1 Pétérù, àpóstélì Jésù kristì sí àwọn àyànfẹ́ tíńse àtìpó ti a fọnka, ní gbogbo Pọntusi, Galátìa, Capadócíà, Ásìa, Bítínìa. 2 Èyí ni gẹ́gẹ́ bi ìmọ̀tẹ́lẹ̀ ti Ọlọ́run Baba, tí ayàsọ́tọ̀ nípa Ẹ̀mí fún igbọ́ran àti fún fífọ́n ọn ẹ̀jẹ Jésù Kristi. Kí ore-ọ̀fẹ́ wa fún yín àti kí àlááfìa yín pòsi. 3 Kí ìbùkún jẹ́ ti Ọlọ́run àti Baba Jésù Kristì Olúwa wa. Nínú àánú ńlá Rẹ, ó so wá di àtúnbí fún ìdánilójú ogún. Ogún yi jẹ́ nípa àjíǹde ti Jésù Kristì kúrò nínú àwọn òkú. 4 Èyí ni fún ogún tí kì yóò ṣègbé, tí kí yóò ní àbàwọ́n, àti tí kìí ṣá. Tí ati pèsè sílẹ̀ fúnyiń ní ọ̀run. 5 A dábòbò yín pèlú agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́, fún ìgbàlà tí o setán láti farahàn ní ìgbà ìkẹhìn. 6 Inú yín dùn gidigidi nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó pondandan báyìí pé kí ẹ̀yin banújẹ́ ninu ọ̀pọ̀ oníruúrú wàhálà. 7 Èyí ni fún ìdánwò ìgbàgbó yín, tí ó ṣeyebíye ju wúrà tí ń ṣègbé lọ, bí o ti lẹ̀ jẹ́ pé a fi iná danwò. Èyí wáyé kí a leèri pé ìgbàgbọ́ yín yọrí sí ìyìn, ògo àti ọlá ní ìfarahàn Jésù kristì. 8 Ẹ̀yin kò ì tí rìi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fẹ́ẹ. Ẹ̀yin kò ri nísìnsìnyí, ṣùgbón ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀, ẹ̀yin si ńdunnú gidigidi pẹ̀lú ayọ̀ tí ẹnu kò le sọ, tí ó lógo. 9 Ẹ̀yin sí n gbà nísìnsìnyí fúnrayín àbáyọrí ìgbàgbọ́ yín, ìgbàlà ọkàn yín. 10 Àwọn wòọ́líì ṣe ìwádì fínífíní nípa ìgbàlà yìí, nípa ore-ọ̀fẹ́ tí yóò jẹ́ ti yín. 11 Wọ́n wádìí láti mọ̀ nípa ẹni náà àti nígbàtí Ẹ̀mí Krístì nínú wọn bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Èyí sí ń ṣẹlẹ̀ bí o tí ń sọ fún wọn sáájú nípa ti ìjìyà Krísti àti àwọn ohun ológo lẹ́yìn Rẹ̀. 12 A fihàn fún wọn pé wọn kò sin arawọn, bíkòse ẹ̀yin, nígbàtí wọ́n sọ àwọn ohun náà, tí a ti sọ fún yín nísìsiǹyí láti ọ̀dọ àwọn oníwàásù ìhìnrere síi yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán láti ọ̀run - àwọn ohun nàá tí àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò. 13 Nítorí náà ẹde àmùrè ọkàn yín. Ẹ wà ní àìrékọjá. Ẹ fi ìgbẹ́kẹ̀lé yín sínú ore-ọ̀fẹ́ tí a ó mú tọ́ yín wá ní ìfarahàn Jésù kristì. 14 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí ńgbọ́ràn ẹmá se da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn ìfẹ́kùfẹ́ tí ẹ̀yin lépa nígbàtí ẹ̀yín jẹ́ alaìmọkan. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yín ti jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin, pẹ̀lú, kí ẹjẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín. 16 Nítorí a kọ́ọ́ pé, "Ẹjẹ́ mímọ́, nítorí tí èmi jẹ́ mímọ́." 17 Nítorí náà bí ẹ̀yin bá pe "baba" ẹni náà tí ń dájọ́ láìsí ojúsàájú gẹ́gẹ́ bíi isẹ́ olúkúlùkù, ẹlo ìgbà ìrìnàjò yín nínú ọ̀wọ̀. 18 Nítorí ẹ̀yin mọ̀ pé kìí ṣe pẹ̀lú wúrà tàbí fàdákà tí ń díbàjẹ́ ni a fi rà yín padà kúrò nínú ìwà asiwèrè tí ẹ̀yin kọ́ láti ọ̀dọ àwọn bàbá yín. 19 Dípò, a ti rà yín padà pẹ̀lú ẹ̀jẹ krístì èyí tí ó seyebíye, ẹni bíi ọ̀dọ́- àgùtàn aláìlábàwọ́n tàbí àbùkù. 20 kí á tó fi ìpiǹlẹ̀ ayé solẹ̀ ni a ti yan krístì, ṣùgbọ́n nísìsiǹyí a ti fihàn fún yín ní ìgbà ìkẹhìn yí. 21 Nípasẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin gba Ọlọ́run gbọ́, tí ó jíi dìde kúrò nínú àwọn òkú àti ẹnití ó sì fi ògo fún kí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé yín le wà nínú Ọlọ́run. 22 Ẹ̀yin sọ ìgbàgbọ́ yín di mímọ́ nípa ìgbọ́ran sí òtítọ́. Èyí si wà fún ìfẹ́ òtítọ́ láàríń ará; nítorí náà ẹ nífẹ́ arayín gidigidi láti ọkàn wa. 23 Ẹ̀yin ti di àtúnbí, kìí ṣe láti irúgbìn ìdibàjẹ́, ṣùgbọ́n láti inú irúgbìn àidìbàjẹ́, nípa ọ̀rọ̀ ìyè tí Ọlórun, ti ó sì dúró. 24 Ńítorí "gbogbo ẹran ara dàbí koríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó koríko. Ewéko gbẹ, àti òdòdó si rẹ̀ dànù, 25 ṣùgbón ọ̀rọ̀ Olúwa dúró láíláí." Èyí ni ìròyìn ayọ̀ tí a kéde rẹ̀ fún yín.