ń díbọ́n gẹ́gẹ́bíi ìráńṣẹ́ ìṣódodo. Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ wọn. 16 Mo sọ lẹ́ẹ́kansi: kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé asiwèrè ni mí. Ṣùgbọ́n, tí ẹ bá lérò bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gẹ́gẹ́ bíi asiwèrè nítorí mò ń fọ́nnu díẹ̀. 17 Ohun tí mò ń sọ nípa ìgboyà ìfọ́nnu yìí nipé Olúwa kò fi àyè fún un, ṣùgbọ́n èmi ńsọ̀rọ̀ bíi aṣiwèrè. 18 Níwọ̀n ìgbàtí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fọ́nnu nínú ẹran ara, èmi pẹ̀lú yóò fọ́nnu. 19 Ẹ̀yin ńfi inúdídùn gbépọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣiwèrè. Ẹ̀yin jẹ́ ọlọgbọ́n fún ara yín! 20 Nítorítí ẹ̀yin ńfi ara ẹnìkan tí ó bá kóo yín lẹ́rú, tí ó bá gbé yín mìn, tí ó bá yájú sí yín, tí ó bá sì gbáa yín létí. 21 Mo sọ nípa tiwa pé a jẹ́ aláìlágbára láti ṣe èyí. síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá ń fọ́nnu- Mò ń sọ̀rọ̀ bíi asiwèrè - èmi pẹ̀lú yóò fọ́nnu. 22 Ǹjẹ́ nwọ́n jẹ́ Hébérù bí? Bẹ́ẹ̀ni èmi náà. ǹjẹ́ ọmọ Ísrẹ́lì? Bẹ́ẹ̀ni èmi náà. Ǹjẹ́ irú ọmọ Ábráhámù? Bẹ́ẹ̀ni èmi pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ nwọ́n jẹ́ ìráńṣẹ́ Krístì? (Mò nsọ̀rọ̀ bí ẹnití kò ní ọkàn.) Mo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti wà nínú iṣẹ́ agbára tí ó ju èyí lọ, nínú túbú jìnà réré, ní lílù tí ó kọjá àlà, ní dídojúkọ ewu ikú. 24 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù, a nà mí ní "ogójì ẹgba ódín ẹyọ̀kan ní ìgbà márùún." 25 Ẹ̀mẹta ni a lù mí ní ọ̀gọ. A sọ mí ní òkúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú-omi tí mo wọ̀ rì. Mo ti gbé inú òkùnkùn ní alẹ́ àti ní ojúmọmọ. 26 Mo ti wà ní ìrìn-àjò òrèkórèè, nínú ewu ìjàm̀bá odò tí ń ṣàn, àwọn adigunjale, àwọn ará mi, àwọn onígbàgbọ́ tí kò mọ Ọlọ́run, nínú ewu ìjàm̀bá ìlú, aginjù, omi òkun, àti àwọn arákùnrin èké. 27 Mo ti wà nínú iṣẹ́ àṣekára, àti ìnira, nínú àìsùn, nínú ebi àti òǹgbẹ, àwẹ̀ ìgbà gbogbo, nínú òtútù àti ní ìhòhò. 28 Yàtọ̀ sí ohun míràn, mo wà nínú ìhámọ́ lójojúmọ́ nítorí ìfòyà mi tí mo ní fún àwọn ìjọ. 29 Tani ó jẹ́ aláìlágbára? tí èmi kòsì jẹ́ aláìlágbára? Tani óti múni kọsẹ̀, ti èmi kòsì bínú sí? 30 Tí èmi bá tilẹ̀ gbọdọ̀ fọ́nnu, èmi yóò fọ́nnu nípa ohun tí ńṣe àfihàn àìlágbára mi. 31 Ọlọ́run àti Bàbá Jésù Olúwa, ẹniti ìyìn yẹ fún títí ayé mọ̀ pé èmi kò ṣe èké. 32 Ní Dàmáskù, baálẹ̀ lábẹ́ Ọba Árẹ́tásì ńṣọ́ ìlú Dàmáskù láti mú mi. 33 Ṣùgbọ́n, a gbémi bọ́ nínú apẹ̀rẹ̀ láti ojú fèrèsé, Mo sì bọ́ ní ọwọ́ wọn.