Òrí Kọkànlélógún

1 Ó sì ṣé, nígbàtí a kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ńlọ lórí omi, a sì lọ tààrà sí ìlú Kọ́sì, ní ọjọ́ kejì a dé ìlú Ródíà, àti làti ibè lọ sí ìlú Pátárà 2 Nígbá tí a rí ọkọ̀ ojú omi tí ó ń ré kọjá lọ sì Pónisià a sì wọ inú rẹ̀, a sì ńlọ. 3 Lẹ́yìn ti arí Síprúsì, à sí fi í sílẹ̀ ní apá àlàáfíà rèkojà sí Síríà a sì dúró ní Tírè níbití ọkọ̀ yóò ti já ẹrù rẹ̀, láti já àwọn ẹrù inú rẹ. 4 Lẹ́yìn tí a ti rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, a dúró síbẹ̀ fún ọjọ́ méje, nípasẹ̀ Ẹ̀mí wón n rọ Pọ́ọlù kí ó máṣe lọ sí Jerúsálẹ́mù. 5 Nígbàti o to àkókò, a kúrò, a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n, àti gbogbo wọn pẹ̀lú àwon aya àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sìn wá jáde kúrò nínú ìlú. Lẹ́yìn náà, a kúnlẹ̀ ní etíkun a sì gbàdura 6 léyin náà a kí ara wa pé ó dìgbà. Léyiǹ náà ni a wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, wọ́n sì padà sí ilé wọn. 7 Nígbàtí a parí ìrìn àjò láti Tírè, a gùnlẹ̀ si Polemisi, a kí àwọn arákùnrin, a sì dúró pẹ̀lú wọn fún ọjọ́ kan. 8 Ní ọjọ́ kejì a kúrò, a sì lọ sí Kesaríà, a sì wọ ilé Fílípì Ajíyìnrere, Ọ̀kan ninu awọn méje, a sì dúró pẹ̀lú rẹ̀. 9 Ọkùnriń yìí ni àwọn Ọmọbìnrin wúńdíá mẹ́rin tí wọn ń máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ 10 Bí a ṣe dúró níbẹ̀ fun ọjọ́ mélòó, Wòlíì kán ti Júdà wá tí a pe orúkọ rẹ̀ ní Ágábù. 11 Ó wá sí ọ̀dọ̀ wa, ó mú okùn ìgbánú u Pọ́ọlù, o sì fi de ẹsẹ̀ àti ọwọ́ ara rẹ̀, ó ní, "báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí àwọn Júù yóò de ẹni ti ó ni ìgbànú yìí, wọn á sì fi í lé àwọn Kèfèrí lọ́wọ́. 12 Nígbàtí agbọ́ n kàn wònyí, àwa àti àwọn tí ó ń gbé ní ibẹ̀, bẹ Pọ́ọ̀lù kí ó máṣe lọ sí Jèrúsalémù. 13 Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dáhùn, "Kíni ohun tí ẹ̀ ńṣe, ẹ̀ ń sọkún láti ba ọkàn mi jẹ́? Torí mo ti ṣetán kì í ṣe lati dè mí nìkan ṣùgbọ́n, láti kú ní Jèrúsalémù nítorí orúkọ Olúwa Jésù. 14 Ṣùgbọ́n nígbàtí a kò leè yí Pọ́ọ̀lù lọ́kàn padà, a jáwọ́, a sì wí pe, "Kí ìfé Olúwa kí o ṣẹ" 15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a gbé àpò o wa, a sì kọjá lọ sí Jèrúsalémù 16 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan láti Kesaríà tẹ̀ lé wa. Wọ́n mú ọkùnrin kan lọ́wọ́ tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Mńásónì, láti ìlú u Sípróósì, Ọmọlẹ́yìn àkọ́kọ́, lọ́dọ̀ ẹnití a ò dúró. 17 Nígbàtí a dé Jerúsalẹ́mù, àwọn arákùnrin kí wa káàbọ̀ tayọ̀tayọ̀. 18 Ni ọjọ́ kejì Pọ́ọ̀lù tẹ̀lé wa lọ sí ọ̀dọ̀ ọ Jákọ́bù, àwọn àgbààgbà sì wà ní ìkàlẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì kí wọn tán, ó ròyìn lọ́kọ̀ọ̀kan ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láàrin àwọn aláìgbàgbọ́ láti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìráńsẹ́ ẹ rẹ̀. 20 Nígbà tí wọn gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, "Wò ó, arákùnrin, ẹgbẹgbèruń àwọn tí ó ti gbàgbọ́ nínú àwọn Júù. Gbogbo wọn ti pinu láti pa òfin mọ́. 21 A ti sọ fún wọn nípa rẹ, pé ìwọ ń kọ́ àwọn Júù tí ó ń gbé láàrin àwọn aláìgbàgbọ́ láti pa Mósè tì, àti pé o sọ fún wọn láti máṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà, kí wọn kí ó máṣe tẹ̀lé àwọn àṣà àtijọ́ mọ. 22 Kíni kí á ṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti wa. 23 Fún ìdí èyí, ṣe ohun tí a sọ fún ọ. A ní àwọn arákùnrin tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. 