1 Èyí tí ó ti wà lati àtètèkọ́ṣe-tí a ti gbọ́, tí a ti ri pẹ̀lú ojú wa, tí a ti wò, tí ọwọ́ wa si ti gbámú-ó jẹ́ nípa Ọ̀rọ̀ ìyè. 2 Àti pẹ̀lú, a fi ìyè naa hàn, a sì ti rí i, a sì n jẹri nípa rẹ. À ń kede ìyè ayérayé fún yín , èyí tí ó wà pẹ̀lú Baba, àti èyí tí ati fi hàn fún wa. 3 Èyí tí a ti rí tí a sì ti gbọ́ tí a n kede fún yín pẹ̀lú, kí Ẹ̀yin náà le ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Ìdàpọ̀ wa wà pẹ̀lú Baba àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì 4 Àti pẹ̀lú, àwa ń kọ àwon ǹkan wọ̀nyí síi yín kí ayọ̀ wa lè di kíkún. 5 Èyí ni ọ̀rọ̀ náà tí àwa ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ tí a sì n kéde fún yin: Ọlọ́run ni ìmọ́lẹ̀, àti nínu rẹ̀ kò sì sí òkùnkùn kankan rárá. 6 Bi àwa bá wípé awa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tí a sì ń rìn ní òkùnkùn, àwa ń parọ́ àwa kò sì ṣe ìṣòdodo 7 Ṣùgbọ́n bí a bá n rìn nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú arawa, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ si wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀sẹ̀. 8 Bí àwa bá wípé àwa kò ní ẹ̀sẹ̀, àwa ń tan arawa, òtítọ́ kò sì sí ní inú wa. 9 Sùgbọ́n bí àwa bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀sẹ̀ wa, olótitọ àti olódodo ni lati dárí ẹ̀sẹ̀ wa jín wá àti lati wẹ́ wá kúrò ninu aìsòdodo gbogbo. 10 Bí àwa ba wípé àwa kò dá ẹ̀sẹ̀, awa pè é ní onírọ́, ọ̀rọ rọẹ̀ kò sì sí ní inú wa