1 Nígbàtí mo tọ̀ yín wá, ará, èmi kò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn tàbí ọgbọ́n orí nígbàtí mo kéde ìjìnlẹ̀ òtítọ́ Ọlọ́run fún un yín. 2 Nítorípé èmi pinnu wípé èmi kò ní mọ ohunkóhun nígbàtí mo wà láàrin yín bíkòṣe Jésù Krístì, Ẹnití a kàn mọ àgbélèbú. 3 Èmi wà pẹ̀lù yín nínú àìlera, nínú ẹ̀rù àti nínú ìwárìrì púpọ̀. 4 Ọ̀rọ̀ mi àti ìkéde mi kìí ṣe pẹ̀lu ọgbọ́n ènìyàn tí a fi ń yí ni lọ́kàn padà. Bíkòṣe nípa ìfihàn ti Ẹ̀mí ati agbára. 5 Kí ìgbàgbọ́ yín mába dúró nínú ọgbọ́n ènìyàn, sùgbọ́n nínú agbára Ọlọ́run. 6 Nìsinsìnyí àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrin àwọn tí ó dàgbà, sùgbọ́n kìí ṣe ọgbọ́n ayé yìí, tàbí ti alásẹ ayé yìí, tí yóò kọjá lọ. 7 Ṣùgboń àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run nínú ìjìnlẹ̀ òtítọ́, ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti pinu tẹ́lẹ̀ saájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ìṣelógo wa. 8 Kò sí ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ ọgbọ́n yìí, nítorípé tí wọ́n bá ní òye yìí ní àkókò náà, wọn kì bá tí kan Olúwa ògo mọ́ àgbélèbú. 9 Ṣùgbón gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, "Àwọn ohun tí ojú kò tíì rí, tí etí kò tíì gbọ́, tí ọkàn kankan kò tíì rò, àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tó fẹ́ràn Rẹ." 10 Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun tí Ọlọ́run ti fi hàn nìpasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀. Nítorípé Ẹ̀mí a má a wadi ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ ti Ọlọ́run. 11 Nítorí tani ó mọ àwọn èrò enìkan bíkòṣe ẹ̀mí ẹni náà nínú rẹ̀? Bákannáà enìkan kò mọ àwọn ohun ìjìnlẹ Ọlọ́run bíkòse Ẹ̀mí Ọlọ́run. 12 Ṣùgbọ́n àwa kò gba ẹ̀mí ti ayé, bíkòṣe Ẹ̀mí tí ó wà làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí àwa kí ó lè mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fifún wa lọ́fẹ̀ẹ́ 13 Àwa ńsọ àwọn ǹkan wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ọgbọ́n ènìyàn kò lè kọ́ni, ṣùgbọ́n tí Ẹ̀mí ńkọni. Ẹ̀mí a má túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí pẹ̀lu ọgbọ́n ti ẹ̀mí. 14 Ènìyàn nípa ti ara kò gba àwọn ohun ti o jẹ́ ti Èmí Ọlọ́run, nítorípé wèrè ni wọ́n jásí fún un. Òun kò lè mọ̀ wọn nítorípé nípa ẹ̀mí ni a fi ń wádi wọn. 15 Ẹnití ó jẹ́ ẹni ẹ̀mí ń wádi ohun gbogbo, ṣùgbọ́n òun kò wà lábẹ́ ìwádìí ẹnikẹ́ni. 16 Nítorí tani ó le mọ ọkàn Olúwa, ti yó fi ma kọ́ Ọ? "Ṣùgbọ́n àwa mọ ọkàn Krístì."