Jòhánù orí kẹta

1 Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fifún wa, tí a n fí npè wá ní ọmọ Ọlórun, àti pé èyíi ni àwá nṣe. Fún ìdí èyí, aiyé kò mọ̀ wá, nítorípé wọn kò tilẹ̀ mọ̀ Ọ́. 2 Àyànfẹ́, ọmo Ọlórun ni àwá nṣe nísisìyí, a kò tí fì ìfihàn bí àwá o ti rí. A mọ̀ pé nígbàtí Krístì bá farahàn, a ó dàbí rẹ̀, nítorí a ó rí gẹ́gẹ́ bí Ó ti rí. 3 Ẹnikẹ́ni, tí ó bá ní ìgboyà nípa ti ọ̀la ńpa ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí òún ti mọ́. 4 Gbogbo ẹnití ó bá ndẹ́ṣe rú òfin; nítorí éṣé ni rírúfin. 5 Ìwọ mọ̀ pẹ́ Krístì farahàn kí Ó lè mú orísìírìsí ẹ́ṣẹ́ lọ, àti pẹ́ nínú rẹ̀ kò sí ẹ̀ṣè. 6 Kò sí ẹni tí ó wà nínú rẹ̀ tí á sí tún má dẹ́ṣẹ̀, kò sí ẹni ti ó d'ẹ́ṣẹ̀ lọ tí yò rí I tàbí mọ̀ Ọ́. 7 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹmá jẹ́kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹni tó bá ń se òdodo jẹ́ olododo, gẹgẹ bi Kristi ti jẹ olódòdo 8 Ẹni tí ń bá dẹṣe t'esu ni, nítorí èsù ńtí déṣẹ̀ l'átètékọ́se. Ìdí èyí ni Ọmọ Ọlórun fifarahàn, kí Oun le ba iṣẹ́ èsù jẹ́. 9 Ẹnikẹ́ni tí a bí nípasẹ̀ Ọlọ́run kòní má dẹ́ṣẹ̀ lọ nítorí irúgbìn Ọlọ́run ńgbé nínú rẹ̀. Kò ní ma mokún nínú ẹ̀ṣè nítorítí a bí nípasè Ọlọ́run. 10 Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlorun nfarahàn àti àwọn èsù pèlú. Ẹnití kò se òdodo ki se ti Ọlọ́run; bẹ sìni ẹni ti kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀. 11 Nítorí èyí ni òrò ìyànjú tí ẹ ti gbọ́ l'átètèkọ́se: pé kí á féràn ara wa. 12 Kìí se bí ti Káìnì, tó jẹ́ t'èsù tì ó sì s'ekú pa arákùnrin rẹ̀. Kílódé tí ó fi pá? Nítorítí iṣẹ́ ọwọ́ rè jẹ́ búburú, tí arákùnrin rẹ jẹ olódodo. 13 Eyin ara mi, ẹ mase je ko ya yin lenu, ti aiye ba korira yin. 14 Awa mọpẹ ati rekọja lati inu iku sinu iye, nitoriti a feran awon arakunrin ni. Ẹnikẹni ti ko feran ngbe inu iku. 15 Ẹnikẹni ti o korira arakunrin re apania ni. Iwọ mọ pe kosi apania ti aye ainipẹkun ngbe inu rẹ. 16 Nipase eyi ni a mọ ifẹ nitoriti Kristi fi ara rẹ lelẹ fun wa. Awa na pelu gbodo fi ara wa fun arakunrin wa. 17 Sugbon ẹnikẹni ti o ba ni ini ninu aiye, ti o ri arakunrin rẹ tin se alaini ti ọkan re ko ya si, bawo ni ifẹ Ọlọrun se wa ninu rẹ. 18 Ẹyin ọmọ mi, ẹmase fẹran pẹlu ọrọ ati ahọn lasan, bikose ninu iṣe ati otitọ. 19 Nipa eyi lase mọ wipe a jẹ ti otito, a si darawa lokan niwaju rẹ. 20 Nitoriti ọkan wa ba dawa lẹbi, Ọlọrun ju ọkan wa lọ, o si mọ ouun gbogbo. 21 Ayanfe, ti ọkan wa ko dawa lẹbi, a ni igboya si Ọlọrun. 22 Ohunkohun ti a ba beere a o ri gba latọdọ rẹ, nitoriti a pa ofin rẹ mọ a si nse nkan to mdara loju rẹ. 23 Èyí ni òfin rè, pé kí á gbàgbọ́ nínú orúkọ ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì kí à sí fẹ́ràn ara wa, gẹ́gẹ́ bí ó se fún wa ní òfin yìí 24 Ẹnití ó pa òfin Ọlọ́run mọ́ ńgbé inú rẹ̀, báyìí ni a se mọ̀pe ó ńgbé nínú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fifún wa.