1 Ẹnikẹ́ni tí o gbàgbọ́ pé Jésù ni Krístì a bíi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹnikẹ́ni tí o bá ni ìfẹ́ bàbá kan òun pẹ̀lú fẹ́ ọmọ tí o bí. 2 Nítorí èyí àwá mọ̀ pé a fẹ́ràn àwọn Ọmọ Ọlọ́run: nígbà tí àwa fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn òfin rẹ̀ tí a ń fi sí ìse. 3 Èyí ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run: wípé a pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Àti pé àwọn òfin rẹ̀ kò nira láti mú lò. 4 Ẹnikẹ́ni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá sẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìsẹ́gun to sẹ́gun ayé: ìgbàgbọ ọ wa. 5 Ta ni ẹni tó sẹ́gun ayé? Ẹni tí o gbàgbọ́ pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run ni. 6 Èyí sì ni ẹni tí o wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀: Jèsú Krístì. Kò sì wá nípa omi nìkan sùgbọ́n nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. 7 Nítorí ohun méta ni ó se ẹlẹ́ẹ̀rí: Ẹ̀mí, omi ati ẹ̀jẹ̀ 8 Àwon mẹ́taà yí fi ohun sọọ̀kan. 9 Tí a bá gbà ẹ̀rí ènìyàn gbọ́, ẹ̀rí Ọlọ́run ga ju tì èníyàn lọ. Nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí, pé ó jẹẹ̀rí nípa Ọmọ rẹ̀. 10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ̀rí yi nínú ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́ ti pèé ní òpùrọ́ nitorí kò gba ẹ̀rí ti Ọlọ́run gbọ́ nípa Ọmọ rẹ̀ . 11 Àti pé ẹ̀rí naa nìyí: Ọlọ́run fún wa ni ìyè ayérayé, àti pé iyè ayérayé naa wa nínú Ọmọ rẹ̀. 12 Ẹni tó ní Ọmọ ní ìyè. Ẹni tí kò ní Ọmọ Ọlọ́run kò ní ìyè. 13 Mo ti kọ àwọn ǹkán wọ̀nyí síi yín kí ẹ̀yin le mọ̀ pé ẹní ìyè ayérayé - fún ẹ̀yin tí o gbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ Ọlọ́run. 14 Pẹ̀lú, èyí ni ìdánilójú tí a ní nínú rẹ̀ pé bí a bá bèrè ohunkóhun nípa ìfẹ́ẹ rẹ̀ oúń gbó wa 15 Pẹ̀lú, tí a bá mọ̀ pé oùń ń gbọ́ wa - ohunkóhun tí a bá bèrè lọ́wọ́ ọ rẹ̀ - a mọ̀ pé a rí ohunkóhun tí a bá bèrè lọ́wọ́ ọ rẹ̀ gbà. 16 Bí ẹnikẹ́ni bá ri arákùnrin rẹ kan tí o ń dá ẹ̀sẹ̀ tí kò já sí ikú, ó gbọdọ̀ gbàdúrà, Ọlọ́run yí ò sí fun un ni ìyè. Moo ń sọ nípa àwọn tí ẹ̀sẹ̀ wọn kò jásí ikú. Ẹ̀sẹ̀ kan ń bẹ tí ó jásí ikú: èmi ò sọ pé kí o gbàdúrà nípa rẹ̀. 17 Gbogbo aìsòdodo ẹ̀sẹ̀ ni, sùgbọ́n ẹ̀sẹ̀ kan wà tí kò jásí ikú. 18 Àwá mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá kií dẹ́sẹ̀. Nítorí ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pa á mọ́, àti pé ẹni búburú nì kòle è pa á lára. 19 Àwá mọ̀ pé a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, a mọ̀ pé gbogbo ayé wà lábẹ́ àkóso ẹni búburú nì. 20 Sùgbọ́n àwa mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti wá ó sì ti fún wà ní ìmọ̀ láti mọ̀ ẹni tí ó jẹ̀ òtítọ́. Àti pé àwá wà nínú ẹni tí ó jẹ́ òtítọ́, nínú Ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì. Òun ni Ọlọ́run ọ̀títọ́ àti ìyé ayérayé. 21 Ẹ̀yin ọmọ ẹ sá fùn ìbòrìsà.