1 Nísinsìnyí nípa àwọn oun tí ẹ kọ : "Ó dára fún ọkùnrin láti má fi ọwọ́ kan obìnrin," 2 Ṣùgbọ́n nítorí ìdánwò fún àwọn ìṣe aìmọ́, kí olúkúlùkú ọkùnrin ní aya tirẹ̀, àti obìnrin kọ̀okan ní ọkọ tirẹ̀. 3 Kí ọkọ kí ó fún íyàwó rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó, àti ìyàwó sí ọkọ rẹ̀ 4 kì í ṣe ìyàwó ló ní àṣẹ lórí ara rẹ̀, bí kò ṣe ọkọ rẹ̀. Bákànnáà, ọkọ kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀, bíkòṣe aya rẹ̀. 5 Ẹmá ṣe dínà ara yín, bíkòṣe nípa àjọmọ̀ yín àti fún àkókò kan pàtó. Ẹṣe èyí kí ẹ le fi ara yín jìn fún àdúrà. Kí ẹ sì padà wá papọ̀, kí Esù kí ó má báa dán yín wò nítorí àìlè kó ara yín ni ìjánu 6 Mo sọ àwọn ǹkan wọ̀nyí fún yín gẹ́gẹ́ bi ìmọ̀ràn kì í sì ṣe gẹ́gẹ́ bi àṣẹ 7 Ó wù mí kí gbogbo yín rí bíi èmi, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní ẹ̀bùn tirẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ẹnìkan ní ẹ̀bùn èyí, ẹlòmíràn ní t'òhún. 8 Sí àwọn tí ò ti ṣe ìyàwó àti sí àwọn opó mo sọ pé ó dára tí wọ́n bá wà lái ṣe ìyàwó, bí mo ti wà. 9 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá lè kórawọn-ní ìjànú, kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Nítorítí ó dára fún wọn tí wọ́n ba ṣe ìyàwó ju kí wọ́n jóná pẹ̀lú ìtara. 10 Nísinsìnyí mo pàṣe fún àwọn lọ̀kọ láya-kì í ṣe èmi, ṣùgbọ́n Olúwa-kí aya kí ó máṣe yapa kúrò ní ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, 11 (ṣùgbọ́n tí ó bá yapa kúrò ní ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kí ó wà láì ṣe ìyàwó tàbí kí ó ṣe ìbálàjà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀)-ọkọ rẹ̀ kòsì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 12 Ṣùgbón sí ẹ̀yin tí ó kù-èmí wí, kìí ṣe Olúwa-pé bí arákùnrin yín kankan bá ní ìyàwó tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí ó sì ṣe tán láti gbé pẹlu rẹ̀, kí ó má ṣe kọ̀ obìnrin náà sílẹ̀ 13 Bí arábìrin kan bá ní ọkọ tí kò gbàgbọ́, tí ó bà ṣetán láti gbé pẹ̀lu rẹ̀, kí obìrin náà má ṣe kọ̌ sílẹ̀ 14 Nítorípé a ya aláìgbàgbọ́ ọkọ sí mímọ́ nítorí aya rẹ̀ a sì ya aláìgbàgbọ́ aya sí mímọ́ nítorí ọkọ rẹ̀. Bíbẹ̀kọ́ àwọn ọmọ yín yíò jẹ́ aláìmọ́, ṣùgbọ́n ati yà wọ́n sọ́tọ̀ náá. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkejì aláìgbàgbọ́ bá ya kúrò, jẹ́ kó lọ. Ní ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, a kò so arákùnrin àti arábìrin náà pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ́. Ọlọ́run ti pè wá láti gbé nínu àláfíà. 16 Ǹjẹ́ báwo ni ìwọ ó ṣe mọ̀, arábìnrin, bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? tàbí báwo lo ṣe mọ̀, arákùnrin, bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là? 17 Ni tòótọ́ ẹ jẹ́ kí olúkùlùku yín gbé ìgbéayé tí Olúwa ti yàn fun, ẹni kànkan gẹgẹ bí Ọlórun ti pèé. Èyí yi ni òfin mǐ ní gbogbo ìjọ. 18 Ǹjẹ́ a kọ ẹnikẹ́ni ni ilà nígbàtí a pèé láti gbàgbọ́? kí ó má ṣe gbìyànjú láti farahàn gẹgẹ bí aláìkọlà. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wâ láìkọlà nígbàtí a pèé láti gbàgbọ́? A kó gbọdò kọọ́ nílà. 19 Nítorí kì í ṣe ìkọlà tàbí àikọlà ló ṣe kókó. Ǹkan tó ṣe kókó ni gbígbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run. 20 Kí olúkùlùku yín wà nínu ìpè tí ó wà nígbà tí Ọlọ́run pèé sí ìgbàgbọ́. 