1 Bákannáà, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ aya, ẹ tẹríba fún ọkọ yín. Ẹ máa ṣẹ ẹ̀yìí, tó bẹ̀ tí wọn bá ti lè ṣẹ àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Krístì, ẹ ó jérè okàn wọn nípa ìwà àti ìṣe yín. 2 Nítorí tí wọn ó ti rí ìwà òtítọ́ yín pẹ̀lú ìtẹríba. 3 Kìí ṣẹ nípa ṣíṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́: nípa irun dídì, nípa wúrà, tàbí nípa aṣọ ìgbàlódé. 4 Bíkòṣe nípa ẹ̀dá ẹni ti inú ọkaǹ, àti ẹwà tí kìí ṣá ti ìwà pẹ̀lẹ́ àti ti ẹ̀mí ìdákẹ́jẹ́, ẹyí tí ọ́ ṣe iyebíye níwájú Olúwa. 5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin mímọ́ ti ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọń ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹríba fún ọkọ wọn 6 Báyìí ni Sárà ṣe gbọ́ran sí Ábráhámù lẹ́nu ó sì pèé ní olúwaà mi. Ẹ̀yin tÍ di ọmọ rẹ̀ bí eyin bá nse ohun tí o dára tí èyin kò sì bẹru ibi. 7 Bákannáà ni kí ẹ̀yin ọkọ ṣẹ bá ìyàwó yín gbé pèlú òye, gẹ́gẹ́bí aláìlera ẹ̀dá obìnrin. Ẹ bọ̀wọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́bí alábàpín nínú ẹ̀bùn ẹ̀mí. Ẹ ṣẹ eléyìí kí àdúrà yín má baá ní ìdènà. 8 Lákòtán, gbogbo yín, ẹ́ wà ní ọkàn kan, ẹ má a sàánú, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín gẹ́gẹ́bí ará, ẹ ní ọkàn tútù pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ 9 Ẹ má fi ibi san ibi, tàbí èébú fún èébú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre, nítorí fún ìdí èyí laṣẹ pè yín, kí ẹ̀yin báa lè jogún ìbùkún 10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá yàn láti fé ìyè, tí ó sì fẹ́ rí ọjọ́ rere, óní láti pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìsọ̀rọ̀ ibi, kí ó sì pa ète rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìsọ̀rọ̀ ètàn. 11 Kí ó yí padà kúrò nínú ìwà búburú sí rere ṣíṣe. Kí ó máa wá àláfíà, kí ó sì máa lé e. 12 Nítorí ojú Olúwa rí olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ẹ wọn. Ṣùgbọ́n ojú Olúwa lòdì sí àwon tí ńse búburú. 13 Tani ó ṣe yín ní ibi, tí ẹ̀yin bá nfé láti ṣe rere. 14 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá ń jìyà nípa òdodo ṣíṣe, ìbùkún ni fún yín. Ẹ má ṣẹ bẹ̀ru oun tí wọ́n ńbẹ́rù, ẹ má sì ṣe dàmú. 15 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹya Jésù Kristi sọ́tọ̀ sí mímọ́ nínú ọkàn yín. Ẹ gbáradì láti dá gbogbo àwọn tí ó bá béèrè ìdí tí ẹ ṣẹ ní ìgbékèlé nínú Ọlọ́run lóuǹ. Ẹ ṣẹ eléyìí pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àtí ìtẹríba 16 Ẹní ọkàn ẹ̀rí tí ó dára, kí ojú báa lè ti àwọn tí ó bá ń sọ́rọ̀ lòdì sí ìgbé ayé rere yiń nínú Kristi, nítorí wọ́n ń sọ́rọ̀ lòdì sí yiń bí ẹni tí ńṣiṣẹ́ ibi. 17 Ó sàn, tí ó bá wu Ọlọ́run fuń yiń láti jìyà fuń rere ṣíṣe, ju kí ẹ jìyà fuń ibi ṣíṣe. 18 Kristi pẹ̀lú jìyà ní ẹ̀kan fuń ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó jẹ́ olódodo jìyà fuń wa, àwa tí a jé alaísòdodo, kí ó báa lè múwa wá sí ọ̀dọ Ọlọ́run. A paá nínú ara, a sì múuwà láayè nípa ti ẹ̀mí. 19 Nípa ti ẹ̀mí, ó lọ wàásù fuń àwọn ẹ̀mí tí ati fi sínú-un túbú 20 Wọ́n ṣe aláìgbọ́ran nígbà tí sùúrù Ọlórun ńdúró nígbà ayée Noah, nígbà tí ó kan okọ̀, tí Ọlọ́run gba àwọ́n mẹ́jọ là kúrò nínú àgbàrá omi. 21 Èyí ni àpẹrẹ ìtẹ̀bọmi, èyí tí ógbà yín là nísinsìnyí kì íse nípa fífọ ìdọ̀tí kúrò lára, ṣùgbón nípa níní ọkàn ẹ̀rí tí ó dára sí Ọlọ́run èyí tí ó wà nípaàsẹ ti àjíǹde Jesu Kristi. 22 Kristi wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó lọ sínú ọ̀rún. Ańgẹ́lì, àwọn àṣẹ, àti agbára gbọ́dọ̀ tẹríba fún un.