ORÍ KAÀRÚŃ

1 Ẹ̀mi ń rọ àwọn àgbà láàrín yín, èmi gẹ́gẹ́bí àgbà bákannáà. Èmí jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀rí sí ìjìya Krístì, èmí sì jẹ́ alábàpín nínú ògo tí yóò farahàn. 2 Nítorínà mo rọ̀ yín èyin àgbà, ẹ má a tọ́jú agbo Ọlọrun tí ńbe láàrín yín. Ẹ má a ṣẹ ìtójú u wọn, kìí ṣẹ bí àfipáṣe, ṣùgbón tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe ṣe ìtọ́jú u wọn nítorí owó tí kò tònà tí ẹ ó rìí gbà, ṣùgbón kí ẹ ṣẹ́ tokàntokàn 3 Ẹ má ṣẹ ṣẹ bí aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ ẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ àpẹrẹ rere fún agbo yín. 4 Nígbà tí Olú Olùṣó-àgùntàn bá farahàn, ẹ óò gba adé ògo tí kì í ṣá. 5 Bákannáà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀ kí ẹ má a ran ara yín lọ́wọ́. Nítorí Olorun lòdì sí àwon agbéraga, o sì fi ore ọ̀fẹ́ ẹ rẹ̀ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ 6 Nítorínà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ẹ ọwọ́ agbára Ọlọrun, òun yóò sì gbé e yín ga ní àkókò tí ó yẹ. 7 Gbé gbogbo àníyàn rẹ lé e, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún. 8 Ẹ jẹ́ alárònújinlè, ẹ kíyè sára. Èṣù tí í ṣe ọ̀tá a yín ń rìn kiri, bí i kìnnìuń, ó ń wá ẹni tí yóò pajẹ. 9 Ẹ ta kò ó. Ẹ jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yín. Kí ẹ mọ̀ wípé, àwọn onígbàgbó ẹgbẹ́ ẹ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà nínú ayé. 10 Lẹ́yìn ìgbà tí e bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun gbogbo ọ̀re-ọ̀fẹ́, tí ó pè yín sínú ògo ayérayé tí ń bẹ nínú Kristi, yóò sọ yín di pípẹ́, yóò fi ẹsẹ̀ ẹ yín múlẹ̀, yóò si fún un yín ní okun. 11 Òun ni ìjọba wà fún láilái. Àmín. 12 Èmí ka Sílfánù sí gẹ́gẹ́ bíi arákuǹrin olóòtọ́, èmí sì ti kọ ìwé kúkurùú yí sí i yiń nípaàsẹ rè. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé ore ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹdúró lórí ohun tí mo kọ. 13 Arábìnrin tí ó wà ní Bábílónì, tí a ti yàn pẹ̀lúu yín ń kí i yín. Bákannáà Máàkù ọmọ ọ̀ mi ń kíi yín. 14 Ẹ kí ara yÍn pẹ̀lú ìfẹnukonu ìfẹ́. Kí àlááfìa kí ó wà pẹlu gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ti Kristi.