1 Èmi kò di òmìnira bí? Èmi kìíse àpóstélì bí? Èmi kò ti rí Jésù Olúwa wa bí? Ẹ́yin kìí ṣe òjíṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? 2 Bí èmi kìí bá ṣe àpóstélì sí àwọn ìyókù, èmi ṣá jẹ́ sí yín. Nítorí ẹ́yín jẹ́ ẹ̀rí àpóstélì mi nínú Olúwa. 3 Èyí ni àwíjàre mi sí áwọn tó ń yẹ̀míwò: 4 Ǹjẹ́ àwa kò ní àṣe láti jẹ àti láti mu bí? 5 Ǹjẹ́ àwa kò ní àṣe láti mú aya tíí ṣe onígbàgbọ́ pẹ̀lú wa bí, bí àwọn àpóstélì ìyókù ti ṣe, àti àwọn arákùnrin ti Olúwa, àti Séfánì? 6 Àbí èmi àti Bárábà nìkan ni a gbọ́dọ́ ṣiṣẹ́? 7 Taní ó ṣe aṣọ́nà fún ìpalára rẹ̀? Taní ó gbin ọ̀gbà àjàrà láì jẹ nínú èso rẹ̀? Àbí taní ó ṣó àgùntàn láì mu nínú wàrà rẹ̀? 8 Ǹjẹ́ èmi ń sọ èyí nípa àṣẹ ti ènìyàn bí? Ǹjé òfin kò so ẹ̀yí pẹ̀lú? 9 Nítorí a ti kọ́ nínu òfin Mósè, "Máse pa màálù tí ń pakà ní ẹnu mọ́." Ǹjẹ́ ohun ni akọ màálù náà Ọlórun ní fẹ́ sí bí? 10 Kó máa sọ̀rọ̀ nípa wa bí? A kọ ọ́ fún wa, nítorí eni tí ń tulẹ̀ kí ó lè túlẹ̀ ní ìrètí, àti ẹni tí ó ń ká, kí ó ká ní àfojúsùn àti pín nínú ìkórè. 11 Tí a bá gbin oun tíí ṣe ti ẹ̀mi sí àrin yín, ǹjẹ́ ó pọ̀ jú láti kéérè oun tí ṣe ti ẹ̀mí lọ́ dọ̀ ọ yín? 12 Bí àwọn ìyókù bá dèna àṣẹ yí lọ́wọ yín, ǹjẹ́ a kò ni ní ọ̀pọ̀ bí? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò gba àṣẹ yí. Dípò, afarada ohun gbogbo dípò kí á ya olùdènà sí ìhìnrere ti Krístì 13 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pè ẹni tí ń ṣiṣẹ́ nínu tẹ́mpìlì ńrí ónjẹ wọn nínú témpìlì bí? Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé ẹni ti n ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ní ń jẹun níbi pẹ̀pẹ 14 Ní ọ̀nà kan náà, Olúwa pàṣẹ pé àwọn tí ń kéde ìhìnrere gbọdọ̀ rí òunjẹ wọn nìbi ìhìnrere. 15 Sùgbọ́n èmi kò tí gba ǹkankan nínú ẹ̀tọ́ yí. Àti pé èmi kò kọ ǹkan wọ̀nyí kí à le ṣe ǹkan fúnmi. Èmi ó ya kú ju kí a fi ìṣògo mi dùn mí lọ 16 Nítorí tí èmi bá wàásù ìhìnrere, Èmi kò ní ìdí láti ṣògo, nítorí èmi gbọ́dọ̀ ṣe èyí. Àti pé ègbé ni fún mi tí n kò bá wàásù ìhìnrere. 17 Nítorí bí èmi bá ṣe èyí tọkàntọkàn, èmí ní èré. Sùgbọ́n tí kì bá ṣe tọkàntọkàn, èmí ṣì tún ní ojúṣe tí a gbé lémi lọ́wọ́. 18 Kí wá ni èrè mi? Pé bí èmi bá wàásù ìhìnrere, èmí lè sọ ìhìnrere làí gba ohùn kan àti làti má lò ní kínkún ẹ̀tọ́ mi nínú ìhìnrere. 19 Nítorí bí mo ti lẹ̀ gba òmìnira nínú ohun gbogbo, èmí di ìránṣé sí gbogbo ènìyàn, kì èmi le borí sí i. 20 Sí àwọn Jû, èmí di Jû, kí èmi le borí àwọn jû. Fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin, èmí dà bí i ẹni tí ó wà lábẹ́ òfin kí èmi lè borí àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin. Èmí se èyí bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi tìkara à mi kò sí lábẹ́ òfin. 21 Sí àwọn tí ó wà ní ìta òfin, èmí dà bí i tí ó wà ní ìta òfin, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí ní ìta òfin olúwa tì kara à mi, bíkòsẹ lábẹ́ òfin Krístì. Emí ṣe èyí kì èmi le jère àwọn tí ó wà ní ìta òfin. 22 Sí àwọn aláìrera, mo di aláìrere kí èmi le jèrè wọn. Èmí ti di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi le jèrè ènìyàn díẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà 23 Èmi ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi le kòpa nínú ìbùkún. 24 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé ni eré-ìje olúkúlùkù ni ń sáré ìje, sùgbọ́n ọ̀kan ṣoṣo ni ń gba oríyìn? Nítorínà sá eré ìje kí o lè gba èrè 25 Olùdíje ma ń ní ìpamóra ní ìgbá ìdíje. Wọ́n ń ṣe bệ lá ti gba èrè tí ó ní ìdibàjẹ́, sùgbọ́n àwa ń sá eré láti gba èrè tí kò ní ìdibàjẹ́. 26 Nítorínà, èmi kò sá eré lá ì ní àfojúsùn tàbí jà ní òfo. 27 Sùgbọ́n èmí í sé ara à mi, mo sì sọ́ di ẹrú, nítorí tí èmi bá ti wàásù fún àwọn ìyókù, èmi ti kàraami má baá di ẹni ìkọ̀sílẹ̀.