1 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti gbìyànju láti ṣàlàyé ìtàn àwọn ohun tó ti wá sí ìmúṣẹ láàrin wa, 2 gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe àgbékalẹ̀ wọn fún àwa tí a jẹ́ ẹlẹ́rìí ojúkoojú àti òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìráńṣẹ́ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. 3 Nítorí nàà ó jẹ́ ohun tí o tọ́ lójú mi - lẹ́yìn tí mo ti ṣe ìwádìí fínnífínní lóríi àwọn nǹkan wọ̀nyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ - láti kọ ìtàn yí ní ṣíṣẹ́ǹtẹ̀le fún yín, Ọlọ́lá jùlọ Tìófílù. 4 Èyí ni láti jẹ́ kí ẹ̀ mọ òtítọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ yín. 5 Ní ìgbà ìjọba Hẹ́rọ́dù, ọba Jùdíà, àlùfáà kan wà láti ìpín Ábíjà tí à ń pé ní Sekaráyà. Ìyàwó rẹ̀ wá láti ìdìlè Áárónì, orúkọ rẹ́ a sì máa jẹ́ Èlísabẹ́tì. 6 Àwọn méjéèjì dúró déédé níwájú Olúwa, wọn a sì máa pa gbogbo òfin àti ìlànà Rẹ̀ mọ́ 7 Sùgbọ́n wọn kò lọ́mọ, nítorí tí Èlísabẹ́tì yàgàn, àwọn méjéèjì sì ti dàgbà gan lásìkò yí. 8 Ó sì ṣe Sekaráyà wà níwájú Olúwa ó ń ṣe iṣé àlùfáà nígbàtí iṣẹ́ kan ìpín rẹ̀. 9 Gẹ́gẹ́ bí àṣà tí wọ́n fi ń yan èwo nínú àwọn álúfáà ni yíò ṣiṣẹ́, a ti yàn àn láti wọnú témpílì Olúwa lọ láti sun tùràrí. 10 Gbogbo àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn ńà sì ń gbàdúra níta nígbàtí wọ́n sun tùràrí náà. 11 Ǹjẹ́ nísinsìnyí áńgẹ́lì Olúwa kan yọ sí i, ó sì dúró lápá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Nígbàtí Sekaráyà rí i, jìnnìjìnní bò ó, ẹ̀rù sì bá á. 13 Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún ún pé, "Má bẹ̀rù, Sekaráyà, nítorí tí àdúrà rẹ ti gbà. Èlísabẹ́tì ìyàwó rẹ yí ò bí ọmọkùnrin kan fún ọ. O ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù. 14 Ayọ̀ rẹ yíò kún inú rẹ yíó sì dùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yíó sì yọ̀ nígbà tí a bá bí i. 15 Nítorí tí yíò jẹ́ ẹni ńlá níwájú Olúwa. Kò gbọdọ̀ fẹnukan ọtí wáìnì tàbí ọtí líle, a ó sì fi Ẹ̀mí Mímọ́ kún un láti inú ìyá rẹ̀ wá. 16 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn Ísrẹ́lì ni a ó yí padà sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 17 Yí ò lọ síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà. Yíó ṣe èyí láti yí ọkàn àwọn baba padà sí àwọn ọmọ, kí àwọn aláìgbọ́ràn le rìn nínú ọgbọ́n àwọn ẹni mímọ - láti ṣètò àwọn tí a ti palẹ̀ mọ́ de Olúwa. 18 Sekaráyà wí fún áńgélì náà pé, "Báwo ni n ó ṣe mọ èyí? Nítorí arúgbó ni mí, ìyàwó mi náà sì ti dàgbà gan. 19 Áńgẹ́lì náà dáalóhuǹ pé, èmi ni Gébúrẹ́lì, ẹnití ó ń dúró níwájú Ọlọ́run. A rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, láti fún ọ ní ìròyìn dárádárá yìí. 20 Wòó! O ó yadi, o kò sì ní le sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ ti gbogbo nǹkan yìí yí ó fi wá sí ìmúsẹ; nítorí pé o ò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, won yíò sì wá sí ìmúsẹ nígbà tó bá yá. 21 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn ti ń dúró de Sekaráyà. Ó ń jọ wọ́n lóju pé ó ti ń pẹ́ jù nínúu tẹ́ḿpìlì. 