Orí Kejì

1 Nítorínà ẹ fi gbogbo ìwà búburú, ẹ̀tàn, àgàbàgebẹ̀, ìlàra àti gbogbo ẹ̀gàn sílẹ̀. 2 Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìkókó, ẹ máa pòǹgbẹ fún wàrà mímọ́ ti ẹ̀mí, kí ẹ̀yin nípasẹ̀ rẹ̀ le dàgbà nínú ìgbàlà, 3 bí tí ẹ̀yin bá ti tọ́ọwò pé rere ni Olúwa. 4 Ẹwá sí ọ̀dọ Rẹ̀, ẹni tíí ṣe òkúta ìyè, tí ènìyàn ti kọ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run ti yàn tí ósì ṣe iyebíye sí i. 5 Ẹ̀yin náà sì dàbii òkúta ìyè tí a kọ́ láti jẹ́ ibùgbé fún ẹ̀mí, láti jẹ́ olórí àlùfà mímọ́ tí ń rúbọ ẹ̀mí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run nípa sẹ̀ ẹ Jésù Krístì. 6 Ìwẹ́ mímó sọ pẹ́: "Sáàwóó, èmí filẹ́lẹ̀ ní Síónì, òkúta, igun-ilé, tí a yàn, tí ó sì ṣe iyebíye. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́, ojú kì yóò tíì. 7 Iyì jẹ́ẹ́ tí ẹ̀yin tí ẹ gbàágbọ́. Ṣùgbọ́n, "Òkúta tí àwọn tí ńkọ́ ilé ti kọ̀ sílẹ̀ tí di pàtàkì òkúta igun-ilé"- 8 àti "òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta ìsubú." Wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ náà tí a yàn wọ́n fún. 9 Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn tí a yàn, olú-àlùfáà, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún ìní Ọlọ́run, kí ẹ̀yin kí ó léè kéde iṣẹ́ ìyanu enití ó pẹ̀ yín nínú òkùnkùn sí inú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. 10 Nígbà kan rí ẹ̀yin kò jẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n nísinsìnyi, ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. Ẹ̀yin kò rí àánú gbà, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ ti rí àánú gbà. 11 Àyànfẹ́, mo pẹ̀ yín gẹ́gẹ́ bíi àlejò àti alárìnkiri láti yàgò fún ìfẹ́ ara, tí ó ń bá ọkàn yín jagun. 12 Ó yẹ kí ẹ jẹ́ oníwàrere ní àrin àwọn kèfèrí, nítorí bí wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ yín bí olùse búburú, wọ́n yóò mà kíyèsí isẹ́ rere yín wọn ó si maa yin Ọlọ́run ní ojọ́ dídé rẹ̀. 13 Ẹ gbọ́ràn sí gbogbo àṣẹ ènìyàn nítorí Olúwa. Ẹ gbọ́ràn sí ọba bí ẹni tí ó ga jùlọ, 14 àti àwọn gómìnà tí a rán láti fìyà jẹ àwọn asebi àti láti yin àwọn tí ó se rere. 15 Nítorí èyí ní ìfẹ́ Ọlọ́run, pẹ́ nípa ṣíṣe rere e ó pa àwọn òmùgọ̀ ènìyàn lénu mọ́. 16 Gégé bí olómìnira ènìyàn, ẹ máṣe lo òmìnira yín gégé bíi ìbòjú fún búburú, ṣùgbọ́n, ẹ dà bi ìránsé Ọlọ́run. 17 Ẹ bu ọlá fún gbogbo ènìyàn. Ẹ ní ìfẹ́ ará. Ẹ bẹ̀ru Ọlọ́run. Ẹ bu ọlá fún ọba. 18 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀. Ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá tí ó dára tí ó sìní ìrẹ̀lẹ̀ nìkan, Ṣùgbọ́n sí àwọn ọ̀gá onírira pẹ̀lú. 19 Oní ìyìn bí ẹnikẹ́ni bá farada ìrora nígbà ìpọ́njú àìtọ́ nítorípẹ́ ó mọ Ọlọ́run. 20 Ǹ jẹ́ kíni èrè tí ó wa níbè bí o bá sẹ̀ tí o sì ń farada ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀? Ṣùgbọ́n bí o bá ti se rere, tí ìpónjú sí mú ọ nínú ìjìyà, èyí ní ìyìn ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 21 Nítorí èyí ní a pẹ̀ yín, nítorí Krístì náà jẹ ìyà fún yín. Ó fi àpẹẹrẹ lelẹ̀ fún ọ láti tẹ̀lé ipa-ọ̀na Rẹ̀. 22 Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ni a kò sì bá ẹ̀tàn kan ní ẹnu Rẹ̀. 23 Nígbàtí a kẹ́gàn Rẹ̀, kò kẹ́gàn padà, ṣùgbọ́n, ó fi ara Rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí yóò dájọ́ dáradára. 24 Òun tìkara Rẹ̀ gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ara Rẹ̀ lọ sí orí igi, kí àwa máá bà nípa nínú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, àti pẹ́ kí a lè máá gbé fún òdodo. Nípa ojú-ọgbẹ́ rẹ̀ ní a múu yín láradá. 25 Gbogbo yín di alárìnkiri bíi àgùntàn tí ó sọnù, ṣùgbọ́n báyíì ẹ tí padà sí ọ̀dọ̀ Olùsọ́-àgùntàn àti Olùtọ́jú ọkàn yín.