Orí Kẹtàlá

1 Bí mo bá tilẹ̀ sọ̀rọ̀ ní èdè ènìyàn àti ti àwọn áńgẹ́lì. Ṣùgbọ́n bí èmi kò bá ní ìfẹ́, èmí jẹ́ agogo tí ń pariwo tàbí ohùn olóhùn gooro 2 Bí èmí ba ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye òtítọ́ àti ìmọ̀ tí ó farasin, àti tí mo ni ìgbàgbọ́ tí ó le ṣí òkè nídìí. Ṣùgbọ́n tí èmi kò bá ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ ǹkankan. 3 Bí mo bá fi gbogbo ohun tí mo ní fún tálákà, àti tí mo si fi ara mi sílẹ̀ láti sun. Ṣùgbọ́n tí èmi kò bá ní ìfẹ́ èmi kò jámọ́ ǹkankan. 4 Ìfẹ́ a máa ní sùúrù, a sì maa ṣoore. Ìfẹ́ kìí ṣe ìlara tàbí ṣe ìfọ́nu. Ìfẹ́ kìí ṣe ìgbéraga 5 tàbí ṣe àrífín. Ìfẹ́ kìí ṣe ti ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kìí tètè bínú. Ìfẹ́ kìí ṣe àkọsílẹ̀ ohun búburú. 6 kìí yọ̀ nínú àìṣòdodo. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ń yọ̀ nínú òtítọ́. 7 Ìfẹ́ a máa farada ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìdánilójú nípa ohun gbogbo, a sì máa ní ìpamọ́ra ohun gbogbo. 8 Ìfẹ́ kò lópin. Bí àsọtẹ́lẹ̀ bá wà, wọ́n a ré kọjá, Bí ẹ̀bùn èdè àìmọ̀ bá wà, á di ohun ìgbàgbé. Bí ẹ̀bùn ìmọ̀ bá wà, á di ohun ìgbàgbé. 9 Nítorí tí àwá ń mọ́ ní apá kan, tí à sì ń sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan. 10 Ṣùgbọ́n nígbàtí èyí tó jẹ́ pípé bá dé, èyí tó jẹ́ àìpé yóò ré kọjá. 11 Nígbàtí mo jẹ́ ọmọdé, èmí sọ̀rọ̀ bíi ọmọdé, èmí gbèrò bíì ọmọdé. Nígbàtí mo di àgbà mo fi àwọn ìṣe ọmọdé sílẹ̀. 12 Nítorí, nísinsínyìí àwa ńwò bàìbàì bíi nínú dígí, ṣùgbọ́n nígbànáà ní ojúkorojú. Nísisìyìí, èmi mọ̀ ní apá kan, ṣùgbọ́n nígbànáà èmi yóò mọ̀ lẹ́kùn rẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe jẹ́ mímọ̀. 13 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, àwọn ohun mẹ́ta yìí dájú: ìgbàgbọ́, ìgboyà ọjọ́ ọ̀la, àti ìfẹ́, ṣùgbọ́n eléyìí tí ó ga jù ní ààrin wọn ni ìfẹ́.