1 Lépa ìfé kí o sì ní ìtara fún ẹ̀bùn ẹ̀mí, pàápàá jùlọ kí o lè sọ tẹ́lẹ̀. 2 Nítorí ẹni tí ó ń sọ èdè àìmọ̀ kò sọ̀rọ̀ sí ènìyàn sùgbón sí Ọlọ́run. Kò sí ẹni tí ó ní òye Rè nítorí ó n´sọ oun ìkọ̀kọ̀ ti ẹ̀mí. 3 Ṣùgbón ẹni tí ó ń so tẹ́lè ń ṣe èyí fún ìdàgbà, ìmúlókànle àti ìtùnú fún àwon ènìyàn. 4 Ẹni tí ó ń sọ èdè àìmọ̀ ń mú ara rè dàgbà, ṣùgbón ẹni tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ ń mú ìjọ dàgbà. 5 Nísinsìyí, ó wù mí kí gbogbo yín lé fèdèfọ̀. Ṣùgbọ́n ju bẹ́ẹ̀ lọ, ó wù mí kí ẹ lè sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹni tí o ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́lá ju ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀ lọ (àyàfi tí ẹnìkan bá ń túmò rẹ̀ kí ìjọ kí ó le dàgbà). 6 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ará, bí èmi bá ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, báwo ni yóò ṣe jé ànfàní fún yín? Èmi kòleè ṣe è yí, bí kò se pé mo ba yín sọ̀rọ̀ nípa ìran, tàbí ìmọ̀, tàbí àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ìkọ́ni. 7 Bí àwọn ohun èlò tí kò ní ẹ̀mí bá ń dún - bíi fèrè tàbí dùrù - tí kò sì sí ìyàtò nínu ohùn wọn, báwo ni ẹnikẹ́ni yóó ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí dùrù ń wí? 8 Nítorí tí ohùn ìpè kò bá dájú, báwo ni ẹnikẹ́ni ó ti ṣe mọ̀ pé àkókò ti tó láti múra ogun? 9 Bẹ́ẹ̀ni, ó rí pèlú yín. Tí ẹ̀yin bá sọ̀rọ̀ tí kò mú ọgbọ́n dání, báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe ní òyẹ ohun tí ẹ ti so? Ẹ̀yin yóò máa sọ̀rọ̀, kò sì ẹni tí yóò ní òyẹ ohun tí ẹ̀ ń sọ. 10 Ó dájú wípẹ́ onírúurú èdè ni ó wà ní ayẹ́, kòsì sí èyí tí kò ní ìtumọ̀. 11 Ṣùgbón tí èmi kò bá mọ ìtumọ èdè kan, èmi yóò jẹ́ àjèjì sí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ yóò sì jẹ́ àjèjì sí mi. 12 Bákan náà pẹ̀lú yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ń pòǹgbẹ fún ìfarahàn Ẹ̀mí, ẹní ìtara fún kíkọ́ ìjọ. 13 Kí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀ gbàdúrà kí ó le è ṣe ìtumọ̀. 14 Nítorí tí èmi bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkàn mí jé aláìléso. 15 Kí ni kí èmi kí ó ṣe? Èmi yóò gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí ì mi, èmi yóò sì tún gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn mi. Èmi yóò kọrin pẹ̀lú ẹ̀mí ì mi, èmi yóò sì tún kọrin pẹ̀lú ọkàn mi. 16 Bí béè kọ́, tí ìwọ bá yin Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀mí, báwo ni ẹlòmíràn yóò ṣe ṣe "Àmín" nígbà tí o bá ń dúpẹ́ tí kò sì mọ ohun tí ò ń sọ? 17 Nítorí ìwọ ń dúpé gidigidi ní tòótọ, ṣùgbón ẹnìkejì rẹ kò tíì dàgbà. 18 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wípé mo le fi èdè fọ̀ ju ẹnikẹ́ni nínú yín lọ. 19 Ṣùgbọ́n nínú ìjọ, màá yàa fi òye mi sọ̀rọ̀ márùń fún ìtọ́ni ẹlòmíràn ju ẹgbàárùń ìfèdèfọ̀. 