Orí Kẹta

1 Ǹjẹ́ a tún ti bẹ̀rẹ̀ láti màa yin arawa bí? Àwa kò ní lò iwe ìyìn sí yin tàbí láti ọ̀dọ yín, bí àwọn ènìyàn kan, ṣé aní? 2 Ẹ̀yin fún ra yín ni ìwé ìyìn wa, tí a kọ si ọ̀kan wa, tí àwọn ènìyàn mọ̀ tí wọ́n sì kà 3 Ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin ni ọ̀rọ̀ láti Krístì, tí a fi fún wa. A kò kọ́ pẹ̀lú íǹkí ṣùgbọ́n nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè. A ò kọ́ sóri pátákó òkúta, bíkòṣe sí orí pátákó okàn àwọn ènìyàn. 4 Àti èyí ni ìgboyà tí aní nípasè Krístì níwáju Ọlọ́run. 5 A ò kójúòsùnwọ̀n nínú arawa láti sọ ǹkankan tí ó ń wá láti ọ̀dọ̀ wa. Dípò bẹ́ẹ̀, Kíkójuòsùnwọ̀n wa wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 6 Ọlọ́run ni ó jẹ́ kí ó ṣeéṣe fún wa láti jẹ́ ìránṣẹ́ májẹ̀mú titun. Èyí kìí ṣe májẹ̀mú ti a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ọ̀rọ̀ náà ńpa ni, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí ń fún ni ní ìyè. 7 Nísisìnyí iṣẹ́ tó ṣẹ̀dá ikú-tí a kọ sí orí òkúta-wá ní pasẹ̀ ògo tí àwọn ọmọ ísrẹ́lì kò le fi taratara wo ojú Mósè. Èyi jẹ́ nítorí ògo tí ó wà ní ojú rẹ̀, ògo tó ńkú rò díèdíè 8 Báwo ni ògo iṣẹ́ tí Ẹ̀mí ńse kò bá tirí? 9 Nítorì bí iṣẹ́ ìdálẹ́bi bá ní ògo, báwo ni iṣẹ́ ìwà mímọ́ kì bá tirí nínú ògo! 10 Nítorí nítòótọ́, ohun tí a ti ṣe lógo rí kò ní ìṣelógo nínú èí mọ́, nítorí ògo tí ó taá yọ. 11 Ṣùgbọ́n bí èyí tó ńkọjá bá nì ògo, báwo ni ohun tó wà títí ò bá ti ní ògo! 12 Nítorí a mú àyà le, a ní ìgboyà. 13 Àwa kò rí bí Mósè, ẹni tó fi òǹdè sí ojú, kí àwọn ọmọ ísrẹ́lì má lè wòó ní ojúkojú ògo ìkẹyìn tí ó nkọjá lọ. 14 Ṣùgbón a de okàn wọn. Títí di ọjọ́ òní òǹdè yí wǎ nínu kíka ìpè májẹ̀mú àtijọ́. Ẹ̀yí kò ṣí sílẹ̀ sí wa, Nítorí nínu Krístì nìkan ni a ti mu kúrò. 15 Sùgbọ́n nísinsìyí, ohunkóhun tí Mósè ka, òńdè wǎ ní ọkàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n bí èyàn bá yí padà sí Ọlọ́run, òǹdè nǎ di kíká kúrò. 17 Nísisìnyí Ọlọ́run ni Ẹ̀mí nà. Ní bi tí Ẹ̀mí Ọlọ́run bá wà, ítúsílẹ̀ wà ní bẹ̀. 18 Nísisìnyí gbogbo wa, pẹ̀lú ojú tí kò ní òǹdè, rí ògo Ọlọ́run. À ti yíwàpadà sínú ògo yî láti ìpele kan sí òmíràn, gẹ́gẹ́ bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ Ẹ̀mí nà.