22 Nígbà tí ó jáde síta, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Ó wá yé wọn pé ó ti ríran kan nígbà tí o wà nínú tẹ́ḿpìlì. Níṣe ló ń fọwọ́ ṣàpèjúwe sí wọn, kó lé sọ̀rọ. 23 Nígbàtí ọjọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sì pé, ó gba ilé rẹ̀ lọ. 24 Lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún. Ó sì farapamọ́ fún oṣù márùn ún gbáko. Ó wípé, 25 "Olúwa ló ṣèyí fún mi nígbàtí Ó bojú àánú wò mí láti pa ẹ̀gàn mi rẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn mi. 26 Ní oṣù kẹfà, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì tí à ń pè ní Násárẹ́tì, 27 sí ọ̀dọ̀ wúndíá kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ọ̀gbẹ́ni kan tí a mọ̀ sí Jósẹ́fù. Ó wá láti ìran Dáfídí, orúkọ wúndíá náà a sì má a jẹ́ Màríà. 28 Ó wá bá a ó sì wípé, "Mo kí ọ o, ìwọ ẹnití ó rí ojúrere ńlá gbà! Olúwa wà pẹ̀lú rẹ." 29 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà rú u lójú, ó sì ń wòye pé irú ìkìni kínni èyí ìbá jẹ́. 30 Áńgẹ́lì náà wí fún un pé, "Máṣe bẹ̀rù, Màríà, nítorí o ti rí ojú rere gbà lọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 31 Wò ó, ìwọ yí ò lóyún, ìwọ yí ò sì bí ọmọkùnrin kan. 'Jésù' ni ìwọ yí ò sọ orúkọ Rẹ̀. 32 Òun yí ò jẹ́ ènìyàn ńlá, Ọmọ Ọ̀gá ògo la ó sì ma pè é. Olúwa Ọlọ́run yí ó sì fún Un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá ńlá Rẹ̀. 33 Yí ò jọba lórí ilé Jákọ́bù títí láí, ìjọba Rẹ̀ kì yí ò sì lópin. 34 Màríà bi áńgẹ́lì náà pé, "Báwo lèyí yí ò ṣe ṣẹlẹ̀ nígbàtí n kò tí ì bá ọkùnrin kankan sùn rí?" 35 Áńgẹ́li náà dá a lóhùn pé, "Ẹ̀mí Mímọ́ yí ò bà lé ọ, agbára Ọ̀gá Ògo yí ó sì bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Ọlọ́run la ó pe Ẹni Mímọ́ tí a ó bí náà. 36 Wò ó, Èlísábẹ́tì ìbátan àn rẹ gan ti lóyuń ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Èyí ni oṣù kẹfà fún ẹnití ayé pè lágàn. 37 Nítorí kò sí ohun tí kò ní seése fún Ọlọ́run." 38 Màríà sì wípé, "Wòó, ìráńṣẹ́-bìnrin Olúwa ni mí. Jẹ́ kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí a fi rán ọ. Áńgẹ́lì náà sì kúrò lọ́dọ́ ọ rẹ̀. 39 Nígbà náà ni Màríà gbéra ní ọjọ́ wọ̀nnì, ó sì yára lọ sí agbègbè orí òkè lọ sí ìlú kan ní Jùdíà. 40 Ó wọ inú ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísábẹ́tì. 41 Ó sì ṣe, nígbàtí Èlísábẹ́tì gbọ́ ìkíni Màríà, ọmọ tí ó wà nínú rẹ̀ fò fáyọ́, Èlísábẹ́tì sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 42 Ó pariwo lóhùn rara ó sì wípé, "Olóríire ni ọ́ láàrin àwọn obìrìnrin, alábùnkúnfún sì ni èso inú rẹ. 43 Èétirí tí ìyá Olúwa mi fi tọ̀míwá. 44 Nítorí ní kété tí mo gbọ́ ìkíni rẹ, ọmọ inú mi fò fáyọ̀. 45 Alábùnkúnfún ni ẹni náà tí ó gbàgbọ́ pe ohun ti Olúwa sọ fún un yíó wá sí ìmúṣẹ. 46 Màríà wípé, ọkàn mi yin Olúwa, 47 ẹ̀mí ì mi sì ti yọ̀ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi. 48 Nítorí tí Ó ti kíyèsí ipò ìrẹ̀lẹ̀ ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ̀. Kíyèsi, láti ìsinsìnyí lọ, gbogbo ìran ni yíò máa pè mí ní alábùnkúnfún. 49 Nítorí tí Ẹni ńlá ti ṣe ohun ńlá fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ Rẹ̀. 50 Àánú Rẹ̀ wà láti ìran dé ìran àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀. 