20 Ará, ẹ má ṣe jé ọmọdé nínú ìrònú yín. Dípò bẹ́ẹ̀, nínú ìwà búburú, ẹ dà bíi ọmọ ọwọ́. Ṣùgbọ́n nínú ìrònú yín ẹ dàgbà. 21 Ó wà ní àkọsílẹ̀ nínú òfin, "nípa àwọn elédè míràn àti ètè àjèjì èmi yóò bà àwọn ènìyan yí sọ̀rọ̀. Kódà àwọn kì yóò gbọ́ mi," ni Olúwà wí. 22 Nítorínà, ìfèdèfọ̀ jẹ́ àmì, kìí se sí onígbàgbọ̀ ṣùgbọ́n sí aláìgbàgbó. Ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ wà fún àmìn, kìí sẹ fún aláìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n fún onígbàgbọ́. 23 Ǹjé tí gbogbo ìjọ bá wà papọ̀ tí wọ́n sì fi èdè fọ̀, tí àjẹ̀jì àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé, wọn kò ní wípé asiwẹ̀rẹ́ ni yín? 24 Ṣùgbọ́n tí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, tí aláìgbàgbọ́ tàbí ẹnití kò ní òye bá wọlé, ohun gbogbo tií òhun bá gbọ́ yóò fún n ní ìdánilójú. A ó dáa lẹ́jọ́ pẹ̀lú ohun gbogbo tí a sọ. 25 Ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yí ò hàn kẹdẹrẹ. Nípa èyí, ò un yóò si dojú bolẹ̀ yóò sì sin Ọlọ́run. yóò si sọ wípé Ọlọ́run wà láàrín yín ní tòótọ́. 26 Kí ló tún kù, ará? nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, oníkálukù si ti ni psálm̀ù kan, ẹ̀kọ́ kan, ìfihàn kan, èdè kan tàbi ìtumọ̀ kan. Ẹ se gbogbo èyí láti mú kí ìjọ kí ó dàgbà. 27 Tí ẹnikẹ́ni bá sòrò ní èdè kan, ẹ jẹ́ kí ènìyàn méjì tàbí mẹ̀ta wà, àti ẹ̀yin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí enìkan sì ma túmọ̀ ohun tí ó ń sọ. 28 Ṣùgbọ́n tí kò bá sí ògbùfọ̀, ẹ jẹ̀ kí oníkálukù wọn dákẹ́ nínú ìjọ. Sì jẹ́ kí oníkálukù máa bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀ àti Ọlọ́run. 29 Jẹ́kí wòlìì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, kí àwọn tí ó kù sì gbọ́ oun tí wọ́n ń sọ pẹ̀lú ìdámọ̀-yàtọ̀. 30 Ṣugbọ́n tí a bá sì fi ohun kóhun han ẹnití ó jókǒ nínú ìsìn, jẹ́kí ẹnití ò ti ń sọ̀rọ̀ dákẹ́. 31 Nítorí gbogbo yín le sọtẹ́lè ní ọ̀kọ̀òkan. Fùn ìkọ́ni àti ìmú-lọ́kànle olúkúlùkù. 32 Nítorí ẹ̀mí àwọn wòlíì wà ní abẹ́ ìdarí àwọn wòlíì. 33 Nítorí Ọlọ́run kìí se Ọlọ́run ìdàrúdàpọ̀, ṣùgbọ́n ti àláfíà. Èyí ni ìlànà nínú gbogbo ìjo onígbàgbọ́. 34 Kí àwọn obìnrin dákẹ́ nínú ìjọ. Nítorí a kò gbà wọ́n láàyè láti sọ̀rọ̀. Dí pò o bẹ́ẹ̀, kí wọn wà ní ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe wí. 35 Bí ohunkóhun bá wù wọ́n láti kọ́, jẹ́ kí wọ́n bi àwọn ọkọ wọn ní ilé. Nítorí ohun ìtìjú ni kí obìnrin sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. 36 Ṣé ipasẹ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe wá ni? Ṣé ẹ̀yín nìkan ni ó tò wá ni? 37 Bí ẹnikẹ́ni bá ro ara rẹ̀ làti jẹ̀ wòlíì, tàbí ẹni ẹ̀mí, jẹ́ kí ó mọ̀ dájú pé àwọn ohun tí mo kọ sí i yín jẹ́ òfin ti Olúwa. 38 Ṣùgbón bí ẹnikẹ́ni kò bá mo èyí, kí a má ṣe dá a mò. 39 Nítorínà, ará, ẹ má a fi ìtara sàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì se dá ẹnikẹ́ni lékun áti fi èdè fọ̀. 40 Ṣùgbón kí ohun gbogbo jẹ́ síse ni dáradára àti létòlétò.