ORÍ KỌKÀNLÁ

1 Ẹṣe àfarawé mi, bí moṣe ṣe àfarawé Krístì. 2 Níṣiṣìnyí moyìn yín nítorí Ẹ rántìì mi nínú gbogbo nǹkan. Mo yìnyín nítorí ẹdi àṣà mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí moṣe fi fún-un yín. 3 Níṣiṣìnyí mofẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Krístì ni orí gbogbo ọkùnrin, pé ọkùnrin ni orí obìnrin, àti pé Ọlọ́rùn ni orí i Krístì. 4 Ọkùnrin kankan tí ó bá gbàdúrà tàbí ṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú tí orí rẹ̀ wàní bíbò táábùkù orí rẹ̀. 5 Ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí ṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀ wa ní sísí sílẹ̀ táábùkù orí i rẹ̀. Nítorí ọ̀kan ni àti nǹkan kannáà ni bí i pé irun orí rẹ̀ wàní fífá. 6 Nítorí bí obìnrin kan kòbá ní bo irun orí rẹ̀, ó gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ kéré. Bí ó bá sì jẹ́ ohun ìtìjú fún obìnrin láti gé irun orí rẹ̀ tàbí láti fá orí rẹ̀, jẹ́kí ó bo oríi rẹ̀. 7 Nítorí ọkùnrin kògbọdọ̀ bo orí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ àwòrán àti ògo Ọlọ́rùn. Ṣùgbọ́n obìnrin ni ògo ọkùnrin. 8 Nítorí a kò dá ọkùnrin láti ọ̀dọ̀ obìnrin. Dípò, a dá obìnrin láti ọ̀dọ̀ okùnrin. 9 Bẹ́ẹ̀ni akòsì dá ọkùnrin fún obìnrin. Dípò, adá obìnrin fún ọkùnrin. 10 Ìdí nìyí tí obìnrin yẹkí óní àmì àṣẹ ní orí rẹ̀ nítorí àwọn ańgẹ́lì. 11 Síbẹ̀síbẹ̀, nínú Olúwa, obìnrin kò dádúró yàtọ̀ sí ọkùnrin, tàbí ọkùnrin dádúró yàtọ̀ sí obìnrin. 12 Nítorí bí obìnrin ṣe wá láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin láti ọ̀dọ̀ obìnrin. 13 Ẹdájọ́ fúnrayín: ṣe ótọ̀nà fún obìnrin láti gbàdúrà sí Ọlọ́run-un pẹ̀lú tí orí rẹ̀ wàní sísí sílẹ̀? 14 Ṣé àwọn ohun ìsẹ̀dá kò tilẹ̀ kọ́ọ yín wípé bí ọkùnrin bání irun orí tí ó gùn, ìtìjú ni fún-un? 15 Ṣé àwọn ìsẹ̀dá kò kọ yín pé bí obìnrin bání irun orí tí ó gùn, ògo rẹ̀ ni? Nítorí irun rẹ̀ ni afi fún-un gẹ́gẹ́ bí ìborí. 16 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí eleyìí, a kòní àṣà mííràn, tàbí íṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run-un. 17 Ṣùgbọ́n nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí èmi kò yìnyín. Nítorí nígbàtí ẹbá kórajọpọ̀, kìí ṣe fún ohun tí ódára ṣùgbọ́n fún àìda. 18 Nítorí ní àkọ́kọ́, mo gbọ́ pé nígbàtí ẹbá kórajọpọ̀ nínú ìjọ, àwọn ìyapa wà láàrin yín, èyí tí mo faramọ́ ní apákan. 19 Nítorí ẹka gbọ́dọ̀ wà láàrin yín bákanná-àn, kí àwọn tí a fọwọ́sí leé jẹ́ dídámọ̀ láàrin yín. 20 Nítorí bí ẹ bá kórajọpọ̀, kìí ṣe ouńjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ̀ ń jẹ. 21 Nígbàtí ẹ bá jẹ, oníkálukú jẹ oúnjẹ tirẹ̀ kí àwọn ìyókù tójẹ oúnjẹ tiwọn. Ebi ń pa ẹnìkan tí ẹlòmíràn síì di ọ̀mùtípara. 22 Ṣé Ẹ kò ní àwọn ilé láti jẹ àti láti mu nínú rẹ̀ bí? Ṣé ẹ̀ ń gan ìjọ Ọlọ́run tí ẹ sì ń dójú ti àwọn tí kòní nǹkankan bí? Kín ló yẹ kí n ṣọ fún yín? Ṣó yẹ kí n yìn yín? Mi ò ní yìn-yín fún èyí! 23 Nítorí mogbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa ohun tí èmi náà fi ránṣé sí i yín, pé Jésù Olúwa, ní alẹ́ tí adalẹ ẹ Rẹ̀, mú búrẹ́dì. 24 Lẹ́yìn ìgbàtí Ó dúpẹ́, Ó gé e, Ó wípé, "Èyíì ní ara mi, tí ó wà fún yín. Ẹṣe èyí láti rántí mi. 25 Ní ọ̀nà kannáà, Ó mú ife lẹ́yìn ouńjẹ alẹ́, Ó sọpé, "Ife yíì ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi. Ẹṣe eléyì ni ìgbà tí ẹbá mu, láti rántì mi". 26 Nítorí ní gbogbo ìgbà tí Ẹ bájẹ búrẹ́dì yí tí ẹ sì mu nínú ife yìí, Ẹ̀ kéde ikú Olúwa títí yóò fidé. 27 Nítorínà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ búrẹ́dì tàbí mu ife Olúwa ní ọ̀nà tíkò tọ́ , yóò jẹ̀bi ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Kí ènìyàn ó kọ́kọ́ yẹ araarẹ̀ wò, àti ní ọ̀nà yìí ni ki ó jẹ búrẹ́dì kí ó sì mu nínú ife náà. 29 Nítorí ẹni tí ó bá jẹ tí ó sì tún mu láì mòye ara, ó ń jẹ ó sì ń mu si ìdájọ́ araarẹ̀. 30 Ìdí nìyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú yín fi jẹ́ aláìlágbára àti aláisàn àti díẹ̀ nínú yín fi sùn. 31 Ṣùgbọ́n bí a bá yẹ ara wa wò, a kòní dáwa lẹ́jọ́. 32 Sùgbọ́n nígbàtí Olúwa bá dáwa lẹ́jọ́, àwa yóò lẹ̀kọ̀ọ́, nítorí kí á le è má ba à dáwa lẹ́bi pẹ̀lú ayé. 33 Nítorínà, ẹ̀yin ará mi, nígbàtí Ẹ bá kórajọpọ̀ láti jẹ, Ẹ dúró de ara yín. 34 Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, ẹ jẹ́kí ó jẹun nílé, nítorípé nígbàtí ẹ bá kó jọpọ̀ kòní jẹ́ fún ìdájọ́. Àti nípa àwọn nǹkan míràn tí ẹ kọ, Èmi yóò se ìtọ́sọ́na nígbàtí mo bá dé.