Orí Kaàrún

1 Ní ti òmìnira, Krístì ti sọ wá di òmìnira. Nítorínà, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ má sì ṣe wà ní abẹ́ ìsàkóso àjàgà ti ìkónilérú. 2 Ẹ wòó, èmi, Pọ́ọ̀lù, sọ fún yín pé tí èyin bá fi ara yín sílẹ̀ fún ìkọlà, Krístì, kì yó ní èrè kankan fún yín. 3 Lẹ́ẹ̀kan sí, mo ṣe ìjẹ́rí pé gbogbo ènìyàn tí ó bá fi ara rẹ síiẹ̀ fún íkọlà ó pọn dandan fún-un láti se ìgbọràn sí gbogbo òfin . 4 A gée yín kúrò lára Krístì, ẹ̀yin tí ẹ ó gba ìdáláre nípasè òfin; ẹyin kò ní ìrírí ore-ọ̀fẹ́ mọ́. 5 Nítorí nípasẹ̀ ti Ẹ̀mí, nípa ìgbàgbọ́, ni a ń fi inúdídùn dúró de ìrètí òdodo tí ó dájú. 6 Nínú Jesù Krístì ìkọlà tàbí àìkọlà kò ní ìtumọ̀ kankan, bíkòse ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ ti ìfẹ́. 7 Ẹ ti ń sáré dáradára. Tani ó dá yín dúró láti má se ìgbọràn sí òtítọ́? 8 Ìyínilọ́kàn padà yí kò ti ọ̀dọ ẹni tí ó pè yín wá! 9 Ìwúkàrà kékeré amá a mú gbogbo ìyèfun wú. 10 Mo ní ìgboyà nínú Olúwa wípé ẹ̀yin kì yóò rí irú èyí mọ́. Ẹni tí ó ń dà yín láàmú ni yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹni yóò wù tí ìbáà jẹ́. 11 Ẹ̀yin ará, tí èmi bá sì ń polongo ìkọlà, kílódé tí èmi ṣì n rí ìpọ́nlójú? Fún ìdí èyí òkúta ìdìgbòlù ibi àgbélèbú ti sí kúrò. 12 Ní ti àwọn tí ó ń dàyínláàmù, ó wù mì kí wọ́n tẹ ara wọn lọ́dà! 13 Nítorí ti a pè yín sí òmìnira, ará. Sùgbọ́n ẹ má se lo òmìnira yín gẹ́gẹ́ bíi ànfàní fún ìgbeayé ẹ̀ṣẹ̀; sùgbọ́n, nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹ ran ara yín lọ́wọ́. 14 Nítorí tí gbogbo òfin di mímúṣẹ nínú àṣẹ ẹyọọkan; nínú'' ìwọ gbọ́dọ̀ fẹ́raǹ ẹnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bi ara rẹ.'' 15 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yín bá ń bu ara yín sán ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run. 16 Ṣùgbọ́n èmi wípé, ẹ rìn nípa tí ẹ̀mí, ẹ̀yin kò sì ní ṣe ìfẹ́ inú ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ 17 Nítorí ìfẹ́ ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí tí ẹ̀mí àti ẹ̀mí sí ti ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí tí àwọn méjéèjì wà ní ìjàkadì pèlú ara wọn, kí ẹ̀yin kí ó má baà ṣe àwọn ohun ti ó ń wù yín láti ṣe. 18 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá wà lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin. 19 Nísisiǹyí, àwọn isẹ́ ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ àrídájú: ìṣẹkúṣe, àìmọ́, ìfẹ́kùfẹ́ ara, 20 ìbọ̀rìṣà, osó, ìkanra, ìjà, owú, inúfùfù, orogún, ìyapa, ìpínyà, 21 Ìlara, ọtí mímu, ìmutí para tí ń fa rògbòdìyàn, àti àwọn ǹǹkan tí ó dàbíi rẹ̀. Èmí ń kìlọ̀ fún yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sọ fún yín tẹ́lẹ̀ rí, wípé àwọn tí ó n ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí kò ní ìpín ní ìjoba Ọlórun. 22 Sùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àláfíà, inúrere, ìwàrere, ìgbàgbó, 23 ìwàpẹ̀lẹ́, àti ìkó-ara- ẹni ní ìjánu; láìsí èyí kò sí òfin. 24 Àwọn tí ó jẹ́ tí Jésù krístì ti kan ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú gbogbo ìtara àti ìfẹ inú rẹ. 25 Tí a bá ń gbé nípa ti ẹ̀mí, ẹ jẹ́ ká máa rìn nípa ti ẹ̀mí náà. 26 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbéraga, nípa mímú ara wa bínú, ṣíṣe ìlara ara wa.