1 Nísinsìnyí ará, emi rán yín létí íhínrere tí mo polongo fún yín, tí ẹ gbà, àní, tí ẹ dúró lé lórí. 2 Nípa ìhìnrere yìí ní á fí gbàyínlà, bí ẹyín bá dirọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ tí mo wàásù fún yín, bíkosebẹ́ẹ̀ asán ni igbàgbọ́ yín. 3 Èmi fifún yín ohun tí ó se pàtàkì jùlọ tí mo gba: èyí tí n se kristi tí ó kú fún ẹ̀sẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tiwí, 4 wípé ó kú, a sì jíi dìde ní ọjọ́ kẹ̀ta gégé bí ìwé mímọ́ tiwí. 5 Krístì farahàn Sẹ́fásì, áti lẹ́hìn náà àwon méjìlá; 6 lẹ́hìn èyínì ó farahan àwon ará tí ó ju ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀ta lọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ won síì wà láyé, sùgbón díẹ̀ nínú won ti sùn. 7 Lẹ́yin èyíni ó farahàn Jákọ́bù, lẹhinna sí gbogbo àwọn Àpóstélì. 8 Ní ìkẹyín, ó farahàn mí, bí ọmọ tí a bí ní àsìkò àìtọ́. 9 Nítorí èmi ni mò keré jùlọ nínú àwọn Àpóstélì. Mi ò yẹ ní ẹnití à bá maa pè ní Àpóstélì nítorítí èmi se inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run. 10 Sùgbón èmi jẹ́ ohun tí mo jẹ́ nípa ore-ọ̀fé Ọlórun, ore-ọ̀fé rẹ̀ tí o sì wa nínú mi kìí se asán. Dípò, èmi siṣẹ́ kárakára ju gbogbo wọn lọ. Síbẹ̀ èmi kọ́, sùgbón ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó wà pẹ̀lú mi. 11 Nítorínà bóyá ó jẹ́ èmi tàbí àwọn, bẹ́ẹ̀ àwa wàásù ẹ̀yin síì gbàgbọ́. 12 Báyìí, tí a bá kéde Krístì pé o jíǹde kúrò nínú àwọn òkú, báwo ni àwọn kan nínú yin se má wípé kò sí àjíǹde àwọn òkú? 13 Ṣùgbọ́n tí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú Krístì tìkara rè kò jé jíǹde pèlù 14 tí Krístì ò bá si jíǹde kúrò nínú òkú, ìwàásù wá jẹ asán, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa pẹ̀lú. 15 Pẹ̀lúpẹ̀lú, àwa rí bi ẹlẹ́rìí èké nípa Ọlọ́run, nítorí àwa ń jẹ́rìí lòdì sí Ọlọ́run, wípé ó jíǹde kúrò nínú òkú nígbàtí kò jíǹde. 16 Nítorí tí á kò bá jí òkú dìdé, àní Krístì pẹ̀lú kò jíǹde; 17 àti wípé bí Krístì kò bá jíǹde, ìgbàgbọ́ yín jẹ́ asán, ẹ̀yín sì wà nínú ẹ̀sẹ yín. 18 Nígbànáà ni àwọn tó ti kú nínú krístì ti ṣègbé pẹ̀lú. 19 BÍ ó bá ṣepé àwa ní ìdánilójú nìkan fún ọjọ́ iwájú nínú Krístì , àwa jẹ̀ ẹni ìká-àánú fún jùlọ nínù gbogbo ènìyàn. 20 Ṣùgbón nísinsìnyí a ti jí Krìstí dìde kúrò nínú àwon òkú, àkọ́bí nínú àwọn tó ti kú. 21 Níwọ̀n ìgbàto sepé nìpasẹ ènìyàn ni ikù ṣe wá, nípasẹ ènìyàn pẹ̀lú ni àjíǹde òkú náà ṣe wá. 22 Torí nínú Ádámù gbogbo wá ku, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú nínú Krístì gbogbo wá ó di alàyè 23 Ṣùgbón oníkálukú ènìyàn ní ipa ọ̀nà tirẹ̀: Krístì jẹ́ àkọ́bí lẹ́yìn èyíni àwọn eni tí se ti Krístì yóò di alàyè ní ìpadàbọ̀ rẹ̀. 24 Nágbànàà ni òpin yóo dé, nígbàtí Krístì yóo jọ̀wọ́ ìjọba fún Ọlọ́run, àní Bàbá. Nígbà yí ni yóo pa gbogbo òfin àti àsẹ́ àti agbára. 25 Nítorí ó gbọ́dọ̀ jọba títí yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá Rẹ sábẹ ẹsẹ̀ Rẹ 26 ikú sì jẹ́ ọ̀tá ìkẹhìn tí a ó parun. 27 Nítorí "tí ó ti fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀." Ṣùgbọ́n nígbàtí ó wípé "ohun ti fi ohun gbogbo," ó fi hàn kedere pé èyí kò pẹ̀lú ẹni tí ó ti fi ohun gbogbo sí abẹ́ ara Rẹ̀. 28 Nígbàtì ohun gbogbo bá wà ní abẹ́ Rẹ̀, nígbà na ni Ọmọ tìkara Rẹ̀ yóò wà ní abẹ́ ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí ẹsẹ̀ Rẹ̀. Èyí yóò sẹlẹ̀ kì Ọlọ́run Bàbá lejẹ́ ohun gbogbo nínú gbogbo. 29 Bíbẹ̀ẹ̀kọ́ kínni àwọn tí a baptísì nínú ókù yóo se? Bi a kò bá ji òkú dìde rárá, nítorí kínni há se baptísì wọn nítorí òkú 30 Nítorí kínni, àwa se wá wà nínu ewu ní wákàtí gbogbo? 