Oríkaàrún

1 Agbọ́ ìròyìn pe ẹ̀sẹ̀ àgbèrè wà laàrin yín, èyí tí wọn kò fàyègbà laàrin àwọn élénì. Ìròyìn naà nipé ọ̀kan nínú yín ún bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn. 2 Ẹjẹ́ agbéraga! sé kòyẹ kí ẹ sọ̀fọ̀ dípò? Ẹni tí ó se èyi yẹ kí ó kúrò laarin yin. 3 Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé un kòsí pẹ̀lú yin nínú ara ṣùgbọ́n mowà pẹ̀lú yín nínú ẹ̀mi, mo ti se ìdájọ́ ẹni ti ó se èyi bi ẹni pe mowà níbẹ̀. 4 Ni ìgbàtí ẹ bá péjọ ní orúkọ Jésù olúwa wa, tí èmí mi àti agbára Jésù olúwa sì wà níbẹ̀,èmi ti ṣe ìdájọ́ ẹni nâ 5 Mo se èyí lati fa ẹni naa lé èsù lọ́wọ́ fún ìparun ti ara, kí a le gba ẹ̀mi rè là ni ọjọ olúwa. 6 Ìgbéraga yín kò dára.Ǹjẹ́ ẹ̀yin kòmò pé ìwúkàrà kékeké ama wú gbogbo àkàrà nibí? 7 Ẹwẹ ara yín kúrò nínú ìwúkàrà àtijọ́ kí ẹ lè baà di titun, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ àkàrà àìwú. Nítorítí ati fi krísítì, tí se ọ̀dọ́ àgùntàn ṣe ìrúbọ 8 Nítorí nâ ẹjọ́ kí á yọ ayọ̀ àjọ̀dún náà, ki ṣe ìwúkàrà ti óti gbó, ìwúkàrà ti ìwà búburú àti ìkà. Dípò, ẹjẹ́ kí á yọ̀ pẹ̀lu àìwú àkàrà ti òtítọ́ àti òdodo. 9 Mo kọ si yin nínú ìwé lati má ní ìbásepọ̀ pẹ̀lu àwọn alágbèrè. 10 Kìí se ní ọ̀nà kankan ni mo fi ńtọ́ka sí àwọn alágbèrè ayé yi, tàbí olójúkòkòrò, tàbí alọ́nílọ́wọ̀gbà, tàbí abọ̀rìsà, nígbàtí ójé kí o le ba yàgò fun wọn oní lati kúrò ninu ayé. 11 Ṣùgbọ́n nísiṣìyí mò ún kọ siyin pé kí ẹ máse ní àjọsepọ̀ kankan pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ún gbé ninu àgbèrè, tàbí olójúkòkòrò, tàbí abọ̀rìsà, tàbí abúni ní ọ̀rọ̀ ẹnu, tàbí amutípara, tàbí alọ́nílọ́wọ̀gbà. Ẹmá se jẹun pẹ̀lú ẹni naa pẹ̀lú. 12 Nítorí bí mo ti kópa nínú dídá àwọn tí ówà ni ìta ìjọ lẹ́jọ́? Dípò, nìjẹ́ kòyẹ kí ẹ dá àwọn ti o wà ninu ìjọ lẹ́jọ́ bi? 13 Ṣùgbọ́n olorun ún dá àwọn tí ó wa ní ìta ìjọ lẹ́jọ́? ''Ẹyọ ènìyàn búburú naa kúrò laarin yín.