Orí Kẹrin

1 Bí ó ṣe yẹ ki ènìyàn kó máa kà wá sí nìyi, bí ìránṣẹ́ Krístì àti ìríjú àwọn ìjìnlẹ̀òtítọ́ Ọlọ́run. 2 Àti pẹ̀lú pé, à ń bère lọ́wọ́ ìríjú pé kí ó jẹ́ olótìtọ́. 3 Ṣùgbọ́n ó jẹ́ oun kékeré fún mí kí ẹ ṣe ìdájọ́ fún mí tàbí nípasẹ̀ ìdájọ́ ènìyàn. Nítorí èmí kò dá ara mí lẹ́jọ́. 4 Èmí kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí a fi kàn mí, ṣùgbọ́n èyí kò túnmọ̀ sí pé mo jẹ́ aláìṣẹ̀. Olúwa ló ń se ìdájọ́ mí. 5 Nítorínà, ẹ má se se idájọ́ nípa ohunkóhun sáájú àkókò tí Olúwa yóò fi dé. Òun yíò sì mú ohun òkùkùn tíó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀ àti pé yíò fi ìmọ̀ ọkàn hàn. Nígbànáà ni olúkúlùkù yíò gba èrè rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 6 Nísinsìyí, ẹ̀yin ará, Èmí mú ìlànà yí lò fún ara à mi àti Àpóllò nítorí i yín, kí ẹ lè ti ara wa kọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó wípé, "Ẹ má ṣe ré ohun tí a ti kọ̀wé e rẹ̀ kọjá." Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ẹnikẹ́ni kí ó má tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì. 7 Torí tani ó rí ìyàtọ̀ láàrin ara yín? Kí ní ẹní tí ẹ kò gbàní ọ̀fẹ́? Bí a bá ti fún yín lọ́fẹ̌, è é ṣe tí ẹ̀yin ń halẹ̀ bí ẹni pé ẹ kò gbà á? 8 Ẹ̀yín ti ní ohun gbogbo tí ẹ fẹ́! Ẹ̀yín sì ti jẹ́ olówó! Ẹ̀yin sì ń jọba láìsí àwa! Nítòótọ́, ó wù mí kì ẹ jọba kí àwa náà si jọba pẹ̀lú yín. 9 Nítorí èmí rò pé Ọlọ́run ti fi àwa àpóstélì hàn gẹ́gẹ́bí bí ẹni ìkẹ́hìn àti bíi àwọn tí a dá lẹ́jọ́ ikú. Àwa sì ti dà bí ìran fún àye, àti fún àwọn angẹli àti fún ènìyàn làti wò. 10 Àwá jé òpè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n èyín jé ológboń nínú Kristi. Àwá jé aláìlera, ṣùgbọ́n èyín ní ìlera. Èyin ní ọlá, ṣùgbọ́n àwa pèlú àìlọ́lá. 11 Títí di wákàtí yìí ebi ńpawá òǹgbe sì ń gbewá, awòwá ní aso bíi tálákà, wọ́n lùwá gidigidi, àwá sì wà láì nílé lórí. 12 Àwá ń sisẹ́ kárakáka, à ń sisé pèlú ọwọ́ wa. Nígbà tì gàn wá, àwá súre. Nígbà tí a senúnibíni síwa àwá faradàá. 13 Nígbà tí a sọ̀rọ wa laìda, àwá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́. Àwá ti di, a sìkà wá sí, ẹ̀gbin aiyé àti ohun tí ó ní èèrí jùlọ. 14 Èmi kò kọ nǹkan wọ́nyí láti fi dójú tì yín, ṣùgbọ́n èmi ń bá a wí bí i ọmọ ò mi olùfẹ́. 15 Nítorí tí ẹ̀yín bá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wǎ olùtọ́ni nínú Krístì, ẹ̀yin kò ní baba púpọ̀. Nítorí mo di baba yín nínú Jésù Krístì nípa ìhìnrere. 16 Nítorínáà mo bẹ̀ yín kí ẹ se àfarawé è mi. 17 Fún ìdí èyí ni mo se rán Tímotíù, olùfẹ́ mi àti ọmọ mi nínú Olúwa nítòótọ́. Yíó mǔ wá sí ìrántí i yín ọ̀nà mi nínú Krístì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ̀ ọ ní ibi gbogbo àti ní ìjọ gbogbo. 18 Nísisìyí àwọn kan nínú un yín ń gbéraga, bí ẹni wípé èmikò tọ̀ yín wá. 19 Ṣùgbọ́n èmi yíò tọ̀ yín wá ní kánkán, tí Olúwa bá fẹ́. Nígbànáà èmi kò ní mọ ọ̀rọ̀ àwọn tí óń gbéraga nìkan, ṣùgbọ́n èmi yíò rí agbára wọn. 20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kò sí nípa ọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n nípa agbára. 21 Kíni ẹyín fẹ́? Ǹjẹ́ kí èmi kí ó tọ̀ yín wá pẹ̀lú pàsán tàbí ìfẹ́ àti nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?