1 Ẹ̀yin olùfẹ́, ní ìwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn ìlèrí wọ̀n yìí ẹ jẹ́ kí á wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ohun gbogbo tì ó sọ wá di àìmọ́ ní ẹ̀mí àti ní ara. Ẹ jẹ́ kí á lépa ìwà mímọ́ nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 2 Ẹ fi àyè gbà wa! Àwa kò se ohun búburú sí ẹni kankan. Àwa ko ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni tàbí yan ẹnikẹ́ni jẹ. 3 Èmi kò sọ ọ̀rọ̀ wọ̀ǹyí láti dá yín lẹ́bi. Nítori mo sọ ní ìsàjú pé àwa níi yín ní ọkán wa, kí à le jùmọ̀ kú papọ̀ kí á sì jùmọ wà ní àyè papọ̀. 4 Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó tóbi nínú yíń, mo sì ń fi yín yangàn. Ọkàn mí kún fún ìtùnú. Ọkàn mí kún rékọjá fún ayọ̀ nínú gbogbo làásígbò wa. 5 Nígbà tí awá sí Masidóníà, a kò ní ìsinmin. kàkà bẹ̀ a yọ wá lẹ́nu ní gbogbo ọ̀nà nípa ìjàgùdù lóde àti ẹ̀ẹ̀rù nínú. 6 Ṣùgbọ̀n Ọlọ́run, ẹni tí ó ń tu olùrẹ̀wẹ̀sì nínú, tùwa nínu nípa dídé Títù. 7 Kìí ṣe nípa díde rẹ̀ nìkan ni Ọlọ́run fi tùwánínú. Ó tún jẹ́ nípa ìtùnú tí Títù ti gbà láti ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú. Ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ ńlá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìsakitiyan nítorí ì mi. Nítorínà mo tún bọ́ yọ̀ púpọ̀. 8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìwé tí mo kọ sí i yín mú yín banújẹ́, mi kò kábàmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo kábàmọ̀ rẹ̀ nígbàtí mo rí wípé ó mú inú yín bàjẹ́. Ṣùgbọ̀n inú yín bàjẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ni. 9 Inú mì dùn ní ìsinsìnyìí, kì í ṣe nítorí tí ẹwà nínú ìdàmú, ṣùgbọ́n nítorí tí ìbànújẹ́ yín mú yín ronúpìwàdà. Ẹ ní ìrírí ìbànújẹ́ ẹni bíi ọlọ́run, nítorínà Ẹ kò pàdánù ohunkóhun nítorí wa. 10 Nítorí ìbànújẹ́ ẹni bíi Ọlọ́run so èso ìrònúpíwàdà tí ó mú ìgbàlà lọ́wọ́ ní aláìkábàmọ̀. Ìbànújẹ́ ti ayé mú ikú dání. 11 Ẹ wo irú ìpinnu ńlá ti ìbànújẹ́ ti Ọlọ́run so nínú yín.Irú ìpinnu ńla yìí ni ó fi hàn wípé ẹ jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀. Irú ìbi ńlá yìí, ẹ̀rù yín, ìsakitiyan yín, ìtara yín, àti èròńgbà yín láti rí wípe a ṣe ìdájọ́ òdodo! Ẹ ti fi ara yín hàn gẹ́gẹ́ bíi aláìlẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀ràn gbogbo yìí. 12 Bí ó tilẹ̀ jẹ̀ wípé mo kọ ìwé síi yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí àwọn olùṣebúburú, tàbí nítorí àwọn tí ó ń jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Mo kọ ọ́ kí ọ̀yin kí ó lemọ bí Ẹ ti jẹ́ olótìtọ́ sí wa ní iwájú Ọlọ́run. 13 Nípa èyí ni a gbà wá ní ìyànjú. Ní àfikún sí ìtùnú wa, a túnbọ̀ yọ̀ nítorí ayọ̀ Títù, nítorí wípe gbogbo yín mú ìtura bá ẹ̀mí rẹ̀. 14 Nítorí bí èmi bá sọ ọ̀rọ̀ rere yín fún Títù, ojú kò tìmí. Ní ìdà míràn, bí ó bá jẹ́ wípé ohun gbogbo tí a sọ fún yín bájẹ́ òtítọ́, bẹ̀ nà ni ohun rere gbogbo tí a sọ nípa yín fún Títù jẹ́ òtítọ́. 15 Ìfẹ́ tí ó ní sí i yín tóbi gidigan, gẹ́gẹ́ bí ó ti rántí igbọràn gbogbo yín, bí ẹ ti gbà á pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwàrírì. 16 Èmi yọ̀ nítorí wípé mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ó kún nínú yín.