Orí Kìnní

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́stélì ti Krístì Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Tímótiù arákùnrin wa, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríntì, àti sí gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tí ó wà ní gbogbo agbègbè Ákáíà. 2 Kí ore-ọfẹ́ jẹ tíyín àti àláfíà lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bàbá wa àti Olúwa wa Jésù Krístì. 3 kí ìyìn jẹ̀ tí Ọlọ́run Bàbá wa àti Olúwa wa Jésu Krístì, ohun ní Bàbá àánú àti Ọlọ́run ìtùnú. 4 Ọlọ́run tù wá nínú ní gbogbo ìpọ́njú wa, ki a ba lè tu àwọn tó wà nínú ìpọ́njú kọkan. A tu awọn ẹlòmíràn nínú pẹ̀lú ìtùnú kan náà tí Ọlọ́run fi tù wà nínú. 5 Gẹ́gẹ́ bí ìjìyà krístì tí di pupọ̀ nítorí wa, bẹ́ẹ̀ naa ni ìtùnú wa di púpọ̀ nípasẹ̀ Krístì. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pọ́n wa lójú, ó wà fún ìtùnú àti ìgbàlà yìn, àti tí a bá sì tù wà nínú, ó wà fún ìtùnú yín. Ìtùnú yín á má ṣe iṣẹ́ àṣepé nígbàtí ẹ bá fi sùúrù jẹ́ alábàápín nínú ìjìyà rẹ̀ pẹ̀lú. 7 Ìgboyà wa nínú yín dájú, nítorí a mọ̀ wípé gẹ́gẹ́ bí a ṣe pín nínú ìjìyà Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a ó pín nínú ìtùnú Rẹ̀. 8 Nítorí a kò fẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè, ẹ̀yin ará, nípa ìpọ́njú tí a dojú kọ ní Ásíà. Adi wíwó palẹ̀ pátápátá ju ohun tí a le gbàmọ́ra, púpọ̀ débi pe a kò tilẹ̀ nírètí pé alè wà láàyè mọ́. 9 Kódà, ati dá ẹjọ́ ikú fún wa. Ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ọ̀nà láti má ṣe fi igbẹ́kẹ̀lé sínú ara wa, bíkòse sínú Ọlọ́run, Ẹni tí ń jí òkú dìde. 10 Ó gbàwá lọ́wọ́ ìparun òjijì , yóò sì tún gbàwá lẹ́ẹ̀kán sii. Àwa ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀ pé Òun yóò tún gbàwálà ní ẹ̀kèjì. 11 Yóò ṣe èyí bí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe nfí àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbànáà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò má dúpẹ́ nítorí wa nípa ore-ọ̀fẹ́ àti ojú rere nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ àdúrà yín. 12 À ń ṣògo nípa èyí, ìjẹri ọkàn wa. Nítorití ó jẹ́ nípa èrò mímọ́ àti ìsòtítọ́ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí a ṣe ètò rẹ sílẹ̀ fún wa nínú ayé. A ti ṣé gbogbo rẹ́ ní ọ̀pọ̀ pẹ̀lú yín-kìí ṣe nípa ọgbọ́n ayé, ṣugbọ́n nípa ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. 13 A kò kọ ohunkóhun síi yín tí ẹ̀yin kò leékà tàbi ní òye nípa rẹ̀, mo ní ìrètí pé 14 gẹ́gẹ́ bi ẹti ni òye díẹ̀ nípa wa. A ó jẹ̀ èrè idí fún ìṣògo yín ní ọjọ́ Jésù Olúwa wa, gẹ́gẹ́ bí ẹ ò ṣe jẹ èrè ìdí fún ìṣògo wa. 15 Nítorí pé mo ní ìgbòóyà nínú èyí, mo fẹ́ wá sì ọ̀dọ̀ yín ní àkọ́kọ́, kí ẹ̀yin kí o lè jẹ ànfààní ìbẹ̀wò ní ẹ́mejì. 16 Mò ńgbèrò láti bẹ̀yín wò nígbàtí mo bá ń kọjá lọ sí Masidóníà. Bákànáà mo fẹ́ láti bẹ̀yín wò tí mo bá ń ti Masidóníà padà bọ̀wá, àti fún yín láti le rán mi ní ọ̀nà mi sí Jùdíà. 17 Nígbàtí mo ń ronú ní ọ̀nà yín, Èmí a ṣiyèméjì bi? Pé èmi a lè gbèrò ohun wọọ̀nì gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ ènìyàn, kí èmi kí ò lè sọ́ wípé "bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ̀ni" àti "bẹ́ẹ̀kọ́, bẹ́ẹ̀kọ́" ní ẹ̀kan ṣoṣo? 18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, a kò sọ méjèjì "bẹ́ẹ̀ni àti bẹ́ẹ̀kọ́". 19 Fún Ọmọ Ọlọ́run Jésù Krístì, tí Sífánù, Tímótíù àti èmi pẹ̀lú kéde rẹ̀ láàrin yín, kìí ṣe "bẹ́ẹ̀ni" àti "bẹ́ẹ̀kọ́." bíkòṣe pé O jẹ́ bẹ́ẹ̀ni. 20 Fún gbogbo ìlèrí Ọlọ́run jẹ́ "bẹ́ẹ̀ni" nínú Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀ ni a wípé "Àmín" sí ogo Ọlọ́run. 21 Nísinsìnyí Ọlọ́run ní ó ṣe àṣepé wa pẹ̀lú yín nínú krístì àti pé Òhun ní ó yàn wá. 22 Ẹní tí ó fi èdìdì Rẹ̀ dì wá tí ó sí fi Ẹ̀mí Rẹ̀ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bíì ìdánilójú ohun tí yóò fí fún wa ní ìkẹ́yìn . 23 Bikoṣe pé, mo pè Ọlọ́run pé kí ó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀rí fún mí pé ìdí tí èmi kò fi wá sí Kọ́rìntì ní kí a lè dáa yín sí. 24 Kìí ṣe nítorí pé à ǹgbìyánjú láti màa darí ohun tí ìgbàgbọ́ yín yóò jẹ́. Bíkòṣe pé, à ń ṣisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín, gẹ́gẹ́ bi ẹ ti dúró nínú ìgbàgbọ́ yín.