21 Ǹjẹ́ ẹ jẹ́ ẹrú nígbà tí Ọlọ́run pè yín? Máṣe jẹ́ kó kàn ọ́ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá le di òmìnira, ẹ ṣe àmúlò anfàni náà 22 Fún ènì tí Olúwa pè gẹgẹ bí ẹrú ẹni òmìnira Olúwa. Bákanâ ẹni tí ó d'òmìnira nígbà tí krístì pèé láti gbàgbọ́ jẹ́ ẹrú krístì. 23 A ti rà yín pẹ̀lú iye kǎn, ẹ má ṣe di ẹrú àwọn ènìyàn. 24 Ará, ní ayé ohunkóhun tí òkànkan wà náà ni a ti pè wa láti gbàgbọ́, ẹ jẹ́ká wà bẹ̀ẹ́. 25 Nísinsìyí nípa àwọn tí kò ṣe ìyàwó rárá, èmi kò ní òfin kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ṣùgbọ́n mo fún yîn ní èrò mi gẹ̀gẹ̀ bi ẹnití, nípa àánú Olúwa, jẹ́ ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé. 26 Nítorínà, mo rò pé nítorí ááwọ̀ tí ń bọ̀, ó dára fún okùnrin kí ó wà bí o ṣe wà. 27 Ǹjẹ́ a so ọ́ pọ̀ pẹ̀lú obìnrin? Má ṣe wà láti d'òmìnira kúrò lọ́dọ̀ọ rẹ̀. Ǹjẹ́ o ní òmìnira lọ́dọ̀ aya? Má ṣe wá aya. 28 Ṣùgbọ́n bí o bá ṣe ìyàwó, o kò dá ẹ̀ṣẹ̀. Bí obìnrin tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó ba ṣe ìyàwó, kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tí ó ṣe ìyàwó á ni onírunrú ìṣòro nígbàtí wọ́n bá ngbé, á sì wù mí láti yọ yín kúrò nínú wọn. 29 Ṣùgbọ́n mo sọ èyi, ará: Àkóko náà kúrú. Láti ìsiǹsìyí lọ, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ó ní aya gbé bí ẹni tí kò ní aya rárá. 30 Àwọn tí ń sọkùn kí wọ́n ṣe bí ẹni tí kò sọkún, àti àwọn tí ń yọ̀, bí pé wọn kò yọ̀, àti àwọn tí ń rà bí pé wọn kò ní ǹkankan; 31 àti àwọn tí ń kó ọrọ̀ ayé mọ́yà kí wọ́n má ṣe bí àwọn tí ń jèrè gbogbo ayé. Nítorí ayé ti isìnsiǹyí ń lọ sí òpin 32 Èmi sì fẹ́ kí ẹ dẹ́kun àníyàn ṣíṣe. Ohun tí ó kan okùnrin tí kò tî gbé ìyàwó ni ohun ti Ọlọ́run, bí yó ṣe tẹ́ ẹ lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ohun tí ó kan ọkùnrin tí ó ti gbé ìyàwó ni ohun ayé yìí, bí yó ṣe tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn- 34 ó ti pín ara rẹ̀. Ohun tí ó kan obìnrin tí kò tí ṣe ìyàwó tàbí wúndíá ni ohun ti Olúwa, bí á ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ohun tí ó kan obìnrin tí ò tí ṣe ìyàwó ni ohun ti ayé, bí yò ṣe tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35 Mo sọ èyí fún anfàní yín, àti láti má fi ìdíwọ́ kankan lé yín, mo sọ èyí fún ohun tótọ́, kí ẹ lè báa fi ara yín jìn sí Olúwa láì sí ìdíwọ́ kankan. 36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò wípé òhun kò ṣe ìtọ́jú àfẹ́sọ́nà rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀-bí ó bá tó ẹni tí ń ṣe ìyàwó ósì gbọdọ̀ rí bẹ̀-kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́, kò dá ẹ̀ṣẹ̀. Kí wọ́n ṣe ìyàwó. 37 Ṣùgbọ́n tí ó bá dúró ṣinṣin nínú ọkàn rẹ̀, kò sí lábẹ́ ipá ósì le ṣàkóso ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, tí ó sì pinu ni ọkàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, láti má jǎ ìbálé àfẹ́sọ́na rẹ̀, yí ó ṣe dáradára. 38 Ẹni tó bá fẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ṣe dáradára, ẹni tí ò sì yàn láti má ṣe ìyàwó yó ṣe dáradára si pàápàá. 39 A so obìnrin mó ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láyé. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní ànfààni láti fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá wù láti fẹ, ṣùgbọ́n nínu Olúwa nìkan. 40 Síbẹ̀ nínú ìdájọ́ mi yóò ní inúdídùn bí ó bá wà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà. Mo sì rò pé mo nì Ẹ̀mí Ọlọ́run.