Orí Kejìlá

1 Ǹjẹ́ ní tI ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ará, èmi kò fẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. 2 Ẹ̀yín mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yín jẹ́ kèfèrí, ẹ̀yín ti sọnù sínú àwọn òrìṣà aláìlefọhùn, ní ọ̀nàkọnà tí wọ́n ti gbà darí yín. 3 Nítorínà, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ wípé kò sí ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó le sọ wípé, "Jésù jẹ́ ẹni ègún". Kò sí ẹni tí ó le sọ pé, "Jésù ni Olúwa", bíkòṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 4 Ǹjẹ́ oríṣìríṣìí ẹ̀bùn ẹ̀mí ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni. 5 Oríṣìríṣi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó wà, ṣùgbọ́n Olúwa kan 6 Onírúurú iṣẹ́ ni ó sì wà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan ni ó ń ṣiṣẹ́ nínú gbogbo wọn. 7 Nísinsìnyí, fún olúkúlùkù ni a ti fún ní ìfihàn mí fún àǹfàní gbogbo ènìyàn. 8 Ǹjé nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ a fi ọ̀rọ́ ọgbọ́n fún ẹnìkan, àti fún ẹlòmíràn ìmọ̀ nípasè Ẹ̀mí kanna. 9 Àti fún ẹlòmííràn ìgbàgbọ́ nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí kan náà, àti fún ẹlòmíràn ẹ̀bùn ìmúláradá nípasẹ̀ ẹ̀mí náà. 10 Àti fún ẹlòmííràn iṣẹ́ ti agbára, àti fún ẹlòmííràn ìsọtẹ́lẹ̀, àti fún ẹlòmííràn ipá láti mọ ìyàtọ̀ àwọn ẹ̀mí, fún ẹlòmíràn oríṣiríṣi ìfèdèfọ̀, àti fún ẹlòmíràn ìtúmọ̀ àwọn èdè. 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan náà ni ó ń ṣiṣẹ́ nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí, tí ó sì fi ẹ̀bùn fún olúkùlùkù bí o ṣè wù ú. 12 Gẹ́gẹ́ bí ara ṣe jẹ́ ọ̀kan tí ó sì ní ẹ̀yà ara púpọ̀ tí àwọn ẹ̀yà yìí sì jẹ́ ara kan náà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni pẹ̀lú Krístì. 13 Nítorípé nípa ẹ̀mí kan ni a tiṣe ìrìbọmi fún wa sí inú ara kan, yálà Júù tàbí Gíríkì, yálà òǹdè tàbí ẹni òmìnira, asì ń mu nínú ohun Ẹ̀mí kan náà. 14 Nítorí ara kìí ṣe ẹ̀yà kan, bíkòṣe pẹ̀lú ẹ̀yà púpọ̀. 15 Bí ẹsẹ̀ bá wípé, "Níwọ̀n ìgbàtí èmi kìí ṣe ọwọ́, èmi kìí ṣe ẹ̀yà ara", kò bùúkù ní ẹ̀yà ara 16 Bí etí bá wípé "Nítorí èmi kìí ṣe Ojú, èmi kìí ṣe ara', kò bùúkù ní ẹ̀yà ara 17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú níbo ni etí íbà gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni imú ìbá gbé wa? 18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run to ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bí Ó ṣe gbèro rẹ̀. 19 Bí wọ́n bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà, níbo ni ara ìbá wa? 20 Nísìsiyì wọ́n jẹ́ ẹ̀ya ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan. 21 Ojú kò le sọ fún ọwọ́, "Èmi kò nílò rẹ". Tàbí kí orí sọ́ fún ẹsẹ́, "Èmi kò nílò rẹ". 22 Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹlẹgẹ́ ṣe pàtàkì, 23 àti àwọn ẹ̀ya ara tí a lérò pé wọ́n jẹ́ aláìlọ́lá ni a fún ní ọlá tí ó ga jù, àti àwọn ẹ̀ya ara wa tí a kò le fi hàn ni a fi iyì púpọ̀ fún. 24 Nísinsìnyí, a kò nílò láti fi ìyì fún wọn nítorí tí wọ́n ti jẹ́ ẹni ìyì. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti so gbogbo ara papọ̀, Ó sì ti fi ọlá púpọ̀ fún àwọn tí ó ṣe aláìní wọn. 25 Ó ṣe eléyì kí ó má bàá sí ìyapa nínú ara, bíkòṣe kí ẹ̀yà ara le má ṣe ìtọ́jú ara wọn ní ìfẹ́ kan. 26 Bí ẹ̀yà ara kan ba ń jìyà, ẹ̀yà ara yókù má jìyà pẹ̀lú rẹ̀, tàbí tí a bá bu ọlá fún ẹ̀yá ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara á yọ̀. 27 Nísinsìnyí ara Krístì ni ẹ̀yin, olúkúlùkù yín jẹ́ ara rẹ̀. 28 Ọlọ́run si ti yàn nínú ìjọ, làkọ́kọ́ àwọn àpọ́stèlì, ẹ̀kejì wòlíì, ẹ̀kẹẹ́tà àwọn olùkọ́, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ agbára, ẹ̀bùn ìmúláradá, àti àwọn tó ń ṣe ìrànwọ́, àti àwọn tó ń ṣe àbojútó àti àwọn tó ní onírúurú èdè 29 Gbogbo wọn á jẹ́ àpọ́stélì bìí? Gbogbo wọn á jẹ́ wòlí bìí? Gbogbo wọn á jẹ́ olùkọ́ bíí? Gbogbo wọn á jẹ́ oníṣẹ́ ìyanu bíí? 30 Ṣé gbogbo wọ́n ló ní ẹ̀bùn ìmúláradá ni? Sé gbogbo wọn ló ń fèdèfọ̀ ni? Ṣé gbogbo wọ́n ló ń túmọ̀ èdè ni? 31 Ẹ fi ìtara wá ẹ̀bùn èyí tó gajù. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ọ̀nà tó dára jù hàn yín.