Ewo 3

1 Ẹnin wa ya, ẹ gbadura fu wa n'ọnan k'ọnan, n'dini afọ ọlọon kotiko gbilẹ ni ko ɖi a yin l'ogo bẹnẹni o gbilẹ n'di yẹ ẹ. 2 Ni ka tiko bọ l'ọwọ enin ye kọ gba tiwa ya uwu onian iseku ya, n'dini kose gudu gudu onian ni ọ gbagbọ. 3 Ama ọluwa wa ni olotitọ, n'kọ f'ẹsẹ yẹ mulẹ, n'kọ yọ yẹ dide n'non iseku. 4 Awa a nin igbọkanle n'nan oluwa n'tiẹ yẹ ni n'kan ye ya apa lasẹ fu yẹ ẹ ni ẹ yẹ ẹ sé un yẹ ni ẹkẹ sin a sé. 5 Oluwa kaa fa ọkan yẹ lọ n'non ifẹ ọlọon, uwu lọsọ suru Kristi. 6 A pa asẹ fu yẹ, enin wa ya, ni l'ekọ Jesu Kristi ọluwa wa kẹ ma se kẹ Pẹki ẹnin ye ya a fọ ni a ya jẹ ti awa gbo aya a rin sègèsègè aya kọ rin gan-gan n'non ẹkon ye aya gba idi wa ẹ. 7 N'dini ẹ ye pa-paa ẹ ti man bẹnẹni ọ wa ni kefu ara yẹ we wa ẹ, n'dini awa akọ rin segesege limeji yẹ. 8 Bẹni akọ sin jẹ ijẹ onikan l'ofẹ, ama n'non ipaju wa uwu wahala wa ni awa a sisẹ ọsan kan aru kan, ni ka ma wa di eunfu onikan n'non yẹ. 9 Kọ sin se ni a kọ nin asẹ ẹ ama awa a fu ara wa se apẹrẹ fu yẹ ni kẹ tiko fu ara ye we wa ni. 10 N'dini lasiko ye awa a wá n'di yẹ ẹ ni a pa asẹ ye fu yẹ, ni: enin ye ko sisẹ ẹ kọ wa niko jijẹ gbo. 11 N'dini awa agbọ oro ẹnin bibọ ya aya a rin segesege limeji yẹ, aya kọtẹ wa an ka sisẹ ifèfè ama aya a t'oju bọle kini. 12 Awa a pe isi onian bẹ, ni a gba ya ni yanju lẹpasẹ ọluwa wa Jesu Kristi ni aya kafu ara balẹ se isẹ ni aya ka jẹ ijẹ ọwọ ara ya. 13 Ama n'ti ẹyẹ ẹnin miya, ire ki se kọma se ko su yẹ. 14 Lẹpa iwe ye a kan i bioseni onikan kọ gba afọ wa gbọ ẹ samin ẹnin bẹ, kẹ ma se ba rin o, ni ko di anan fu. 15 Ama kọma se kodi ọta yẹ ẹ f'afọfu bẹnẹni enin yẹ ẹ. 16 Ọluwa alafia pa paa ko fu yẹ l'alafia lasiko kasiko, lọna gudugudu, ọluwa kọ wa uwu gudugudu yẹ. 17 Ẹmi Pɔlu, man ki yẹ ọwọ ara mi ni mofu kan iwe ye, lọsọ iwe ye man kon gudu gudu bẹnẹni man fu ọwọ tẹ nẹn bẹni man kon iwe. 18 Ore-ofẹ oluwa wa Jesu Kristi ko wa uwu gudu gudu yẹ. Amin