Orí Kejìnlá

1 Èmi gbọdọ̀ fọ́nnu, ṣùgbọ́n kòsí èrè kankan níbẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò lọ sínú ìran àti ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá. 2 Mo mọ ọkùnrin kan nínú Krístì ẹnití, fún ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn- yálà nínú ara, tàbí nínú ẹ̀mí, èmi kòmọ̀, Ọlọ́run mọ̀ - Amúu sókè sínú ọ̀run kẹta. 3 Àtipé, mo mọ̀ pé ọkùnrin yìí, yálà nínú ara, tàbí nínú ẹ̀mí, èmi kò mọ́, Ọlọ́run mọ̀- 4 Amúu lọ sókè sínú ọ̀run rere, tí ó sì gbọ́ ǹkan tí ó jẹ́ mímọ́ jù fún ẹnikẹ́ni láti sọ. 5 Nípò ènìyàn yí, èmi á fọ́nnu, ṣùgbọ́n, nípò èmi tìkaláraàmi, èmi kì yóò fọ́nnu, àyàfi nípa àìlágbára mi. 6 Tí èmi báfẹ́ fọ́nnu, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀, nítorí èmi yóò máa ṣọ òtítọ́. Ṣùgbọ́n èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa fọ́nnu, kí ẹnikẹ́ni máṣe rò nípa mi ju ohun tí a rí tàbi gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi. 7 Èmi yóò sì tún yẹra fún ìfọ́nnu nítorí àwọn ìfihàn tí ó ṣe ọ̀nà ọ̀tọ̀ yí. Nítorínáà, kí èmi má baà gbé ìgbéraga wọ̀, ẹ̀gún nínú ẹran ara ni afi fún mi, òjíṣẹ́ Sàtánì láti yọ mí lẹ́nu, kí èmi máṣe gbéraga jù. 8 Ní ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa ní orí ẹ̀yí, kí ó le múu kúrò lọ́dọ̀ mi. 9 Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wípé "ore-ọ̀fẹ́ Mi tó fún ọ, nítorí a sọ agbára mi di pípé nínú àìlágbára." Èmi á kúkú fọ́nnu púpọ̀ nípa àìlágbára mi, kí agbára Krístì baà le gbé inú mi. 10 Nítorínáà, mó se ìtẹ́lọ́rùn nínú àìlágbára gbogbo, nínú àbùkù, nínú wàhálà, nínú inúnibíni àti ipò tí kò rọnilọ́rùn. fún ìgbàkúúgbà tí mo jẹ́ àìlágbára, nígbà náà ni mo di alágbára. 11 Mo ti di aṣiwèrè! Ẹfi ipá mú mi sí èyì, nítorí ó tí yẹ kí ẹkan sárá sími. Èmi kò kéré sí àwọn tí à ńpè ní àpọ́stélì tí ó dára jùlọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò jẹ́ ohunkóhun. 12 Àmì tòótọ́ ti àpọ́stélì ni a tiṣe àfihàn rẹ̀ láàrin yín pẹ̀lú sùúrù tí ó pé, àmì àti iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ alágbára. 13 Fún báwo ni ẹ̀yin ṣe jẹ́ aláìṣe pàtàkì ju àwọn ìjọ tí o kù lọ, àyàfi pe èmi kò jẹ́ àjàgà fún yín? Ẹ dáríjì mi fún àṣìṣe yí! 14 Ẹ wòó! Mo ti ṣetán láti wá sí ọ̀dọ̀ yín ní ẹ̀kẹta. Èmi kò ní jẹ́ àjàgà fún un yín, nítorí èmi kò fẹ́ ohun tí ńṣe tiyín. Mo fẹ́ẹ yín. Nítorí àwọn ọmọ kò yẹ láti fi ohun kan pamọ́ fún àwọn òbí. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ni ó yẹ láti fi ohun kan pamọ́ fún àwọn ọmọ. 15 Èmi yóò fi ara àti ohun ìní mi fún yín pẹ̀lú inúdídùn. Tí mo bá ní ìfẹ́ yín jù, ǹjẹ́ kòyẹ kí ẹní ìfẹ́ mí bí? 16 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe wà, èmi kòjẹ́ àjàgà fún yín. Ṣùgbọ́n, nítorípé mo jẹ́ ọlọ́gbọ́n, èmi ni ẹni tí ó mu yín pẹ̀lú ẹ̀tàn. 17 Ǹjẹ́ mo ti yàn yín jẹ nípa rírán ẹnikẹ́ni síi yín bí? 18 Mo rọ Títù láti lọ sọ́dọ̀ yín, àti pé mo tún rán arákùnrin kan yókùn pẹ̀lú rẹ̀. Ǹjẹ́ Títù yàn yín jẹ bí? Ǹjẹ́ a kò rìn ní ọ̀nà kannáà bi? Ǹjẹ́ a kò rìn nípa gbígbé ìgbésẹ̀ kannáà bi? 19 Ǹjẹ́ ẹ lérò pé láti àkókò yí wá àwa ńgbèjà ara wa fún yín bí? Ní ojú Ọlọ́run, ati ńsọ ohun gbogbo fun yín nínú Krístì láti ro yín ní agbára. 20 Nítorí mò ńbẹ̀rù pé nígbàtí mo bá padà dé, èmi kò ni báa yín bí mo tifẹ́. Mo bẹ̀rù pé ẹ̀yin kò ní bá mi bí ẹti fẹ́. Mo bẹ̀rù pé àríyànjiyàn yóò wà, ìjowú, ìbínú fùfù, èrò ìmọ̀-tara-ẹni-nìkan, òfófó, ìgbéraga, àti rúdurùdu. 21 Mò ńbẹ̀rù pé nígbàtí mo bá padà dé, Ọlọ́run mi le ti rẹ̀ mí sílẹ̀. Mò ńbẹ̀rù pé a le mú mi bínú nítorí àwọn tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ kí ó tó di ìsinsìnyí, àti àwọn tí kò ronúpìwàdà kúrò nínú àìmọ́, àti ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí wọn ńṣe.