1 Báàyí nípa gbígba ọrẹ fún àwọn onígbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí mo tí darí àwọn ìjọ Gàlátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. 2 Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀ , ẹni kọọ̀kan yín gbọdọ̀ ya ohun kàn sí apákan, kí ẹ si paámọ́ gẹ́gẹ́ bí ìkápá yín . Ẹ ṣe èyí kó má bà sí ọrẹ gbígbà mọ́ nígbà tí mo bá dé. 3 Tí mo bá dé, ẹnikẹ́ni tí ẹbá yàn, ni èmi ó fí lẹ́tà rán láti gbé ọrẹ yín lọsí Jerúsálẹ́mù . 4 Tí ó ba tọ́ fún mi láti lọ pẹ̀lú , wọn ó lọ pẹ̀lú mi. 5 Ṣùgbọ́n èmi yóò wá sí ọ̀dọ̀ yín nígbàtí mo bá gba Makedóníà kọjá. 6 Bóyá màá dúró pẹ̀lú yín tàbí lo ìgbà òtútù pẹ̀lú yín , kí ẹ lè rànmí lọ́wọ́ nípa ìrìn àjò mí, ní ibi gbogbo tí mo bá lọ 7 Nítorí kò wùmí nísinsìnyí láti rí yín fún akókò péréte. Nítorí ówùmí láti lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú yín, bí Ọlọ́run bá gbà mí lááyè . 8 Sùgbọ́n èmi yó dúró ní Éfésù títí di Pẹ́ntíkọ́stì, 9 nítorí ìlẹ̀kùn gbòòrò tí ṣí sílẹ̀ fún mi àti pé àwon alátakò púpọ̀ ní ó wà. 10 Nísinsìnyi nígbàtí Tímótíù bádé, ẹ ri dájú pé ódúró pẹ̀lú yín láìsí ìbẹ̀rù, nítorí tí ó ń ṣe isẹ́ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tíń ṣe. 11 Mà ṣe jẹ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ̀. Ẹ ran lọ́wọ́ ní ọ̀nà rẹ̀ ní àlafíà, kí ó báa lè wá sí ọ̀dọ̀ mí. Nítorí mó ń retí rẹ̀ kí ó wá pẹ̀lú àwọn arákùnrùn náà. 12 Ní bà yìí nípa arákùnrín wá Apóllò , mó gbàá níyànjú gidigidi láti bẹ̀yín wò pèlú àwọn arákùnrin náà. Ṣùgbọ́n nítorí kìí ṣe nípa ìfẹ́ inú rẹ láti wá nísinsìnyí. Síbẹ̀, yóò wá nígbàtí àkókò bá tó. 13 Ẹ máa ṣọnáà, ẹdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbó, ẹ́ ṣe bí ọ̀kùnrin, ẹní ìgbóyà. 14 Ẹ má ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́. 15 Ẹ̀yin mọ ìdílé Stéfánà, àwọn ní ẹni àkọ́kọ́ tí ó dí Krìstẹ́nì ní Akaia, wọ́n sì tí fi arawọ́n jìn fún iṣẹ́ ìsìn àwọn onígbàgbọ́. Nísinsìnyí mo bẹ̀ yín, ara, 16 kí ẹ̀yin ki ó rẹ arayín sílẹ̀ fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti sí gbogbo àwọn alábàṣíṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa tí ń ṣe làálàá. 17 Inú mí dùn fún wíwá Stéfánà, Fọ́túnátù, àti Ákáíkù. Wọ́n tí fí kún ohun tí ó kù nígbà tí ẹ kò sí níbẹ̀. 18 Nítorí wọ́n tí tù okànmí lára àti ti yin pẹ̀lú, nítorí náà, ẹ máa ṣe idánimọ̀ irúfẹ́ àwọn ènìyàn bá yìí. 19 Àwọn ijọ ti Ásíà ńki yín. Ákúilà àti Prìskíllà kíi yín nínú Ọlúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ní ilé wọn. 20 Gbogbo àwọn arákùnrin ń kíi yín . Ẹ kí ara yín pẹ̀lú ifẹ̀nukonu mímọ́. 21 Èmi, Pọ́ọ̀lù kọ ohun wọ̀nyí pẹ̀lú ọwọ́ ara mí. 22 Pé bi ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Olúwa, ẹjẹ́ kí ó di ẹni ìfibú. 23 Kí oreọ̀fẹ́ Olúwa wà pẹ̀lú yín. 24 Ìfẹ́ mi wà pẹ̀lú gbogbo yín nínú Krístì Jésù.