1 Nísisìyí nípa oúnjẹ èyí tí a ti fi rúbọ fún òrìsà-àwá mọ́ wípé ''gbogbo wa ni ó ní ìmọ̀''. Ìmò a máa00 gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa kọ́ sókè. 2 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òún mọ ohun kan, ẹni náà kò tíì mọ̀ bótiyẹ kí ó mọ̀ 3 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni báfẹ́ Olúwa, ẹni náà ni Olúwa mọ̀ọ̀. 4 Ǹjẹ́ nípa oúnje tí ati fifún òrìsà- ''àwá mòpé òrìsà nínú ayé yìí jẹ́ asán'' àti'' wípé kòsí ọlọrùn míràn bíkòṣe òkan''. 5 Nítorí bóyá àwọn olúwa míràn wà, ìbáà se ní ọ̀run tàbí ní ayé gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ni àwọn ''ọlọọ́run'' áti àwọn ''olúwa'' ún wà. 6 Síbẹ̀ fún wa,'' Ọlọrun kan ni ó ń bẹ tí íṣe Baba, tí ó dá ohun gbogbo, ẹnití àwá fún, àti Olúwa wa kan tí í se Jésù krístì, ẹnití ohun gbogbo ti ipasè rẹ̀ wà, àti ẹnití a wà nípasè rè.'' 7 Síbè, ìmọ́ yí kò sí nínú gbogbo ènìyàn. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn míràn ún bọ òrìsá tẹ́lẹ̀, wón sì ń jẹ oúnjẹ tí ati fifún òrìsà. Ẹ̀rí ọkàn wọn sì ti díbàjẹ́ nítorí ó ti rẹ̀wẹ̀sì. 8 Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò ní ṣe àfihàn wa níwájú Ọlọ́run. A kó di ẹni ìbàjẹ́ bí akòbá jẹun, bẹ́ẹ̀ni a kò sì di ẹni dídára bí abá jẹun. 9 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí òmìnira rẹ má baà se okùnfà ìsubú fún àwọn aláìlera nínú ìgbàgbó. 10 NÍtorípé bí ẹni tí ó ní ìmò bá rí ọ tí ò ń jẹun nínú ilé òrìsà. Ǹjẹ́ a kò mú ọ̀kan àárè rẹ̀ le láti jẹ oúnjẹ tí ati fifún òrìsà bí?. 11 Ńjẹ́ nítorí ìmọ̀ yín nípa iwa òtítọ́ ti òrìsà, àwọn aláìlera, àwọn ará èyí tí krísítì kú fún ni ó ti bàjẹ́. 12 Nítorínà, bí ìwọ́ bá sẹ sí arákùnrin rẹ tí o sì pa ọkàn wọn tí ó se àìlera lára, o sẹ́ sí krísítì. 13 Nítorínà, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yíò jẹ ẹ́ mó, kí èmi kí ó má ba à mú arákùnrin mi subú.