Orí Kejì

1 Nítorínà mo pinu nítèmi làti ma wá sí ọ̀dọ yín ní ọ̀nà tí yóò mú ìnira bá yín. 2 Tí mo bá mú ìnira bá yín, ta ni yó pẹ̀tù sí mi nínú bí kìí ṣe ẹni tí a nilára nípasẹ̀ mi 3 Mo kọ èyí bí mo ti ṣe nítorí nígbàtí mo bá wá sí ọ̀dọ yín mi ò rí ìnira ní ọ̀dọ àwọn tí ó yẹ kó mú inú midùn. Mo ní ìgboyà nínu gbogbo yín pé ayọ̀ mi jẹ́ ìkanǎ pẹ̀lú ayọ̀ tí ẹ ní 4 Nítorípé mò ńkọ èyí sí yín nínú ìpọ́njú ńlá, pẹ̀lú ìpòrùru okàn, àti omijé tó pọ̀. Mi ò fẹ́ fa ìnira fún yín. Dípò bẹ́ẹ̀, mo fẹ́ kí ẹ mọ bí ìfẹ́ tí mo ní síyín ti jínlẹ̀ sí. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá ti fa ìnira fún yín, kò fá fún èmi nìkan, bíkòṣe ní ànà díẹ̀-lá ti ma so bó ti burú tó-sí gbogbo yín. 6 Ìjìyà irú ẹni bẹ́ẹ̀ nípasẹ́ gbogbo ènìyàn tó nìkan. 7 Ṣùgbọ́n nísinsìyí dípò ìjìyà, ẹ ṣe ìdáríjì kí ẹ sì pẹ̀tù si nínú. Ẹ ṣe èyí kí ọkàn rẹ̀ má ṣe kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì. 8 Mo gbà yín ní ìyànjú pé kí ẹ fi ìfẹ́ yín hàn si ní gbangba. 9 Ẹ̀yí ni ìdí tí mo ṣe kọ èyí, kí mo ba lè dǎn yín wò láti mọ̀ bó yá ẹ ṣe ìgbọràn sí gbogbo ǹko. 10 Bí ẹ bá dáriji ẹnikẹ́ni, mo dáríji ẹni nǎ pẹ̀lú. Ohun tí mo ti dáríjì-bí mo bá dáríji ńkankan-ó ti di ìdáríjì nítorí yín ní iwáju Krístì. 11 Ó rí bẹ̀ nítorí kí sátánì má ṣe tàn wá. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ èro rẹ̀. 12 Ilẹkùn kan ṣí sí lẹ̀ fún mi nípasẹ̀ Ọlọ́run nígbàtí mo wá sí orílẹ̀ èdè Tróásì láti wààsù ìhìnrere Krístì níbẹ̀. 13 Bákanà, okàn mi pòrúru, nítorí mi ò rí arámi Títù níbẹ̀. Mo sì fi wọ́n sílẹ̀ mo si padà sí Makidónìa. 14 Ṣùgbọ́n kí ọpẹ́ jẹ́ ti Ọlọ́run, tí nínu Krístì ń tọ́ wa láti borí. Nípasẹ̀ wa à ń tan òórún dídùn ìmọ̀ rẹ̀ ní bi gbogbo. 15 Nítorí sí Ọlọ́run a jẹ́ òórùn dídùn Krístì, pẹ̀lú àwọn tí a gbàlà àti láàrin àwọn tí ńṣègbè. 16 Sí àwọn ènìyàn tí ń ṣègbé, ójẹ́ òórún làti ikú sí ikú. Sí àwọn tí a ńgbàlà, ójẹ́ òórùn làti ìyè sí ìyè. Tani ó yẹ fún àwọn ǹkan yìí? 17 Àwa kò dàbí ènìyàn púpọ̀ tí ó ta ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún èrè kan. Dípò béè, pẹ̀lú èrò mímọ́, a sọ̀rọ̀ nínú Krístì, bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwáju Ọlọ́run.