1 Ìwé tí mo ti kọ́kọ́ kọ sí ọ, Tìófílù, sọ gbogbo ohun tí Jésù bẹ̀rẹ̀ síí ṣe àti sí i kọ́, 2 títí adi ọjọ́ tí a gbà Á s'ókè, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti pa àṣẹ láti ipasẹ Ẹ́mí Mímọ́ fún áwon àpóstélì tí Ó ti yàn. 3 Lẹ́yìn ìjìyà Rẹ̀, Ó fi ara rẹ̀ hàn wọ́n l'áàyè pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí ó dájú. Fún ogójì ọjọ́ ni ó fi ara hàn wọ́n, tí ó sì sọ nípa ìjọba Ọlọ́run. 4 Nígbàtí Ó ṣe ìpàdé pẹlú wọn, ó pàṣẹ fún wọn láti máṣe kúrò ní Jèrúsálémù, ṣùgbọ́n kí wọ́n dúró de ìlérí tí Bàbá ṣe, wípé, "Ẹ́yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi 5 pé nítòótọ́ ni Jòhánù fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi fún yín, ṣùgbọ́n a ó tẹ̀ yín bọ'mi nínú Ẹ̀mí Mímọ́ níwọ̀n ọjọ́ díẹ́." 6 Nígbàtí wọ́n sì péjọ pọ̀, wọ́n bii léèrè wípé, "Olúwa, ǹjẹ́ ísinsìnyí lẹ fẹ́ dá ìjọba padà fún Ísráẹ́lì?" 7 Ó sì wí fún wọn pé, " Kìí ṣe fún un yín láti mọ ígbà tàbí àkókò tí Bàbá ti pinnu nípa àṣẹ Òun tìkararẹ̀. 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yó gba agbára, nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ bá sọ̀kalẹ̀ sórí yín, ẹ̀yin ó sì jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí mi ní Jèrúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà, àti títí dé òpín ayé." 9 Nígbàtí Jésù Olúwa ti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, bí wọ́n sì ti ń wo òkè, a gba Á s'ókè, àwọ̀ sánmà kan sì pa Á mọ́ kúrò ní ojú wọn. 10 Bí wọ́n sì ti ń tẹjú mọ́ ọ̀run bí Ó ti ń lọ, l'ójijì, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ funfun dúró l'ẹ́gbẹ wọn. 11 Wọ́n wípé "Ẹ́yin ará Gálílì, èéṣe tí ẹ̀yin dúró níbíyìí tí ẹ sì n wo ojú ọ̀run? Jésù yí tí a gba sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú ọ̀run, yóò tún padà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti rí I tí Ó n lọ sínú ọ̀run." 12 Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jèrúsálémù láti Òkè Ólífì, èyí tí ó súnmọ́ Jèrúsálẹ́mù, ni ìwọ̀n ìrìn àjò ọjọ́ ìsinmi kan. 13 Nígbàtí wọ́n sì dé bẹ̀, wọ́n lọ sí yàrá òkè, níbi tí wọ́n ńgbé. Àwọn wọ̀nyí ni, Pétérù, Jòhánù, Jákọ́bù, Áńdérù, Fílípì, Tómásì, Bátólómíù, Mátíù, Jákọ́bù ọmo Álféú, Símónì ọmọ ẹgbẹ́ onítara ẹ̀sìn ti a mọ̀ sí Sílọtì, àti Júdásì ọmọ Jákọ́bù. 14 Gbogbo wọn sì wà ní ìṣọ̀kan, bí wón ṣe n fi ìtara tẹ̀síwájú nínú àdúrà. Àwọn obìnrin, Màríà ìyá Jésù, àti àwon arákùnrin Rẹ̀ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 15 Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nnì, Pétérù dìde dúró láàrin àwọn arákùrin, tí ó tó ìwọ̀n ọgọ́fà ènìyàn, ó sì sọ wípé 16 " Ẹ̀yin ará, ó ṣe pàtàkì kí ìwé mímọ́ wásí ìmúṣẹ, èyí tí a ti ipasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dáfídì nípa Júdásì enití ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí o mu Jésù. 17 Nítorí òun ti jẹ ọ̀kan lára wa rí, ó sì ti jẹ àǹfàní isẹ́ ìránṣẹ́ yi". 18 (Ǹjẹ́, okùnrin yi ti ra ilẹ̀ kan pẹ̀lú owó tó pa nínú ìwà ìkà rẹ̀, níbẹ̀ ni o sì ti ṣubú láti ibi gíga, tí ó forí lulẹ̀, tí ara rẹ̀ sì bẹ́, tí gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jade. 19 Gbogbo àwọn tí ngbé ní Jèrúsálémù sì gbọ nípa èyí, wọ́n sì pe ilẹ́ náà ni "Akeldama" ní èdè wọn, èyí tí ó túmọ̀ sí "Ilẹ̀ Ẹ̀jè.") 20 Nítorí a ti kọọ́ nínú Iwé Sáàmù pé, 'Jẹ́ kí ilẹ̀ rẹ̀ kí ó di ahoro, kí ẹnìkẹ́ni má sì ṣe gbé inú rẹ̀'; 'Sì jẹ́ kí ẹlòmíraǹ gbà ipò adarí rẹ̀.' 21 Nítorína, ó ṣe pàtàkì pe kí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin ti ó ń ti tẹ̀lé wa láti ìgbà ti Jésù Olúwa ti n wọléwọ̀de láàrin wa, 22 bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìtẹ̀bọmi Jòhánù títí di ìgbà tí a gbé E lọ sókè kúrò ní ọ̀dọ̀ wa, ẹni yi gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́ri àjínde Rẹ pẹ̀lú wa." 23 Wọ́n sì pe àwọn ọkùnrin méjì síwájú, Jóséfù tí à n pè ní Básábà, ẹnití a tún ń pè ní Justu, àti Màtáyà. 24 Wọ́n gbàdúrà wọ́n sì wípé, " Ìwọ, Olúwa, ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyaǹ, nítorínáà ṣe àfihàn èwo nínú àwon méjì yí ni ìwọ ti yàn, 25 ki ó le dípò àlàfo ti Júdási fi sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ yi àti nínu ìpè àwọn àpóstélì nínú èyí ti oun ti kọsẹ̀ nígbàtí ó yan ipa tirẹ̀. 26 Wọ́n sì dìbò fún wọn, ìbò sì mú Màtáyà, a sì kàá mọ́ àwọn àpóstélì mọ́kànlá.