24 Mu àwọn arakunrin wọ̀nyí kí o sì wẹ ara rẹ mọ́ pẹ̀lú wọn. kí o sì san owó ìná wọn fún wọn, kí wọn ba lè fá orí wọn. Kí gbogbo ènìyàn le è mọ̀ pé ohun gbogbo tí wọ́n ti sọ nípa rẹ ki í ṣe òtító. Wọn yóò sì mọ̀ pé ò ń tẹ̀ le òfin. 25 Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó ti gbàgbọ, a kọ̀wé sí wọn pẹlú ìtọ́ni kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi ṣe ìrúbọ sí orìṣà àti ẹ̀jẹ̀, kúrò nínú ẹran tí a yín lọ́rùn àti kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀. 26 Nígbànáà ni Pọ́ọ̀lù mú àwọn arákùnrin náà, àti ní ọjọ́ kejì ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pẹ̀lú u wọn, ó lọ sínú tẹ́ḿpìlì ó sì kéde àwọn àkókò àti ọjọ́ ìyàsímímọ́, tí tí a fi ṣe ọrẹ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. 27 Nìgbà tí ọjọ́ méje náà fẹ́ẹ̀ parí, àwọn Júù kan, láti Áásíà rí Pọ́ọ̀lù nínú téḿpìlì, wọ́n sì dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú u. 28 Wọ́n ń pariwo, ''Ẹ̀yin ọkùnrin Ísráẹ́lì, ẹ ràn wá lọ́wọ́. Èyí ni Ọkùnrin náà tí o ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ibi gbogbo ní àwọn ohun tí ó lòdì sí àwọn ènìyàn àti òfin, àti ibí yìí. Pẹ̀lú, ó ti mú àwọn Gíríkì wọ inú tẹ́ḿpìlì láti ba ibi mímọ́ jẹ́ ''. 29 Nítorí wọn ti kọ́kọ́ rí Trófímúsì ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìlú, wọ́n sì rò wípé Pọ́ọlù mú u wá pẹ̀lú rẹ̀ wá sínú tẹ́ḿpìlì. 30 Wọ́n sì ru inú gbogbo àwọn ará ìlú sókè, àwọn ènìyàn náà sì sáré sí i, wọ́n sì gbá Pọ́ọ̀lù mú. Wọn sì fà á jáde kúrò nínú tẹ́ḿpìlì, lójú ẹsẹ̀ wọn sì ti àwọn ìlẹ̀kùn. 31 Bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti paá, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pe ìrókẹ̀kẹ̀ ti gba Jerúsálẹ́mù kan. 32 Lójúkan náà, ó sì mú àwọn ọmọ ogun àti àwọn Balógun Ọgọ́rùn, ó sì sáré tọ àwọn ènìyàn náà lọ. Nigba ti àwọn eniyan náà rí Balógun àti àwọn ọmọ ogun, wọ́n dá ọwọ́ dúró àti má a lu Pọ́ọ̀lù 33 Lẹ́yìn náà ni Balógun sún mọ́ wọn ó sì gbé ọwọ́ lé Pọ́ọ̀lù, ó pàṣẹ kí wọ́n fi ẹ̀wọn méjì dè é. Nígbà náà ni ó bèèrè pé ta ni, àti kíni ó ṣe. 34 Àwọn kan nínú àwọn èrò ń pariwo ohun kan nígbà tí àwọ́n mìíraǹ ń sọ n kan miran. Nígbà tí Olórí ẹ̀ṣọ́ kò leè sọ ohun kan nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ariwo, ó pàṣẹ kí wọn mu Pọ́ọ̀lù lọ sí ibi ìsádi. 35 Nígbà tí ó dé ibi àtẹ̀gùn, àwọn ọmọ ogun gbé e nítorí i wàhálà àwọn ènìyàn 36 Ọpọlọpọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n sì ń pariwo, "Mú u kúrò!" 37 Bí a ṣe fẹ́ẹ́ mú Pọ́ọ̀lù lọ sí ibi ìsádi, ó sọ fún olórí ẹ̀ṣọ́ pé, "ṣé mo le è sọ ohun kan fún ọ?" Olórí ẹ̀ṣọ́ dahun oni, "Ṣé o le è sọ Gíríkì? 38 "Ìwọ a kọ́ ni ará Égípítì, ẹni tí ó kọ́kọ́ darí àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin 'agbanipa' lọ sí inú ijù?" 39 Pọ́ọ̀lù wí pé, "Júù ni mí, láti ìlú Tásúsù ní Silisíà. Ọmọ ìlú tó ṣe pàtàkà kan ni mo jẹ́, mo bẹ̀ ọ , jẹ́kí n bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀." 40 Nìgbá tí Olórí ẹ̀ṣọ́ fún un láàyè, Póòlù sì dìde lórí àtẹ̀gùn, ó sì ju ọwọ́ sí àwọn ènìyàn, nígbà tí ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ó wí pé.