1 Pọ́ọ́lù, ẹnití Krístì Jésù pè láti jẹ́ Àpọ́stẹ́lì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Sọ́sténì arákùnrin wa. 2 sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríntí, sí àwọn tí ati sọ di mímọ́ nínú Krístì Jésù, àwọn tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́. Àwá sì ń kọ ìwé yìí pẹ̀lú sí àwọn tí ó ń pe orúkọ Olúwa wa Jésù Krístì ní ibi gbogbo. Olúwa wọn àti Olúwa wa. 3 Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlááfìa wà pẹ̀lú yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì Olúwa. 4 Èmi sì ń fi ìgbà gbogbo dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run fún un yín nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti Jésù Krístì fi fún un yín 5 Òun si ti sọ yin di ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ní ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ gbogbo, 6 gẹ́gẹ́ bí a ti fi òdodo ẹ̀rí nípa Krístì múlẹ̀ láàrin yín. 7 Nítorínà ẹ̀yin kò se aláìní ẹ̀bùn ẹ̀mí bi ẹ̀yin ti fi ìtara dúró fún ìfihàn Olúwa wa Jésù Krístì. 8 Òun pẹ̀lú yó fún un yin ni ókun títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó le wà láì l'àbàwọ́n ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Krístì. 9 Olóòótọ́ ni Ọlọ́run, Ẹnití Ó pèyín sínú ìdàpọ̀ ti Ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì Olúwa wa. 10 Nísinsìnyí èmí bẹ̀ yín, ará, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Krístì , wípé kí gbogbo yín fi ohùn sọ̀kan, àti wípé kí ìyapa kí ó máse sí láàrin yín. Èmí bẹ̀ yín kí ẹ darapọ̀ ní inú kan àti ìdí kan. 11 Nítorípé a jẹ́ kí ó yé mi, ẹ̀yin ará mi, láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé Kílóè pé ìyapa wà láàrin yín. 12 Èyí túmọ̀sí, olúkúlùkù yín wípé, "èmi dúró pẹ̀lú Pọ́ọ́lù" tàbí "èmi dúró pẹ̀lú Àpólò" tàbí "èmi dúró pẹ̀lú Kefa" tàbí "èmi dúró pẹ̀lú Krístì." 13 Ǹjẹ́ ìpinyà wà nínú Krístì bí? Ǹjẹ́ Pọ́ọ́lù ni a kànmọ́ àgbélèbú fún un yín bí? Tàbí ní orúkọ Pọ́ọ́lù ni a se ìtẹ̀bomi fún un yin bí? 14 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorípé émi kò se ìtẹ̀bọmi fún ẹnikẹ́ni yín, bíkòṣe Krispu àti Gaiu. 15 Èyí sẹlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni kí ó másọ wípé mo se ìtẹ̀bọmi fún un yín ni orúkọ ara mi 16 (Mo sì tún ṣe ìtẹ̀bọmi fun ìdílé Stífánì. Lẹ́yìn èyí, èmi kò mọ bí mo ṣe ìtẹ̀bọmi fún ẹlòmíràn.) 17 Nítorípé Krístì kò rán mi láti ṣe ìtẹ̀bọmi bíkòṣe láti wàásù ìhìnrere. Òun kò rán mi láti wàásù pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti ènìyàn. Kí agbára àgbélèbú Krístì máṣe di asán. 18 Nítorí ọ̀rọ̀ àgbélèbú jẹ́ ọ̀rọ̀ asiwèrè fún àwọn tí ń ṣègbé. Ṣùgbọ́n láàrin àwọn tí Ọlọ́run ń gbàlà, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. 19 Nítorí a ti kọ ọ́ pé, "Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọgbọ́n run. Èmi yóò sì sọ òye àwọn olóye di asán." 20 Níbo ni ọlọgbọ́n náà wà? Ńíbo ni ọ̀mọ̀wé náà wà? Níbo ni òjiyàn ayé yìí náà wà? Ọlọ́run kò a ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di wèrè bí? 21 Níwọ̀n bí aráyé kò ti mọ Ọlọ́run nínú ọgbọ́n Rẹ̀. Ó wu Ọlọ́run nipa wèrè ìwàásù láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là. 22 Nítorípé àwọn Júù ń bèrè fún àmì àti àwọn Helenì ń wá ọgbọ́n. 23 Ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Krístí tí a kàn mọ́ àgbélèbú. Òkúta ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti wèrè sí àwọn Helenì. 24 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí Ọlọ́run ti pè, Júù àti Helenì, àwa ń wàásù Krístí tí ṣe agbára Ọlọ́un àti ọgbọ́n Ọlọ́un. 25 Nítorípé wèrè Ọlọ́run gbọ́n ju ènìyaǹ lọ, àti àìlera Ọlọ́un lágbára ju ènìyàn lọ. 26 Ẹ wo ìpè yín, ará. Kìí se ọ̀pọ̀ yín ni o jẹ ọlọgbọ́n bí o ti wà nínú ayé. Kìí ṣe ọ̀pọ̀ yín ni ó jẹ́ alágbára. Kìí ṣe ọ̀pọ̀ yín ni a bí ní ilé ọ́lá. 27 Ṣùgbón Ọlọ́run yàn àwọn ohun asiwèrè ayé yìí láti dójúti àwọn ọlọgbọ́n. Ọlọ́run yan àwọn ohun aláìlera láti dójúti àwọn ohun tó lágbára. 28 Ọlọ́run yan àwọn ohun tí a rẹ̀ sílẹ̀ àti tí a kẹ́gàn ní ayé yìí. Òun sì yan àwọn ohun tí a kàsí asán, láti sọ dí asán àwọn ohun tí ó ṣe iyebíye. 29 Òun ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni mába ní ìdí láti ṣògo níwáju Rẹ̀. 30 Nítorí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe, nísinsìnyì ẹ̀yin wà nínú Krístì Jésù, Ẹnití Ó jẹ́ ọgbọ́n Ọlọ́run fún wa. Òun di òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadá wa. 31 Fún ìdí èyí, gégé bì ìwé mímọ́ ti wí, "Jẹ́kí enití ń ṣògo, máa ṣògo nínú Olúwa."