1 Ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a ti fifún àwọn ìjọ Masidóníà. 2 Nígbà ìdánwo ìpọ́njú ńlá, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ ati òṣi wọn ti so èso ọrọ̀ púpọ̀ nínu ìfifúnni. 3 Nítorí mo jẹ́rí wọn pé wọ́n fifúnni gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àti ju bí agbára wọn ti mọ lọ. Àti tinútinú wọn 4 àti pẹ̀lú ọ̀pọ́lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀ wọ́n bẹ̀è wá wípé kí á fún àwọn ní ànfàní láti ní ìpín nínú iṣẹ́ ìrànṣẹ yìí sí àwọn onígbàgbọ́. 5 È yí kò ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ròó. Kàkà bẹ̀, wọ́n kọ́kọ́ fi ara wọn fún Olúwa. Lẹ́yìn èyí wọ́n fi ara wọn fún wa gẹ́gẹ bí ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 Nítorínà a rọ Títù, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìfifúnni yìí, kí ó mú wá sí ìparí ní àrin yín. 7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yín pọ̀ nínú ohun gbogbo- nínú ìfẹ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìmọ̀, nínú iṣẹ́ takuntakun, àti nínú ìfẹ́ yín sí wa. Nítorínà ẹ sakitiyan pẹ̀lú láti pọ̀ nínú ìṣe ìfifúnni. 8 Èmi kò sọ éyí gẹ́gẹ́ bí àṣẹ. Dípò bẹ̀, mo sọ ọ́ kí á le mọ òtítọ́ ìfẹ́ yín kí á sì gbe yẹ̀wò sí tí àwọn ènìyàn yókù. 9 mọ ore ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jésù Kristì. Ní òtítọ́ ọlọ́rọ̀ nií ṣe, ṣùgbọ́n ó di tálákà nítorí yín, kí ẹ ba lè di ọlọ́rọ̀ nípa òṣì rẹ̀. 10 Lórí ọ̀rọ̀ yìì èmi yíò fun nyín ní ìmọ̀ràn tí yíò ràn yín lọ́wọ́. Ní ọdún kan sẹ́yìn, ẹ̀yin kò bẹ̀rẹ̀ láti ṣe ohun kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìpóngbẹ yín láti ṣe é. 11 Ní ìsinsìnyí, ẹ parí iṣé nà. Gẹ́gẹ́ bí ìpòngbẹ àti èròńgbà yín láti ṣe wọ́n ní ìgbà na, kí ẹ̀yin kí ó sì mú uń wá sí ìparí. 12 Nítorí bí ẹ̀yin ti ní ìpòngbẹ láti ṣe àwọn ìṣe nà, ohun tí ò dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà. Ó gbọdọ̀ dúró lórí ohun tí ènìyàn bá ní, kì sì í ṣe lórí ohun tí kò ní. 13 Nítorí iṣẹ́ yìí kìí ṣe láti dẹ àwọn ènìyàn yókù lára tàbí làti di ẹrù wúwo lée yín lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ìdọ́gba wà ní àrin yín. 14 Ohun ìní yín ní àkókò nà yí ò bá àìní wọn pàde. Èyí nà rì bẹ̀ kí ohun ìní ti wọn le bá àìní ti yín nà pàdé, àti pé kí ìdọ́gba le wà. 15 Ó wà gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́: "Ẹni tí ó ní tí ó pọ̀ kò ní ǹkan kan sẹ́kù, àti ẹni tí ó ní kékeré kò ṣe aláìní ohun kankan." 16 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, tí ó fi irú ìfẹ́ tí mo ní sí yín sí Títù ní ọkàn. 17 Nítorí kì í ṣé wípé ó gba ẹ̀bẹ̀ wa nìkan, ṣùgbọ́n ó tún ní èròńgbà láti ṣe é. Ó wá sí ọ̀dọ̀ yín tinútinú rẹ̀. 18 A ti rán an pẹ̀lú arákùnrin tí gbogbo ìjọ gbé oríyìn fùn fún iṣẹ́ ìpolongo ìyìn-rere. 19 Kì í ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ìjọ tún yàn án láti lọ pẹ̀lú wa nínu iṣé ìfinfúnni wa. Èyi wà fún ọlá Ọlọrún fún ara rẹ̀ àti fún ìtara tiwa láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́. 20 A n dènà gbogbo ọ̀nà tí àwọn ènìyàn yí ó fi má a rí àríwísí síwa nípa iṣẹ́ ìlawọ́ tí à ń ṣe. 21 Àwa ń kíyésára láti ṣe ohun tí ó ní ọ̀la, kì í ṣe ní iwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n ní iwájú àwọn ènìyàn. 22 Áwa tún rán arákùnrin míràn pẹ̀lu wọn. A ti ṣe àyẹ̀wò fún uń ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a sì ri wípe ó jẹ́ ẹni tí ó ní ọkàn rere láti ṣe iṣẹ́ púpọ̀. Ó tún ṣe ọlọgbọ́n nítorí ìgbẹ́kẹ̀le tí ó tóbi nínu yín. 23 Ní ti Títù, Ó jẹ́ akẹgbẹ́ mí àti olubáṣiṣẹ́pọ fún yín. Níti àwọn arákùnrin wa, àwọn ìjọ ní ó rán wọn. Wọ́n jẹ́ iyì fún Krístì. 24 Nítorínà ẹ fi ìfẹ́ yín hàn sí wọn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ìjọ pẹ̀lu ìdi tí a fi ń sọ̀rọ̀ rere nípa yín.