Orí Kìńní

1 Láti ọ̀dọ̀ alàgbà sí obìnrin tí a yàn àti àwọn ọmọ rẹ̀, tí mo nífẹ̌ nítòótọ́-kìí sì se èmi nìkan, sùwọ́n gbogbo àwọn tí ó ti mọ òtítọ́- 2 nítorí òótọ́ tí ó wà síbẹ̀ nínú u wa tí yóò sì wà pẹ̀lú wa títí láí. 3 Kí ore-ọ̀fẹ́, àánú, àlàáfìà wà pẹ̀lú wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá àti láti òdò Jésù Kristì, Ọmọ Bàbá, ní tòótọ́ àti ní ìfẹ́. 4 Mo yò gidigidi pé mo ti rí díè nínú àwọn ọmọ yín tí ó ń rìn ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin láti ọ̀dọ Bàbá. 5 Nísinsìnyí, mo bẹ̀ yín, arábìnrin-kìí se bíi pé mò ń kọ òfin titun, ṣùgbọ́n èyí tí a ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀- pé kí á fẹ́ràn ara wa. 6 Èyí ni ìfẹ́, pé kí á rìn nípa òfin Rẹ̀. Èyí ni òfin, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ́rẹ́, pé kí ẹ rìn nínú rẹ̀. 7 Nítorì ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ni ó ti lọ sínú ayé, wọn kò sì jẹ́wọ́ pé Jésù Kristì wá nínú ara. Èyí ní ẹlẹ́tàn àti alòdì sí Krístì. 8 Ẹ wọ ara yín, kí ẹ má baà sọ ohun tí a ti sisẹ́ papọ̀ fún nù, kí ẹ̀yin kí ó baà le gba èrè tí ó kún. 9 Ẹni tí ó bá tẹ̀síwájú tí kò sì dúró nínú ẹ̀kọ́ Krístì kò ní Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúro nínú ẹ̀kọ́ náà, ẹni bẹ́ẹ̀ ní Baba àti Ọmọ. 10 Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yǐ wá, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbàá sínú ilé yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ́ kíi. 11 Nítorí ẹni tí ó kíi kópa nínú isẹ̀ ibi rẹ̀. 12 Mo ní ohun tó pọ̀ láti kọ síi yín, ṣùgbọ́n kò wù mí láti kọ ọ́ pẹ̀lú ìwè àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní irètí láti wá sọ́dọ̀ yín, àti láti báa yín sọ̀rọ̀ lójúkorojú, kí ayọ̀ wa baà leè pé. 13 Àwọn ọmọ arábìnrin yín tí a yàn kí i yín.