51 Ó ti fi agbára hàn ní apá Rẹ̀; Ó sì ti fọ́n àwọn tí ó gbéraga nípa èrò ọkàn an wọn ka. 52 Ó ti gba agbára lọ́wọ́ àwọn ọmọ aláde, Ó sì ti gbé àwọn onírẹ̀lẹ ga. 53 Ó fi ohun dídára bọ́ àwọn ti ebi ń pa yó, ṣùgbọ́n Ó rán àwọn ọlọ́rọ̀ lọ lọ́wọ́ òfo. 54 Ó ti ran Ísrẹ́lì ìránsẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó le ṣàànú fún un 55 (gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣèlérí fún àwọn bàbá wa), fún Ábráhámù àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ títí láí. 56 Màríà wà pẹ̀lú Èlísábẹ́tì fún bíí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ló padà lọ sílé e rẹ̀. 57 Ǹjẹ́ àsìkò àti bímọ ti tó fún Èlísábẹ́tì ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ pé Olúwa ti fi àánú ńla Rẹ̀ hàn án, wọ́n sì bá a yọ̀. 59 Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ wọn wá kọlà fún ọmọ náà. Wọn ti fẹ́ sọ ọ́ ní Sekaráyà, gẹ́gẹ́ bí orúkọ bàbá rẹ̀. 60 Ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ dáhùn pé, "Rárá. Jòhánù ni yíò má a jẹ́." 61 Wọ́n wí fún un pé, "kò sí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ìbátan yín tí ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀." 62 Wọ́n ṣàpèjúwe fún bàbá rẹ̀ pé orúkọ wo ló fẹ́ sọ ọ́. 63 Bàbá rẹ̀ béèrè fún nǹkan ìkọ̀wé ó sì kọ ọ́ pé, "Jòhánù ni orúkọ rẹ̀." Èyí sì jọ gbogbo wọn lójú. 64 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ẹnu rẹ̀ là ahọ́n rẹ̀ sì tú. Ó sọ̀rọ̀ ó si yin Ọlọ́run lógo. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ó wà láyíká wọn. Òkìkí nǹkan wọ̀nyí sì kàn yíká gbogbo agbègbè Jùdíà. 66 Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sì pa nǹkan wọ̀nyí mọ̀ ní ọkàn wọn, wọ́n wípé, "Irú ènìyàn wo ni ọmọ yí yíò wá jẹ́?" Nítorí tí ọwọ Olúwa wà lára rẹ̀. 67 Sekaráyà bàbá rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé, 68 "Ìyìn ni fún Olúwa Ọlọ́run Ísrẹ́lì, nítorí tí ó ti wá láti ṣe ìrànwọ́ àti láti ṣe ìmúṣẹ ìràpadà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀. 69 Ó ti gbé agbára ìgbàlà dìde fùn wa ní ilé Dáfídí ìráńṣẹ́ Rẹ̀, 70 gẹ́gẹ́ bí Ó ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ rẹ̀ tí wọ́n ti wà láti ìgbà àtijọ́ 71 Yí ò fún wa ní ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kóríra wa. 72 Yí ó ṣe èyí láti ṣàánú àwọn bàbá wa àti láti rántí májẹ̀mú mímọ́ Rẹ̀, 73 ẹ̀jẹ́ tí Ó jẹ́ fún Ábráhámù bàbá wa 74 Ó búra fún wa pé, lẹ́yìn tí a bá ti gbàwá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yí ò le sìn Ín láì sí ìbẹ̀rù, 75 ní ìwà mímọ́ àti ìdúró déédé níwájú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. 76 Bẹ́ẹ̀ni, àti ìwọ, ọmọ, wòlíì Ẹni Gíga Jùlọ ni a ó ma pè ọ́, nítorí ìwọ yí ò lọ ṣíwájú Olúwa láti pa ojú ọ̀nà Rẹ̀ mọ́ àti láti pèsè àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún dídé Rẹ̀, 77 láti fi ìmọ̀ ìgbàlà hàn fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 78 Èyí yí ò ṣẹlẹ̀ nítorí àánú Ọlọ́run tó pọ̀ lórí àwọn ènìyàn Rẹ̀, nítorí èyí tí òtítọ̀ ti ẹ̀mí bíi òòrùn láti òkè wá yí ó fi wá ràn wá lọ́wọ́, 79 láti ràn sórí àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn àti òjìji ikú. Yí ó ṣe èyí láti tọ́ wa sí ipa ọ̀nà àlàáfíà. 80 Ǹjẹ́ ọmọ náà dàgbà ó sì di akọni nínú ẹ̀mí, ó sì wà nínú aginjù títí ó fi di ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní gbangba fún Ísrẹ́lì.