1 Nígbà náà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélógún, mo gòkè lọ sí jerúsálẹ́mù pèlú Bánábà, mo sì mú Títù náà pèlú mí. 2 Mo lọ nítorí ìran kan àti láti gbé ìhìnrere tí mo ń kéde rẹ̀ láàrin àwọn Kèfèrí kalè ní iwájú wọn. Mo bá àwọn tí ó dàbí pé wọ́n ṣe pàtàkì sọ̀rọ̀ ní kọ̀kọ̀, kí èmi kí ó bà léè ri dájú wípé èmi kò sáré - tàbí ti sáré - lásań. 3 A kò fi ipá kọlà fún Títù gan tó wà pẹ̀lú mi tí ó sì jẹ́ Gírìkì. 4 Àwọn arákùnrin èké wá láti ṣe amí ní kọ̀kọ̀ lórí òmìnira tí a ní nínú Jésù Krístì. Wọ́n fẹ́ láti sọ wá di ẹrú, 5 Ṣùgbọ́n àwa kò tẹríba ní jíjọ̀wọ́ arawa fún wọn fún ìgbà kan, kí òtítọ́ ti ìhìnrere leè wà pẹ̀lú yín. 6 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó rí bí ẹnipé wọ́n ṣe pàtàkì (ohunkóhun tí wọ́n jẹ́ kò nítumọ̀ sí mi, Ọlọ́run kìí se ojú-ìṣàjù) - àwọn ni mo sọpé, wọ́n rì bí ẹnipé wọ́n ṣe pàtàkì, wọn kò fi ohunkóhun kún mi. 7 Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ríi wípé a ti fi ìhìnrere sí ìkáwọ́ mi fún àwọn aláìkọlà, gẹ́gẹ́ bí a ti fi ìhìnrere sí ìkáwọ́ Pétérù fún àwọn tí ó kọlà. 8 Nítorí Ọlọ́run, tí ó ṣiṣẹ́ nínú Pétérù fún tí àpọ́stélì sí àwon tí wọ́n kọlà, sì ńṣe iṣẹ́ nínú mi sí àwọn kèfèrí. 9 Nígbàtí Jákọ́bù, Sẹ́fásì, àti Jòhánnù, àwọn tí a dámọ̀ gẹ́gẹ́ bíi àwọn tí ńkọ́ ìjọ, ti lóye ore-ọ̀fẹ́ tí a fifún mi, wọ́n fún èmi àti Bánábá ní àtìlẹ́yìn. Wọ́n ṣe eléèyí kí àwa báa lè lọ sọ́dọ̀ àwọn kèfèrí, àti pé àwon yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó kọ ilà. 10 Wọ́n bèrè pé kí á rántí àwọn otòṣì, ohun gangan tí èmi ńfẹ́ láti ṣe. 11 Ṣùgbọ́n nígbàtí Sẹ́fásì wá sí Áńtíókù, mo pèé níjà sí ojú rẹ̀ nítorípé a kéde rẹ̀ níbi àìtọ́. 12 Kótó di wípé àwọn arákùnrin kán wá láti ọ̀dọ Jákóbù, Sẹ́fásì ń jẹun pẹ̀lú àwọn kèfèrí. Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn arákùnrin yìí dé, ó dúró ósì yaa kúrò lọ́dọ̀ àwọn kèfèrí. Ó sí bẹ̀rù àwọn ti ó ń pèé fún ìkọlà. 13 Bákan náà ni ìyókù àwọn Júù darapọ̀ nínú àgàbàgebè yìí. A sì tún mú Bánábá kùnà pẹ̀lú wọn nípasẹ̀ àgàbàgebè wọn. 14 Ṣùgbọ́n nígbàtí mo ríi pé ìwà wọn kò tẹ̀le òtítọ́ ti ìhìnrere, mo sọ fún Séfásì ní iwájú gbogbo wọn, "tóbá jẹ́ pé ẹ̀yin jẹ́ Júù ṣùgbọ́n ẹ̀yín ńgbé bíi kèfèrí ti kìí ṣe bíi Júù, báwo ni ẹ̀yin ṣelè fi ipá mú àwọn kèfèrí láti gbé ayé gẹ́gẹ́ bíi Júù?" 15 Àwa gangan tìkalára wa jẹ́ Júù nípa ìbí, àwa kìí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ kèfèrí; 16 Síbẹ̀ àwá mọ̀ wípé kòsí ẹni tí a dá láre nípa iṣẹ́ òfin, ṣùgbọ́n nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Àwa náà wà nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì kí á ba lè gba idáláre nípa ìgbàgbọ́ nínú Krístì àti láìṣe nípa isẹ́ òfin. Nípa isẹ́ òfin, ẹran ara kan kò ní gba ìdáláre. 17 Ṣùgbọ́n bí a ṣe ńwá ìdáláre nínú Krístì, àwa náà, a ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ rí, ǹjé Krístì ńtẹ ẹ̀ṣẹ̀ síwájú bí? rárá! 18 Nítorí tí mo bá tún gbogbo ohun tí mo ti bàjẹ́ kọ̀, mo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí arúfin. 19 Torí nípa òfin mo kú fún òfin, kí nle wà fún Ọlọ́run. 20 A ti kàn mí mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú Krístì. Kìí ṣe èmi ni mo yè mọ́, ṣùgbọ́n Krístì yè nínú mi. Ayé tí mo ńgbé nísìnsinyí nípa ẹran ara, mo yè nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, Ẹni tí ó fẹ́ mi àti ẹni tí ó fi ayé rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan, ǹjẹ́ tí ènìyàn bá le jẹ àǹfàní òdodo nípasẹ̀ òfin, nígbànáà ni Krístì kú fún asán.