1 Nísisìnyí, nítorí a ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ yî, àti bí a ti gba àánú, a kó wà ní ìrẹ̀wẹ̀sì 2 Dípò bě, ati ko ọ̀nà tí ó ń dójú ti ni tí ó wà ní ìpamọ́. a kò gbé nípa ọgbọ́n àrékérekè, a kò sì di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ní ònà tí ó tọ́. Nípa fífi òtító hàn, a fi ara wa ṣe àpèjúwe okàn gbogbo ènìyàn ní iwájú Ọlọ́run. 3 Ṣùgbọ́n bí ìhìnrere wá bá ní ìbòjú, ójẹ́ ìbòjú fún àwọn tí ń ṣègbé. 4 Ní ìhà wọn, ọlọ́run ayé yî tí fọ́ ojú ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́. Fún ìdí èyí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere ògo Krístì, tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run. 5 Ṣùgbọ́n a kò sọ nípa tiwa, bíkòse Jèsú Krístì bí Olúwa, àti àwa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ̀ rẹ nítorí Jésù. 6 Nítorí Ọlọ́run ló sọ èyí, "Ìmọ́lẹ̀ ó tàn jáde nínú òkùnkùn." Óti tân sí ọkàn wa, láti fi ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run bí ní iwájú Krístì Jésù. 7 Ṣùgbọ́n a ní ìsura yí ní ife amọ̀, kó lè di ìfihàn pé agbára ńlá jẹ́ ti Ọlọ́run kìí ṣe ti wa. 8 A pọ́n wa lójú ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò borí wa. A rí ìdàmú ṣùgbọ́n kò kún fún ìbànújẹ́. 9 A pọ́n wa lójú ṣùgbọ́n aò di ìkọ̀sílẹ̀, A lù wá mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n aò pa wà run. 10 À ńgbé ní ara wa ikú Jésù, kí ayé Jésù le di ìfarahàn ní ara wa. 11 Àwa tí a wà láàyè ńgbé ikú Jésù káàkiri ní ara wa, nítorí kí ayé Krístì ba lè di ìfihàn ní ẹran ara wa. 12 Nítorínì ikú ńsisẹ́ ní inu wa, ṣùgbọ́n ìyè ǹṣiṣẹ́ ni inú rệ. 13 Sùgbọ́n àwa ní ẹ̀mí ìgbàbọ́ kannà pẹ̀lú èyí tí a kọ́: "Mo gbàgbọ́, mo sì sọ." Àwa sì gbàgbọ́, a sì sọ pẹ̀lú. 14 A mọ̀ pé ẹni tó gbé Jésù Olúwa yóò gbé àwa nǎ pẹ̀lú Jésù. Àwá mọ̀ pé yó mú wa pẹ̀lú rê sí iwájú Rè. 15 Gbogbo rẹ̀ jẹ́ nítorí rệ, bí ore-ọ̀fé ti tàn sí ènìyàn púpọ̀, ìdúpẹ́ yó gbòrò si sí oòo Olúwa. 16 Àwa kò di aláì ní ìgboyà. Bó ti lè jẹ́ pé à ńṣègbé lọ ní ìta, àń yí padà lójojúmọ́ ní inú wa. 17 Fún àkókò yí, ìpèníjà ìmọ́lẹ̀ ńmu wa gbáradì fún ẹ̀rù ògo ayérayé ní gbogbo òdìnwọ̀n. 18 Ṣùgbọ́n a kò ńwo ohun tí ojú le rí, bíkòṣe àwọn ohun ti akò lè rí. Àwọn ohun tí a lè ri jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọ́n àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ ti ayérayé.