ORÍ ÌKẸẸ̀RIN

1 Olùfẹ́, ẹ máse gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ dán àwọn ẹ̀mì wò lati ri wípé lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ti wá, nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì èké ni wọ́n ti wọ inú ayé. 2 Nípa èyí ni ẹ ó fi dá Ẹ̀mí Ọlọ́run mọ̀- gbogbo ẹ̀mí tí ó bá jẹ̀wọ́ pé Jésù Krístì wá nínú ẹran ara ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 3 àti gbogbo ẹ̀mí tí kò bá jẹ́wọ́ Jésù kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Èyí jẹ́ ẹ̀mí asòdì sí Krístì, tí ẹ ti gbọ́ pé ó ńbọ̀, ó sì ti wà nínú ayé báàyí. 4 Ẹ̀yín wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọmọ ọ̀wọ́n, ẹ̀yín sì ti sẹ́gun wọn, nítorípé ẹnití ó wà nínú yín ju ẹnití ó wà nínù ayé lọ. 5 Láti inú ayé ni wọ́n ti wá: nítorínáà, ohun tí wọ́n nsọ ti inú ayé wá, ayé sì ntẹti sí wọn. 6 Láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwa ti wá. Ẹnikẹ́ni tí ó mọ Ọlọ́run ńtẹ́tí sí wa. Ẹnití kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò tẹ́tí sí wa. Nípa èyí ni a fí ńmọ ẹ̀mí òtítọ̀ àti ẹ̀mí àsìse. 7 Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á ní ìfẹ́ ara wa, nítorí ìfẹ́ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ ni a bí làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì mọ Ọlọ́run. 8 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ìfẹ́, kò mọ Ọlọ̀run, nítorípé Ọlọ́run ni ìfẹ́. 9 Nítorí ìdí èyí ni a se fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn láàrin wa, pé Ọlọ́run ti rán Ọmọkùnrin rẹ̀ kansoso sínú ayé kí á ni le ni ìyè nítorí rẹ̀. 10 Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kìí se pé àwa ní ìfẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Oun ní ìfẹ́ wa, àti pé Oun rán ọmọ rẹ̀ láti di ètùtù fún àwọn ẹ̀sẹ̀ wa. 11 Olùfẹ́, bí Ọlọ́run bá ní ìfẹ́ wa tó báàyí, àwa pẹ̀lú gbọdọ̀ ní ìfẹ́ ara wa. 12 Kòsí ẹnití ó ti rí Ọlọ̀run ri, bí àwa bá nì ìfẹ́ ara wa, Ọlọ́run wà nínú wa síbẹ̀, a sì sọ ìfẹ́ rẹ di pípé nínú wa. 13 Nípa báàyí ni a ó fi mọ̀ pé àwa wà nínú rẹ ati Oun nínú wa, nítorí tí Ó ti fún wa nínú Ẹ̀mí Rẹ̀ 14 Bákanáà, àwa ti rí a sì ti jẹri pé Bàbá ti rán Ọmọ náà lati jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé. 15 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run náà, Ọlọ́run ńgbé nínú rẹ̀ àti oun nínú Ọlọ́run. 16 Bákanáà, àwa ti mọ̀, a sì ti gba ìfẹ́ tí Ọlọrun ní fún wa gbọ́. Ọlọ̀run ni ìfẹ́, àti ẹnití ó bá wà nínú ìfẹ́ yi wa nínú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà nínú rẹ̀. 17 Nítorí èyí, ìfẹ́ yi ti di pípé larin wa, kí àwa leè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́, nítorí bí Oun ti rí bẹ́ẹ̀ náà ni àwá rí ní aiyé yi. 18 Kòsí ẹ̀rù nínú ìfẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ pípé ńti ẹ̀rù síta, nítorípé ẹ̀rù ní se pẹ̀lú ìjìyà. Sùgbọ́n ẹnití ẹ̀rù ńbà kò ti di pípé nípa ìfẹ́. 19 A ní ìfẹ́ nítorítí Ọlọ́run ni Ó kọ́kọ́ ní ìfẹ́ wa. 20 Bí ẹnikẹ́ni bá wípé " Mo ní ìfẹ́ Ọlọ́run" tí ó sì kóìríra arákùnrin rẹ̀, òpùró ni. Nítorípé, ẹnití kò ní ìfẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí ó rí, kò leè ní ifẹ́ Ọlọ́run tí kò rí. 21 Bákanáà, èyí ni òfin ti a gbà lati ọ̀dọ̀ rẹ̀: ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ arákùnrin rẹ̀.