1 Ẹ̀yin ọmọ, mò ń kọ àwọn ǹkan wọ̀nyí síyín kí ẹ má baà dẹ́sẹ̀. Sùgbọ́n bí ẹnìkan bá ń dẹ́sẹ̀, a ní agbẹjọ́rò pẹ̀lu bàbá, Jésù krístì, ẹni tí ń ṣe olódodo. 2 Òun ni a fi ṣe ìrúbọ fún àwọn ẹ̀sẹ̀ wa. kìí ṣe fún tiyín nìkan sùgbọ́n fún gbogbo aráyé 3 Nípa èyí ni a fi mọ̀ wípé a mọ̀ọ́: tí àwa bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ̀ọ́. 4 Ẹni tí ó sọ wípé, mo mọ Ọlọ́run sùgbọ́n tí kò pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, òpùrọ́ ní, otítọ́ kò sì sí nínù rẹ̀. 5 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá pa òfin rẹ̀ mọ́, inú ẹni náà ni ìfẹ́ Ọlọ́run tí jẹ́ pípé. Nípa èyí ni àwa sì mọ̀ wípé a wà nínú rẹ̀. 6 Ẹni tí ó sọ wípé òun wà nínú Ọlọ́run gbọdọ̀ rìn tìkalárarè bíi Jésù ṣe rìn. 7 Olùfẹ́, èmi kò kọ òfin tuntun sí yín. Ṣùgbọ́n òfin tí ẹ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ láti ìgbà tí ẹ ti ń tẹ̀lé Jésù. Òfin tí tẹ́lẹ̀ yìí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ tí gbọ́. 8 Síbẹ̀ èmi ń kọ òfin tuntun síyín, èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ nínú Krístì àti nínú yín, nítorí òkùnkùn tí ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sì tí ń tàn. 9 Ẹni tí ó sọ wípé òun wà nínú ìmọ́lẹ̀ tí ó sì kórira arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn títí di ìsinsin yìí. 10 Ẹni tí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ síbẹ̀, kò sì sí ìdí láti kùnà nínú ṣíṣe ohun tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórira arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn ó sì ń rìn ní òkùnkùn; kò mọ ibi tí óń lọ, nítorí òkùnkùn ti bo ojú rẹ̀. 12 Mò ń kọ̀wé síyín ẹ̀yin ọmọ nítorí àti dári ẹ̀sẹ̀ yín jìn yín nítorí orúkọ rẹ̀. 13 Mò ń kọ̀wé síyín ẹ̀yin bàbá nítorí ẹ̀yin mọ ẹnití ó tí wà láti àtètèkọ́ṣe. Mò ń kọ̀wé síyín ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin torí ẹ tí borí eniibi náà. Mò tí kọ̀wé síyín ẹ̀yin ọmọdé, nítorí tí ẹ tí mọ bàbá. 14 Mo tí kọ̀wé síyín ẹ̀yin bàbá, torí ẹ tí mọ ẹnití ó tí wà láti àtètèkọ́ṣe. Mo tí kọ̀wé sí yín ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin nítorí ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé inú yín síbẹ̀, ẹ̀yin sì tí borí eniibi náà. 15 Ẹ máṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohun tí ń bẹ nínú ayé, bí ẹnìkan bá fẹ́ran ayé, ìfẹ́ baba kò sí nínú rẹ̀. 16 Nítorí, ohun gbogbo tó wà nínú ayé- ìfẹ́kùfẹ́ ara, ìfẹ́kùfẹ́ ojú àti ìgbéraga ohun tí ènìyàn jẹ́ tàbí dà- kìíse láti ọ̀dọ baba sùgbọ́n láti inú ayé ni. 17 Ayé àti ìfẹ́ rẹ̀ ńkọjá lọ, sùgbọ́n ẹni tó bá ṣe ìfẹ́ ti Ọlọ́run yóò wà títí láíláí. 18 Ẹ̀yin ọmọdé, ìgbà ìkẹyìn ní a wàyí. Gẹ́gẹ́ bíi ẹ tí gbọ́ wípé asòdì sí Krístì ń bọ̀, nísisìnyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn asòdì sí Krístì tí dé. Nípa èyí la fí mọ̀ wípé ìgbà ìkeyìn ni a wà yìí. 19 Wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ wa sùgbọ́n wọn kìí ṣe ara wa. Nítorí ká ní wọ́n wá láti ọ̀dọ wa ni, wọn ìbá wà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ, wọ́n fi hàn wípé wọn kìí ṣe ara wa. 20 Sùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfàmì òróró yàn láti ọ̀dọ Ẹni Mímọ́, ẹ̀yin sí ti mọ òtítọ́ niì. 21 Èmi kò kọ ìwé síyín nítorí tí ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, sùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ òtítọ́, àti nítorí kò sí iró nínú òtítọ́. 22 Tani òpùrọ́ bíkòṣe ẹni tí ó sẹ́ wípé Jésù ní Krístì? ẹni náà ni asòdì sí Krístì nítorí tí ó sẹ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. 23 Ẹni tó sẹ́ Jésù kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tó bá ka Ọmọ sí, mọ bàbá náà. 24 Fún ẹ̀yin, ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ ti gbọ́ wà síbẹ̀ nínú yín. Tí ohun tí ẹ tí gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ bá wà nìnù yín, ẹ̀yin ó wà síbẹ̀ nínú Ọmọ àti nínú Bàbá. 25 Ìlérí tí ó fún wa ni èyí: Ìyè aìnípẹ̀kun. 26 Mo ti kọ àwọn ńǹkan wọ̀nyí síyín nítorí àwọn tí ó fẹ́ síyín lọ́nà. 27 Fún ẹ̀yin, ìfàmì-òróró-yàn tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà síbẹ̀ nínú yín, ẹ kò sì nílò ẹnìkankan láti kọ́ yín mọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ìfàmì-òróró-yàn rẹ̀ ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo, èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ tí kìí ṣe ẹ̀tàn, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ yín, ẹ wà nínú rẹ̀ síbẹ̀. 28 Nísinsìnyí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró síbẹ̀ nínú rẹ̀, torí tí ó bá dé, kí á leè ní ìgboyà kí ojú má sìṣe tìyín níwájú rẹ̀ ní dídé rẹ̀. 29 Tí ẹ̀yin bá mọ̀ wípé Ó jẹ́ olóòótó, ẹ mọ̀ wípé gbogbo ẹni tó bá ṣe ohun tó tọ́ ní á tí inú rẹ̀ bí.