1 Ará, mofẹ́ kí ẹmọ́, pé àwọn bàbá wa wàní abẹ́ kùrukùru tí gbogbo wọ́n sì gba òkun kọjá. 2 Gbogbo wọn ni a baptìsì sínú Mósè nínú kùrukùru àti òkun, 3 àti pé gbogbo wọ́n jẹ ouńjẹ ẹ̀mí kanná-àn. 4 Gbogbo wọ́n mu omi Ẹ̀mí kanná-àn. Nítorí wọ́n mu láti àpáta ẹ̀mí tí ó tẹ̀lé wọn, àti pé Krístì ni àpáta náà. 5 Ṣùgbọ́n inú Ọlọ́run kòdùn púpọ̀ ṣí ọ̀pọ̀pọlọ̀ wọn, àti pé òkú wọn fọ́nká kiri nínú aginjù. 6 Níṣinṣìnyí gbogbo ǹ kan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, fuń ìdí èyí ákòní póǹgbẹ fuń ohun búburú bí wọ́n tise. 7 Ẹ̀mà se jẹ́ abọ̀rìṣà, bí àwọn kan ṣe jẹ́ nínú wọn. Èyí bí ase kọ̀wé rẹ̀, "àwọn ènìyaǹ jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì jí dìde láti ṣéré". 8 Ẹmá ṣe jẹ́ ká ṣe àgbèrè, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n ṣeṣe. Ní ọjọ́kan, ẹgbẹ̀rúnmẹ́tàlélógún ènìyàn kú nítorí rẹ̀. 9 Tàbí kí á dán Jésù wò, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n ṣeṣe tí àwọn ejò síì pawọ́n run. 10 Bákannáà ẹmá ṣe kun, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n ṣeṣe ti ańgẹ́lì ikú ṣíì pawọ́n run. 11 Níṣiṣiǹyí gbogbo ńkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún wa. Akọ wọn fún ìlànà wa - fún àwa lórí ẹni tí òpin ayé tidé. 12 Nítorínà jẹ́kí ẹni tí ó rò pè òhun dúró kíyèṣára kí ó má bàà ṣubú. 13 Kòsí ìdánwò tí ó borí yín tíkò wọ́pọ̀ sí gbogbo ìran ènìyàn. Dípò, olóòdodo ni Ọlọ́run. Kòní jẹ́kí á dán-an yínwò kọjá agbára yín. Pẹ̀lú ìdánwò yóò sì pèsè ọ̀nà àtibọ́, Kí ẹ̀yin kí ó leè ma fara dàá. 14 Nítorínà, ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹsá fún ìbọ̀rìṣà. 15 Mò ń báa yín ṣọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bíi onírònú ènìyàn, kí ẹ le baà dájọ́ ńǹkan tí mò ńsọ. 16 Aago ìbùkún tí a bùkún, ṣé kìí se ìpín nínú ẹ̀jẹ̀ Krístì bí? Búrẹ́dì tí a gé, ṣé kìí ṣe ìpín nínú ara Krístì bi? 17 Nítorí ìṣù búrẹ́dì kán wà, àwa tí a pọ̀ arakanná-àn niwá. Ajẹ nínú ìṣù búrẹ́dì kanná-àn papọ̀. 18 Ẹwo àwọn ènìyàn Íṣrẹ́álì: ṣé àwọn tó jẹ nínú ìrúbọ kọ́ni ókó pa ní ori pẹpẹ bí? 19 Kíni mò ń sọná? Pe òrìṣà jẹ́ nǹkan bí? Tàbí pé oúnjẹ ìrúbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan bí? 20 Ṣùgbọ́n mò ń sọ nípa àwọn nǹkan tí àwọn kèfèrí ń rúbọ, pé wọ́n ń fi àwọn nǹkan wọ̀nyí fuń démónì kìí ṣe sí Ọlọ́run. Mi ò fẹ́kí ẹ jẹ́ olùkópa pẹ̀lú àwọn démónì! 21 Ẹ̀yin kòle mu ninu ife ìmumi Olúwa àti ife ìmumi àwọn démónì. Ẹ̀yin kòle ní ìbádàpọ̀ níbi tábìlì Olúwa àti níbi tábìlì àwọn démónì. 22 Tàbí kí á mú Olúwa jowú bí? Ṣé a ní agbára jùúlọ ni? 23 "Gbogbo nǹkan ló tọ̀nà", ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo nǹkan ló lérè. "Gbogbo nǹkan ló tọ̀nà", ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo nǹkan lómú àwọn ènìyàn dàgbà sókè. 24 Ẹnikẹ́ni kò gbọ dọ̀ wá ire ara rẹ̀. Dípò, oníkálukú gbọdọ̀ wá ire ọmọnìkejì rẹ̀. 25 Ẹ̀nyin lè jẹ ohunkóhun tíwọń ń tà ní ọjà, láìṣí àwọn ìbéèrè ẹ̀rí ọkàn. 26 Nítorí," ayé jẹ́ ti Olúwa àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀". 27 Bí aláìgbàgbọ́ bá pè ọ́ láti jẹ oúnjẹ, tí ósì wù ọ́ láti lọ, jẹ ohunkóhun tí ó bá wà ní iwájúù rẹ láì bèèrè ìbéèrè ẹ̀rí ọkaǹ. 28 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá ṣọ fuń ọ, "oúnjẹ yí wá láti ìrúbọ kèfèrí, máṣe jẹ́. Èyí ni nítorí ẹni tí ó wí fún ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn. 29 Èmi ò ṣọ nípa ẹ̀rí ọkàn rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀rí ọkàn ẹnìkejì. Nítorí kínni á fi dá òmìnira mi lẹ́jọ́ pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn ẹlòmííran? 30 Bí mo bá kópa nínú oúnjẹ pẹ̀lú ìmoore, kílódé tí mofi di ẹni àbùkù fún èyí tí mo dúpẹ́ fún? 31 Nígbànáà, bóyá ẹ jẹ tàbí ẹ mu, tàbí ohunkóhun tí ẹ ṣe, ẹ ṣé gbogbo rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 32 Ẹ máá ṣe fi ẹ̀ṣùn kàn àwọn Júù, tàbí àwọn Gíríkì, tàbí àwọn ìjọ Ọlórùn-un. 33 Mo gbìyànjú láti wu gbogbo ènìyàn ní gbogbo ọ̀nà. Èmi kò wá èrè ti ara mi, ṣùgbọ́n ti àwọn mìíràn. Mo ṣèyí kí wọn kí ó leè di ẹni ìgbàlà.