31 Èmi ńkú lójojúmó! è yí ni èmi kede nípa ṣí ṣògo nínu yín, tí mo ní nínu krístì Jésù Olúwa wa. 32 Kíní se èrè mi, láti inú ìwòye ènìyàn, bí mo bá bá ẹranko jà ní Éfésù, bí àwon òkú kò bá jíǹde? "Ẹjẹ́ kí a jẹ, kí á sì mu, nítorí ní ọ̀la àwa ó kú." 33 kí á má se tàn yín jẹ: "ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́. 34 Ẹ jí ìjí òdodo! kí ẹ má sì ṣe ma dẹ́sè mọ́. Nítorí àwọn kan nínu yín kò ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Mo sọ èyí sí ojú tì yin. 35 Ṣùgbọ́n ẹnikan yóò wípé, Báwo ni àwọn òkú se ji dìde, àti wípé irú àgọ ara wo ni won ó ṣe wá? 36 Ẹ̀yin jẹ́ ailámọ̀kan! ohun tí ẹ̀yin gbin kì yóo bẹ̀rẹ̀ sí ní dàgbà àyàfi tí o bá kú. 37 Ohun tí ẹ̀yin gbìn kìí ṣe ara tí ó jẹ́, ṣúgbọ́n yóò jẹ́ irú gbìn la san. Ó lè jé ọkà tàbí ǹkan míràn. 38 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fún ni ara bó se wú, àti fún irúgbìn kọ̀kan ní ara rẹ̀. 39 Kí ṣe gbogbo ẹran ara ló rí bákanáà. Dípò, ẹran ara kan ló wà fún ènìyàn, àti òmíràn fún eranko, ti òmíràn fun ẹyẹ ati òmíràn fún eja. 40 Ará òkè òrun àti ará ayé sí wà pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ògo ti ará òkè òrun jẹ̀ irú kan àti ti aiyé tó jẹ́ irú míràn. 41 Ògo ọ̀rùn kán sì wà, àti ògo òmíràn fún òsùpá àti ògo míràn fún àwon ìràwò. Nítorì ògo ìràwò kan yà tò sí òmíràn. 42 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àjíǹde òkú. Ohun tí a fúrúgbìn ní ìdibàjẹ́, Ohun tí a jí dìde ní àidìbàjẹ́. 43 A gbìn ní àìlọ́lá; a sì jíi dìde nínú ògo. 44 A gbìn ní ara tí ó ya pa sí ara ; a sì ji dìde nínú ara ẹ̀mí. Ara tí ó ya pa sí ara wà, ara ẹ̀mí si wa pẹ̀lú. 45 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a kọ́ọ́, " Ádàmù ọkùnrin àkọ́kọ́ di aláyè ọkàn."Ádámù ìkẹhìn di ẹ̀mí ìsonidàyè 46 Ṣùgbọ́n ti ẹ̀mí kò kọ́kọ́ wa bíkòse ti ara tí ó ya pa sí ara, lẹ́yìnnáà ti ẹ̀mi' 47 Ọkùnrin àkọ́kọ́ ti inú èrùpẹ̀ wá. Ọkùnrin kẹ̀jì wá láti òkè òrun. 48 gẹ́gé bí èyí tí a dá láti inú èrùpẹ̀ bẹ́ẹ́ ni àwon tí a dá láti inú èrùpẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí òkè òrun se jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwon tí ó jẹ́ ti òkè ọ̀run 49 Gẹ́gẹ́ bí a sì ti bí àwòrán ọkùnrin èrùpẹ̀ náà, a ó bi àwòrán okunrin ti oke orun. 50 Èyì nì mo wì, ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò le jogún ìjọba Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ni ìdibàjẹ́ kò le jogún aìdibàjẹ́. 51 wòó! èmi ṣo òtítọ́ tí ó farasin fún yin: kíì se gbogbo wa ni yóo ó ku, ṣùgbọ́n gbogbo wa ni a o pa lára dà 52 Lọ́gàn a ó pawálára dà, ní ìsẹ́jù àáyá ti ìpe ìkẹ̀hìn. Nítorí ìpè yóò dún, àwon tí o kú yóò sì dìde ní aìdibàjẹ̀, a ó sì pa gbogbo wa lára dà. 53 Nítorí àgo ara ìdibàjẹ́ yíì gbọdọ̀ gbè aìdibàjẹ́ wọ̀, ara kíkú yíì si gbọdọ̀ gbé ara aìkù wọ̀. 54 Ṣùgbọ́n nígbàtí ara ídibàjẹ́ yíì bá sì ti gbé aìdibàjẹ́ wọ̀, àti nígbàtí ara kíkú bá gbé aìkú wọ̀, nígbànáà ni a ó wá nìpa ọ̀rọ̀ tí a ti kọ wípé, " a gbé ikú mì ní ìsẹ́gun." 55 "ikú oró rẹ dà? Isà òkú ìsẹ́gun re dà? 56 Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀, agbára ẹ̀ṣẹ̀ si ni ofin. 57 Ṣùgbọ̀n ọpẹ̀ ni fún Ọlọ́run , tí ó fún wa ní ìsẹ́gun náà nìpa Jéṣù Krístì Olúwa wa. 58 Nítorínà, ẹ̀yin ará mi, ẹ máà dúró ṣinṣin, àti laiyẹsẹ̀ kí ẹ ma pọ̀ si ní isẹ́ Olúwa nígbàgbogbo, nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé isẹ́ yín kíì se asan ninu oluwa.