1 Nígbàtí ẹnìkan nínú yín bá ní ááwọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn, ǹjé ó ha lè lọ sí ilé ẹjọ́ ní iwájú aláìgbàgbọ́ adájọ́, bí kò ṣe sí iwájú àwọn onígbàgbọ́? 2 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ti lẹ̀ mọ̀ wípé àwọn onígbàgbọ́ ni yí ó ṣe ìdájó aiyé? Tí ó bá ríbẹ̀ ẹ̀yin yóò ṣe ìdájọ́ aiyé, ẹ kò tì lẹ̀ yanjúu àwọn ọ̀rọ̀ kékèké tí ó ṣe patàkì bí? 3 Ǹjé ẹ kò mọ̀ pé a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ángẹ́lì? ǹjẹ́ a lè ṣe ìdájọ́ àwọn ohun aiye yí nígbàna? 4 Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ ẹ ní láti ṣe ìdájọ́ tí ó jẹmọ́ ti ojojúmọ́, kí ló dé tí ẹ fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí ọwọ àwọn tí kò ní ǹkan ṣe pẹ̀lú ìjọ? 5 Mo sọ èyí sí ìtìjú yiń. Ṣé kò sí ọlọgbọ́n láàrín yiń ti yóò yanjúu ijà láàrín ará bí? 6 Sùgbón bí o tì rí, onígbàgbọ́ kan lọ sí ilé ẹjọ́ nítorí onígbàgbọ́ míràn, tí a sì gbé ẹjọ́ nà sí iwájú adájọ́ tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́! 7 Wípé ìjà wà láàrìn àwọn onígbàgbọ́ ti jẹ́ ìjákulẹ̀ fún yín. È é ṣe tí ẹ kò ku lè jiyà fún aṣìṣe yin? È é ṣe tí ẹ kò kúkú lè gbà láti yàn yín jẹ? 8 Ṣùgbọ́n ẹti ṣẹ̀ ẹ sì ti yan àwọn enìyàn jẹ, tí wọ́n sì jẹ́ arákùnrin yín! 9 Ǹjẹ́ ẹ kò tì lẹ̀ mọ̀ pé aláìṣòdodo kì yó jogún ìjọba Ọlọ́run? Ẹmá ṣe gba irọ́ gbọ́. Ìbálòpọ̀ alíàìmọ́, àwọn abọ̀rìṣà, àwọn alágbèrè, àwọn oní panṣágà, àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ ìbálòpọ ọkùnrin sí ọkùnrin àti obìnrin sí obìnrin, 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọmùtí, asọ̀rọ̀ ẹni láìda, ati alọ́ni lọ́wọ́ gbà - kò sí ẹnìkan nínú wọn tí yo jogún ìjọba Ọlọ́run. 11 Báyìí ni àwon kan nínu yín ṣe rí. Sùgbọ́n ati wẹ̀ yín, a sì ti sọ yín di mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ní orúkọ Jésù Kristì Olúwa ati nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run wa. 12 Ohun gbogbo ló tọ́ sí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun gbogbo ló ní èrè. "Ohun gbogbo ló tọ́ sí mi," ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú wọn kò ní bo rí mi 13 "Ońjẹ wá fún inú, inú wà fún ońjẹ pẹ̀lú," ṣùgbọ́n Ọlórun kò ní ṣe àmúlò wọn. Ara kì í ṣe fún ìbálòpọ̀ ágbèrè. Dípò è yí, ará jẹ́ ti Olúwa, Olúwa yóò sì pèsè fún ara. 14 Ọlọ́run ni ó jí Olúwa, Òhun pẹ̀lú ni yó pa wá lára dà nípa agbára rẹ̀ 15 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín jẹ́ ẹ̀yà ara Krístì? émi o á mú ẹ̀yà ara krìstí kúrò, èmi ó sì dàá pọ́ mọ́ ti aṣẹ́wó bí? Ká má ri. 16 Ǹjẹ́ ìwọ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá darapọ̀ mọ́ aṣẹ́wó di arakàn pẹ̀lú rẹ̀? Bí ìwé mímọ́ ti sọ pé, "Àwọn méjèjì yóò di ara kan." 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá darapọ̀ mọ́ Olúwa di ara kan pẹ̀lú rẹ̀. 18 Sá fún ìbálòpọ̀ àgbèrè! Àwọn ẹ̀ṣè míràn tí ènìyàn ń dá jẹ́ sí ìta ara, ṣùgbọ́n ìbálòpọ̀ àgbèrè ènìyàn ṣe lódì sí ara rẹ̀. 19 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pe ara yín jẹ́ tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó ngbé nínu yín, tí ẹ ní láti ọ̀dọ̀ Ọlórun? Ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé ẹ ọ̀ kí ṣe ti ara yín? 20 Nítorí a ti rà yín ní iye kan. Nítorína ẹ fi ògo fún Ọlọ́run pẹ̀lú ara yín.