Orí Kẹtàlá

1 Ẹ̀kẹta nìyí tí mo ńwá sí ọ̀dọ̀ yín. "Gbogbo ẹ̀sùn gbọdọ̀ fi ìdi múlẹ̀ nípa ẹ̀rí ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta." 2 Mo ti sọ fún àwọn tí ó ti ńdẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti fún àwọn tí ókù nígbàtí mo wá lẹ́ẹ̀kejì, mo tún sọ lẹ́ẹ̀kan si: Nígbàtí mo bá wá padà, èmi kò ní dáwọnsí. 3 Mo sọ èyí fún yín nítorípé ẹ̀yin ńwá ẹ̀rí pé Jésù ńsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi. Kò jẹ́ aláìlágbára sí mi. Dípò bẹ́ẹ̀, Ó ní agbára nínú yín. 4 Nítorí a kàn án mọ́ àgbélèbú nínú àílágbára, ṣùgbọ́n Ó wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run. Àwa pẹ̀lú jẹ́ aláìlágbára nínú Rẹ̀, ṣùgbọ́n a ó gbé pẹ̀lú Rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run láàrin yín. 5 Ẹ yẹ ara yín wò láti mọ̀ bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́. Ẹ ṣe ìgbéyẹ̀wò ara yín. Ńjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ èyípé Jésù Krístì wà nínú yín? -àyàfi tí ẹ bá ti kùnà nínú ìgbéyẹ̀wò náà. 6 Àtipé mo gbàgbọ́ pé ẹ̀yin yóò ṣe ìdámọ̀ pé àwa kò kùnà nínú ìgbéyẹ̀wò náà. 7 Nísinsìnyí, à wa gbàdúrà sí Ọlọ́run kì ẹ̀yin máṣe ṣe ohun tí kò tọ́. Èmi kò gbàdúrà pé kí àwa le farahàn gẹ́gẹ́ bíi ẹnití ó ti yege nínú ìgbéyẹ̀wò náà. Dípò èyí, mo gbàdúrà pé kí ẹ̀yin le ṣe ohun tí ó tọ́, bíótilẹ̀jẹ́pé a dàbí ẹnití ó kùnà nínú ìgbéyẹ̀wò náà. 8 Nítorí, a kò leṣe ohunkóhun yàtọ̀ sí òtítọ́ nìkan. 9 Nítorí a yọ̀ nígbàtí a jẹ́ aláìlágbára àti nígbàtí ẹ jẹ́ alágbára. A tún gbàdúrà pé kí ẹ̀yin di pípé. 10 Mo kọ àwọn ǹkan wọ̀nyí nígbàtí mo yà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín, kí n má baà wọ̀ pẹ̀lú yín ní ọ̀nà tí kò bójúmu nípa lílo àṣẹ tí mo ní- tí Olúwa fifún mi, kí nbaà gbeyín sókè, kí n má sì ṣe fà yín wálẹ̀. 11 Ní àkótán, ará, ẹyọ̀! Ẹ ṣe iṣẹ́ fún ìdápadàbọ̀ sípò, ẹ tújúka, ẹ gbà fún ara yín, ẹ gbé nínú àlàáfíà. Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín. 12 Ẹ kí ara yín pẹ̀lú ìfẹnukonu mímọ́. 13 Gbogbo onígbàgbọ́ kíi yín. 14 Kí ore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì Olúwa, ìfẹ́ ti Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ Ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.