1 Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Krístì. 2 Wàrà ni mo fi ń bọ́ yín, kì í ṣe òkèlè; nítorí ẹ kò tí le gbà á nísinsìn yìí náà, ẹ kò í tí le gbà á. 3 Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí ibí tí owú àti ìjà bá wà láàrín yín, ẹ̀yin kò ha máa gbé nípa ti ara bí, ẹ̀yin kò ha máa rìn nípa ìlànà ènìyàn bí? 4 Nítorí nìgbà tí ẹnìkan ba wípé, “Èmi ń tẹ̀lé Páúlù,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Àpóllò,” ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha máa gbé bí ènìyàn? 5 Ta ni Àpóllò? Tani Páúlù? àwọn ìránṣẹ́ nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi rán olúkúlùkù. 6 Èmi gbìn, Àpóllò ń bomirin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìdàgbà wá. 7 Ǹjẹ́ ẹni tí ó ń gbìn bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ó ń mú ìbísí wá. 8 Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín jẹ́ ọ̀kan, ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. 9 A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni. Ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, ilé Ọlọ́run. 10 Gẹ́gẹ́ bíi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀lé ọlọ́gbọ́n, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọn lé e. 11 Nítorí kò sí ẹni tó le fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀, àní, Jésù Kristì. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko, mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13 A ó fi iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn. Nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn. Iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá dúró, òun yóò gba èrè rẹ̀; 15 Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, bí ìgbà tí ènìyàn bá iná kọjá. 16 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé tẹ́mpílì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́ àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹ́mpílì Ọlọ́run jẹ́, Ọlọ́run yóò parun. Nítorí pé mímọ́ ni tẹ́mpílì Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni ni ẹ̀yin jẹ́. 18 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Bí ẹnikẹ́ni nínú yín ba rò pé òun gbọ́n ní ìgbà yí, ẹ jẹ́ kí ó di "òmùgọ̀" kí ó bá a le è gbọ́n. 19 Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn.” 20 Bákannáà “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 21 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn mọ́. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo, 22 Ìbá ṣe Páúlù, tàbí Àpóllò, tàbí Céphásì, tàbí aiyé, tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun tí ń bọ̀. Tiyín ni gbogbo ǹkan, 23 ẹ̀yin sì ni ti Krístì, Krístì sì ni ti Ọlọ́run.