1 Ama, wọ fọ ọtitọ ye yẹ fu ẹkọ iré ye ma ẹ. 2 Fọ fu agbalagba ya ni aya kajẹ onisuru, asaju, ko nẹ afọ kisian agbo ogu iré ẹ, ko pé n'nọn igbagbọ wu ieẹ, wu suru. 3 Bẹ ni ọbọion agbalagba a ya kanẹ iwa iré lojù bi onian iré, ye aya ka bu ipo fu ẹ ko na jẹ afafọ onian l'aṅi ẹ , koma jẹ aniọti. 4 Owa ni aya ka fu ẹkọ iré , ni kase ẹkọ fu omạ égidàn ye nẹ oko yai ẹ ni aya kawa dédé ni ayaka fian ọkọ yan wu oma ya. 5 Aya ka nẹ anu kiya, aya ka wa dédé aya ka mu ojuto ile, oli wa iré, aya ka fu arabalẹ fu ọkọ ya-ndi afọ ọlọhun ko ma bajẹ. 6 Bẹẹ ni mu oma ẹsọ ya lara kile ni aya ka fu ara balẹ. 7 Wo pàpàà jẹ aifusé akọgbn in'nọn ẹkọ iré, nki fu ẹkọ ki ma wu ye yẹ. 8 Afọẹ kọmà, koma nẹ isina ni anọn ko mu otà ni aya ka ma ri iseku fọ larawa. 9 Oma ọdọ ya ka fu ara balẹ fu oga ya ; aya ka se ko dọn fu oga ya nọna kona, aya ka ma gbo ya nanu. 10 Aya ka ma solé nkan kan, ama aya ka se ọtitọ ngbaki gba ndi ni ẹkọ afọ olọhun olugbala wa ko wulo. 11 Ooré ofẹ ọlọhun, ewo odo igbala wa ti ṅa dié. 12 A kọ wa ni ka jawọ nhọn ẹsẹ wu ojukunkun aiyé ni ka gbe l'ayé ye n'non iwa kisian. 13 Bẹẹ ni a ka fu à dio dé kusẹẹ ye a dé wu ójọ ye ogo ọlọhun lakun wu olugbala wa Jésu-Kristi nko fu ara han . 14 O fu ara ẹ fu fu wa ndi ni ko ra wa pada lawo ẹsẹ ni ọ sọ wa di oma ilu kima yé jẹ tẹ gbo nkọ gba ara ẹ fu isẹ iré ki se. 15 Nkan ye wa fọ ya nẹ, mu nẹ l'ara kile, wa ba ya fọ wu asẹ. Onika ko ma fu ojù dié.