1 Nítorínà, níwọǹ ìgbà tí Kristi ti jìyà nínú ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe béè. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nínú ara ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ 2 Fuń ìdí èyí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì yóò gbé ìgbé ayé rẹ̀ tókù nínú ara láti wu ènìyaǹ, bíkòṣe láti wu Ọlọrun. 3 Nítorí àsìkò tí rékọjá fuń àwon kèlfèrí láti ṣẹ ohun tí ó wù wọ́n - ìwà ara, ìfẹ́ gidigidi, imutípara, ayé ìjẹkújẹ, àríyá líle, àti ìbòrìṣà tí ó jẹ́ ìríra 4 Nísisìyí, ójẹ́ ohun ìjọjú fuń wọn pé ẹkò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọń sì ń sọ̀rọ̀ ibi sí yín 5 Wọ́n óò jíyìn fuń ẹni tí ó ti gbáradì láti ṣe ìdájọ alààyè àti òkú 6 Fuń ìdí èyí ni a ṣe wàásù ìhìnrere fuń àwọn tí óti kú pẹ̀lú, pé bí ótilè jẹ́ wípé ati ṣe ìdájọ́ wọn nínú ara gẹ́gẹ́bi ènìyaǹ, síbẹ̀ wọ́n ó wà láàyè ninu ẹ̀mí sí Ọlọrun. 7 Òpin ohun gbogbo súnmó ìtòsí. Nítorínà ẹwà ní ọkaǹ pípé, kí ẹ sì fi ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé ayé e yiń nínú àdúrà 8 Ju ohun gbogbo lọ, ẹní ìfẹ́ tí ó yé kooro sí ara yiń, nítorí ìfẹ́ a máa borí òpòlopò ẹ̀ṣẹ̀ 9 Emá a gba ara yiń làlejò láì sí ìkuǹ sínú. 10 Bí olúkúlukù yiń ti rí ẹ̀buǹ gbà, emáa fi èbuǹ un yiń ran ara yiń lọ́wọ́. Ẹ má a ṣe èyìí gẹ́gẹ́bi ìríjú orísìíorísìí ẹ̀bùn ọ̀fé Ọlọrun 11 Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó sọ ọ́ bí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránsẹ́, kí ó ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára tí Ọlọrun fuń un. Nínú ohun gbogbo, ẹ má a hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi. 12 Ẹ̀yin olùfẹ́ ẹ̀ mi, ẹ má ṣẹ jẹ́ kí ìdánwò nínú iná èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i yín kí ójo yín lójú, bí ẹni pé ó jẹ́ ohun tí ojú kò rírí. 13 Kàkà bẹ́ẹ̀ bí ó ti wù kí ẹ̀yín ti jìyà nítorí Jesu Kristi tó, ẹ máayò nísinsìnyí kí ẹ̀yin bá le yọ̀ bákan náà nígbàtí Jesu Kristi bá farahàn nínú ògo rẹ̀ 14 Bí wọ́n bá bú ọ nítorí orúkọ Kristi, alábùkún fún ni ìwọ, nítorí ẹ̀mí ògo àti ẹ̀mí Ọlọrun ti bà lẹ́ ẹ yín lórí. 15 Ṣùgbón, ẹ má ṣẹ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà gẹ́gẹ́ bí apànìyàn, tàbí olè, tàbí ẹni ibi, tàbí ẹni tí ń tojú bọ nǹkan-oní-nǹkan 16 Ṣùgbón tí ẹnikẹ́ni bá ń jìyà gẹ́gẹ́ bí Krìstíanì, kí ojú má ṣe tì í, kàkà bẹ́ẹ̀ kí ẹ má a yin Ọlọrun lógo fún orúkọ Krìstíanì tí a ń pè mọ́ọ yín. 17 Nítorí àsìkó titó tí ìdájó yóò bẹ̀rẹ̀ nílé Ọlọrun. Tí ó bá bẹ̀rẹ̀ lórí i wa, báwo ni yóò ti rí fún àwon tí kò gba ìhìnrere Ọlọrun gbó. 18 Tí ó bá jẹ́ wípé agbára káká lafi gba olódodo là, bá wo ni yóò ti rí fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ 19 Nítorínà, kí gbogbo àwọn tí ó bá ń jìyà nítorí ìfẹ́ Ọlọrun kí wọ́n fi ọkàn wọn lé ẹlẹ́dàá olótìító lọ́wọ́ nípa rere ṣíṣe.