1 Siṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ má gba ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni asán. 2 Nítorì ó sọ pé, "ni akoko ti o dara mo fi òye mi sí yín, àti ní ọjọ́ ìgbàlà. 3 A kò fi ìdíwọ́ sí iwájú ẹnikẹ́ni, nítorí a kò fẹ́ kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa di ohun àbùkù. 4 Dípò, a n fi ìjẹ́èrí arawa mú lẹ̀ nípa àwọn ohun tí à ńṣe, pé a jẹ́ ìrańṣẹ́ Krístì. A jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ́ ni ìpamọ́ra, ìpọ́njú, ìrẹ̀wẹ̀sì, ìṣoro, 5 ìjìyà, nínú túbú, rògbògbòdìyàn, iṣẹ́ àṣekára, àìlesùn, nínú ebi, 6 ni ìjẹ́ mímọ́, ìmọ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìkẹ́, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, ni ìfẹ́ ìjìlẹ̀. 7 A jẹ́ ìránsẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀dọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run. A ní ìhámọ́ra ìṣòdodo fún apá ọ̀tún àti apá òsì.. 8 Àwá ǹrìn ni ọlá àti àìlọ́lá, ní ìkọ̀sílẹ̀ àti ìyìn. 9 A nṣiṣẹ́ bí pé aò mọ̀ wá rí, ṣùgbọ́n a sì mọ̀ wá dáadaá. A nṣiṣẹ́ bí kíkú a sì n-rí!-a sì wá láyé. A nṣiṣẹ́ bí ẹni tín jìyà nítorí àwọn ìṣe wa ṣùgbọn kìí ṣe bí ìtanù sí ikú. 10 A nṣiṣẹ́ bí ẹni tó ní ìṣòro, ṣùgbọ́n àwá yọ̀ ní ìgbàgbogbo. A nṣiṣẹ́ bí otòṣì, ṣùgbọ́n a ní ọ̀rọ̀ púpọ̀. A nṣiṣẹ́ bí pé aó ní ǹkankan ṣùgbọ́n síbẹ̀ bí pé a ní ohun gbogbo. 11 A ti sọ ohun gbogbo tó jẹ́ òtítọ́ fún yín, àwọ̀n Kọ̀ríntì, ọkàn wa sì ṣí sílẹ̀. 12 Ọkàn yín kò wà ní ìdíwọ́ nípasẹ̀ wa, ṣùgbọ́n bíkòṣe nípa erò yín. 13 Nísisìnyí, dípò ẹ̀rù- mo sọ bí ọmọdé-ẹ si ọkàn yín sílẹ̀. 14 Má ṣe wà ní ìsòpọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́. Nitoriti ohun kan wo ni wiwa ni mimo ni se pelu àìgbọràn? Ìpéjọpọ̀ wo ni ó wà láàrin ìmọ́lè àti òkùnkùn? 15 Àdéhùn wo ló wà láàrin Krístì àti èṣù? Tàbí ìpín wo ni onígbàgbọ́ ní papọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 Àti àdéhùn wo ni ó wà láàrin tẹ́mpìlì Olúwa àti òrìṣà? Nítorí àwa ni tẹ́mpìlì Ọlọ́run alaàyè, bí Olúwa ti sọ pé, "Èmi yó gbe láàrín wọn èmi yó sì rìn láàrin wọn pẹ̀lú. Èmi yó jẹ́ Olúwa wọn, àti àwọn yó sì jẹ́ ènìyàn mi." 17 Nítorínà, "Jáde kúrò láàrín wọn, kí o sì di yíyà sọ́ tọ̀," ni Olúwa wí. "Má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́, Èmi yó sì gbà ọ́ 18 Èmi yó jẹ́ Bàbá fún ẹ, àti ìwọ yó jẹ́ ọmọkúnrin ati ọmọbìnrin mi," ni Ọlọ́run alágbára wi.