1 Àwá mọ̀ pé bí gbígbé ní ayé yî bá parun, a ní ile kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kìí ṣe ile tí a ti ọwọ́ ènìyàn kọ́, ṣùgbọ́n ilé ayérayé, ní ọrun. 2 Nítorí a ńké ni ìrora nínu àgọ́ yî, à ńfẹ́ láti wọ̀ wá pọ̀lú aṣọ ilé ọ̀run. 3 À ǹgbèrò èyí nítorípé wí wọ̀ọ́ a kò ní wà ní ìhòhò.. 4 Nítòótọ́ bí a bá wà nínu àgọ́ yî, awa nke irora, pẹ̀lú àjàgà. A kò fẹ́ wà láì wọ aṣọ, nítorípé kí a bá lè gbé ohun tí kò ṣe kókó mì nípasẹ̀ ayé. 5 Ọlọ́run ni ẹni tí ó mú wa gbáradì fún àwọn ǹkan yî, tó fún wa ní Ẹmí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ ohun tí yóò wà. 6 Nítorínà máa ní ìgboyà ní gbàgbogbo. Ní ìyára pé bí à wa bá wà ní ilé ní ti ara, awá jìnà sí Ọlọ́run. 7 Nítorí pé àwá ńrí nípa ìgbàgbọ́, kìí ṣe nípa ti ara. 8 Nítorínà àwá ní ìgboyà. Àwa yóò kúkú jìnà sí ara a ó sì wà ní ile pẹ̀lú Ọlọ́run. 9 Àwá sì fi ṣe ìlépa wa, bóyá a wà nílé tàbí lájò, láti tẹ́ ẹ lọ́rùn. 10 Nítorí a gbọdọ̀ farahàn ní ìjǒkó ìdájọ́ Krístì, kí ẹnikànkan le gba oun tí ó yẹẹ́ nípa ohun to ṣe ni ti ara, dáradára tàbí búburú. 11 Nítorínà, mímọ ìbẹ̀rù Olúwa, a gba ènìyàn ní ìyànjù. Ohun tí a jẹ́ jẹ́ kedere sí Ọlọ́run. Mo lérò pé ó sì tàn gbangba sí ọkàn rẹ 12 A kò fẹ́ gbà yín ní íyànjú si láti rí wa bí olóòtó. Dípò, à ń fún yín ní ìdí láti lé sògó nínu wa, kí ẹ ba lè ṣe ìdáhùn fún àwọn tó ń gbéraga nípa ìrírí ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun tó wà nínú ọkàn. 13 Nítorí a kò wà ní ọgbọ́n wa, fún Ọlọ́run ni; bí a bá ti lẹ̀ wà ní ọgbọ́n wa, nítorí yín ni. 14 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ńkún wa, nítorí àwá mọ́ dájú pé: Ẹnìkan yí kú fún gbogbo enìyàn, àtí pé nítorínà gbogbo enìyàn ti kú. 15 Ókú fún gbogbo enìyaǹ, nítorí kí àwọn tó wà láyé ma gbé ayé fún ara wọn mọ́ ṣùgbón fún òun tó kú nítorí wọn tí a sì gbé dìde. 16 Nítorí ìdí èyí, láti isìsíǹyi lọ a kò dájọ́ fún ẹnikẹ́ni ní ìlànà ti enìyàn, bí a ti lẹ̀ rí Krístì bá yẹn ní gbà kan rí. Ṣùgbọ́n nísisìnyí a kò dájọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ànà yi mọ́. 17 Nítorínà, bí ẹnikẹ́ni bá wà nínu Krístì, ó ti di àtúnbí. Ohun átijọ́ ti kọ já lọ. Wòó, wọ́n ti di tuntun. 18 Àwọn ǹkan wọ̀nyí ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ó gbà w´ padà sí ọ̀dọ rẹ̀ nípasẹ̀ Krístì, o si fun wa ni (ministry) ìràpàdá. 19 Ó jẹ́ pé, ninú Krístì Ọlọ́run ra ayé padà sí ọ̀dọ rẹ́, láì ka ẹ̀ṣẹ̀ wọn lòdì sí wọn. Ó ń fi lé wa lọ́wọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìràpadà. 20 Nítorínà a ti yàn wá gẹ́gẹ́ bí aṣojú Krístì, bíi pé Ọlọ́run ńfi ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ wa. Àwa ń bẹ̀ yín, nítorí ti Krístì: Ẹ di ìràpadà sí Ọlọ́run!" 21 Ó fi Kristi se irubo fun ẹ̀ṣẹ̀ wa. Òun ni ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀ ri'. Ó ṣe èyí kí a bá le di ẹni mímọ́ Ọlọ́run nínu rẹ̀.